Báyìí ni ìpèníjà ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra ṣe le nípa lórí oúnjẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Abubakar Maccido
- Role, Reporter
- Reporting from, Kano
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Bí làásìgbò ètò ààbò ṣe ń peléke si ní Nàìjíríà, pàápàá ní ẹkùn àríwá níbi tí ìkọlù àwọn agbébọn, ikọ̀ Boko Haram/ISWAP, wàhálà àwọn darandaran àti àgbẹ̀ ti ń wáyé ní gbogbo ìgbà, tó sì jẹ́ pé ibẹ̀ ni oko dídá pọ̀ sí jùlọ.
Bí a ṣe ti wà ní àsìkò òjò báyìí, ọ̀pọ̀ àwọn àgbẹ̀ ni ẹ̀rù ń bà láti lọ sóko nítorí wọn kò fẹ́ fi ẹ̀mí ara wọn wéwu tàbí jẹ́ káwọn agbébọn jí àwọn gbé.
Lẹ́nu ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tó kọjá báyìí, àwọn ìkọlù tó wáyé ní ẹkùn ìlà oòrùn, ìwọ̀ oòrùn àti ààrin gbùngbùn àríwá ti mú ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àti dúkìá lọ. Àwọn agbègbè yìí ni ìpèsè oúnjẹ ti máa ń wáyé jùlọ.
Láìpẹ́ yìí ni iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ọ̀gbìn ní Nàìjíríà rọ àwọn òṣìṣẹ́ láti gba ààwẹ̀ àti àdúrà ọlọ́jọ́ mẹ́ta kí ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ má ba à sí ní Nàìjíríà. Èyí ṣe àfihàn bí ọ̀rọ̀ náà ṣe le tó.
Ní ọdún 2024, àjọ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ oúnjẹ ní àgbáyé, World Food Program sọ pé àìsí ètò ààbò, ọ̀wọ́ngógó àti àyípadà ojú ọjọ́ yóò mú kí ebi pọ̀ si ní Nàìjíríà àti pé èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ni yóò kojú ebi tó lágbára.
Àjọ tó ń rí si òǹkà ní Nàìjíríà, National Bureau of Statistics, NBS, sọ pé ìdá 39.16% ni ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ nínú oṣù Kẹwàá, ọdún 2024 lòdì sí ìdá 31.52% tó jẹ́ ní oṣù Kẹwàá, ọdún 2023.
Àwọn onímọ̀ gbàgbọ́ pé àìsí ètò ààbò tó dúró ire wà lára nǹkan tó fa àlékún owó oúnjẹ.
Wọ́n wòye pé ìjọba nílò láti wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ ààbò tàbí kí wọ́n wá ọ̀nà láti dáko ní ìlànà ìgbàlódé nítorí ẹ̀rù tó ń ba àwọn àgbẹ̀ ní ẹkùn àríwá láti lọ sóko.
Báwo ni wàhálà ètò ààbò ṣe le ní ipa lórí oúnjẹ àti iye rẹ̀ lọ́dún yìí?
Akọ̀wé ẹgbẹ́ àwọn àgbẹ̀ ní Nàìjíríà, All Farmers Association of Nigeria (AFAN), Dókítà Yunusa Halidu sọ fún BBC News Pidgin pé àìsí ààbò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìdí tó máa ń fa ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ.
"Kó tó di pé wàhálà ètò ààbò wà báyìí, ọ̀pọ̀ ìpínlẹ̀ ní ẹkùn àríwá Nàìjíríà ni wọ́n máa ń gbin oúnjẹ lọ́pọ̀ yanturu, tí oúnjẹ sì máa ń pọ̀ lọ́jà," Halidu sọ.
"Tí kìí bá ṣe àìsí ètò ààbò tó péye, ìpínlẹ̀ Zamfara nìkan le pèsè oúnjẹ tí gbogbo Nàìjíríà yóò jẹ."
Halide gbàgbọ́ pé àìsí ààbò ni okùnfà ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ tí Nàìjíríà ń kojú báyìí.
"Àì máa pèsè oúnjẹ tó ló jẹ́ kí iye tí wọ́n ń ta oúnjẹ máa lọ sókè si lẹ́nú ọdún mélòó kan sẹ́yìn, àìsí ààbò tó péye ló sì fà á. Ṣé ẹ mọ̀ pé bí àwọn èèyàn bá ṣe ń bèèrè nǹkan sí I owó rẹ̀ yóò máa lọ sókè sí.
Ó wòye pé àwọn ìpínlẹ̀ kan ní àríwá Nàìjíríà ni wọ́n ti ń pèsè ìrẹsì tí ọ̀pọ̀ ń jẹ tẹ́lẹ̀ àmọ́ ìpèsè ìrẹsì ní Nàìjíríà ti dínkù jọjọ.
"Àwọn ìpínlẹ̀ bíi Borno, Yobe, Katsina, Zamfara, Sokoto àti Kebbi máa ń pèsè ìrẹsì dáadáa tẹ́lẹ̀ àmọ́ péréte ni ìrẹsì tí wọ́n ń gbìn báyìí."
Ó fi kun pé ìpínlẹ̀ Jigawa nìkan ni wọ́n ti ń dáko ní ẹkùn àríwá Nàìjíríà báyìí láì sí wàhálà àwọn agbébọn.
Halidu tẹ̀síwájú pe tí ìjọba bá le kojú ìṣòro ètò ààbò, tí wọ́n sì ṣe àtìlẹyìn tó péye fún ètò ọ̀gbìn, Nàìjíríà kò n'ní ìṣòro oúnjẹ kankan àti pé oúnjẹ máa pọ̀ tí gbogbo èèyàn máa lè rà.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kí ni ọ̀nà àbáyọ?
Dókítà Angarawai Ijantiku Ignatius tó jẹ́ onímọ̀ nípa ètò ọ̀gbìn àti aṣojú Nàìjíríà ní International Crops Research Institute for Semi-Arid Tropics (ICRISAT) ní Kano sọ fún BBC pé ìjọba nílò láti dókoòwò gidi sétò ọ̀gbìn ìgbàlódé.
Ó sọ pé pẹ̀lú àwọn ìmọ̀ ìgbàlódé náà, a nílò ilẹ̀ láti ṣètò ọ̀gbìn.
Ó ní àwọn èèyàn le máa lo àpò tàbí ike láti fi máa gbin àwọn oúnjẹ bíi iṣu, ata àti àlùbọ́sà nínú ilé láti fi máa bọ́ ẹnu wọn.
Ó ṣàlàyé pé ohun mìíràn tí ìjọba le ṣe ni kí wọ́n pèsè ilẹ̀ táwọn èèyàn le fi máa dáko nínú ìlú èyí táwọn àgbẹ̀ le ti máa dáko wọn.
"A ni àwọn ìmọ̀ ẹ̀rọ láti fi ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọ̀fẹ́ fáwọn àgbẹ̀ lórí ọ̀nà tí wọ́n fi le máa dáko láàárín ìlú.
"Bí wọ́n ṣe máa dáko láàárín ìgbà péréte tí wọ́n sì máa kó èrè oko wọn, pin fáwọn aráàlú kíákíá.
"Ohun tí a kàn máa nílò ni àwọn fijilanté tí wọ́n máa ma dá ààbò bo àwọn àgbẹ̀."
Ṣùgbọ́n Dókítà Ignatius wòye pé ètò yìí kàn jẹ́ àtìlẹyìn lásán, kò lè dé ibi gbogbo àti pé gbogbo èèyàn kọ́ ló máa le gbin oúnjẹ sílé wọn.
Onímọ̀ nípa ètò ààbò míì Dókítà Auwal Abdullahi sọ pé ìjọba Nàìjíríà nílò láti wá ọ̀nà míì láti gbogun ti ìwà ìgbéṣùmọ̀mí.
Ó sọ pé láti ọdún mẹ́wàá ni ìjọba ti ń lo ìwà ipa láti fi kojú àwọn agbéṣùmọ̀mí, ó ní ó yẹ kí wọ́n gbìyànjú ìlànà ìjíròrò wò.
Ó ní tó bá tit ó àsìkò ọ̀gbìn, ìjọba nílò láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn aráàlú àti pé tó bá ṣeéṣe kí wọ́n dúnàádúrà pẹ̀lú àwọn agbébọn tó ń da àwọn àgbẹ̀ láàmú.
Dókítà Abdullahi ní ìgbésẹ̀ yìí ṣiṣẹ́ ní ìjọba ìbílẹ̀ Birnin Gwari, ìpínlẹ̀ Kaduna.
Ó fi kun pé ti wọ́n bá lo ìlànà ìpẹ̀tù sááwọ̀ láti fi bá àwọn agbébọn sọ̀rọ̀ láti gba ohun ìjà lọ́wọ́ wọn, láti dẹ́kun ìjínigbé àti ìdaranjẹko, àwọn àgbẹ̀ yóò lè dáko, tí yóò sì ṣe ìrànwọ́ fún ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà.















