Bí a ṣe mú afurasí ògbóǹtarìgì olórí agbénipa àti adigunjalè tó ń pàwọn èèyàn lẹ́kún ní ìpínlẹ̀ Eko rèé - Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Lagos State Police Command
Yoruba bọ wọn ni ọjọ gbogbo ni tole, ọjọ kan ni toloun, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti ṣalaye bi ọwọ ṣe tẹ ogbontarigi olori apaayan at'awọn adigunjale to n ṣọṣẹ n'ipinlẹ Eko, Wasiu Akinwande, ti inagijẹ rẹ n jẹ Olori Eso.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita wi pe aṣeyọri nla ni ileeṣẹ ọlọpaa ṣe lori akititan rẹ lati gbogun ti iwa ọdaran ati iwa ipa nipinlẹ naa pẹlu bi ọwọ ṣe tẹ Olori Eso.
Ọgbẹni Hundeyin ni lana ọjọ Abamẹta, ogunjọ oṣu Kẹfa ọdun yii ni awọn ikọ akọṣẹmọṣẹ ọlọpaa to ni imọ nipa mimu ọdaran ṣọ Akinwande ti wọn si yọ tẹle e titi ti wọn fi mu un.
Hundeyin fidi rẹ mulẹ ninu atẹjade naa wi pe Olori Eso jẹ ọmọ ọdun mẹrinlelogoji, o si jẹ olori awọn agbenipa, adigunle ati awọn ẹlẹgbẹ okunkun.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni Olori Eso yii atawọn iṣọmọgbe rẹ ni wọn ti n ṣọṣẹ lagbegbe Mushin ati ayika rẹ fun ọpọ igba bayii.
Olori Eso jẹ afurasi ọdaran agbenipa tawọn ọlọpaa ti kede wi pe awọn wa fun igba diẹ bayii.
Hundeyin ni ''bi ọwọ ṣe tẹ Olori Eso jẹ aṣeyọri nla fun ileeṣe ọlọpaa ipinlẹ Eko lori igbiyanju rẹ lati daabo bawọn olugbe agbegbe Mushin atawọn agbegbe mii niluu Eko lọwọ awọn adigunjale to n dunkoko mọ wọn.''
''Bayii ni a ṣe mu afurasi ogbontarigi agbenipa ati olori awọn adigunjale Wasiu Akinwande''
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye pe ''nibi ti Wasiu Akinwande maa n sa pamọ si lagbegbe Agbado nipinlẹ Ogun ni ọwọ ọlọpaa ti tẹ ẹ, lẹyin ti a ti gbiyanju lati mu un fun ọpọ igba ti ko ṣee ṣe.
Fun bii ọdun mẹwaa lati ọdun 2009 si 2024 ni Wasiu Akinwande atawọn iṣọmọgbe rẹ ti n ṣọṣẹ ti wọn ti n dunkoko mawọn araalu papaa julọ awọn olugbe agbegbe Mushin nipinlẹ Eko.
Oun lo wa nidi ọpọ iṣẹlẹ idigunjale, ipaniyan, ijinigbe ati ipaniyan awọn ẹlẹgbẹ okunkun ti n waye niluu Eko.
Olori Eso atawọn iṣọmọgbe rẹ da ibẹru-bojo silẹ lagbegbe Mushin atawọn agbegbe mii niluu Eko.''
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ninu ibẹru ati ibanujẹ ọkan lọpọ ẹbi n gbe bayii lẹyin ti wọn ti fara kaasa iṣẹlẹ idigunjale tabi ipaniyan lati ọwọ Akinwande.
O ni bo tilẹ jẹ pe Olori Eso ti n sa lati ipinlẹ kan si omiran fun ọpọ ọdun, ileeṣẹ ọlọpaa pada gba a mu.
''Ẹbi mẹrin ti wa jẹrii wi pe afurasi Olori Eso lo ṣeku pa awọn ọmọ awọn''
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa fikun ọrọ rẹ pe oriṣiiriṣii ibọn ati nnkan ija oloro lawọn ọlọpaa ba nile Olori Eso to wa ni Mushin.
Alukoro ọlọpaa ni Olori Eso funra rẹ lo jẹwọ wi pe awọn ohun ija oloro yii loun atawọn iṣọmọgbe oun maa n lo lati digun jale ati lati ṣeku pa eeyan.
Lara nnkan ija oloro tawọn ọlọpaa ri nile Olori Eso ni ibọn AK-47 meji, ibọn K2 kan, ibọn Red Ryder kan ati ibọn ''pump rifle'' mẹta.
Awọn nnkan ija oloro mii ti wọn ka mọ Olori Eso lọwọ ni ibọn rirọ ibilẹ meji, agolo ọta ibọn mẹtadinlọgọta, aadọrin ọta ibọn 5.56 , ọta ibọn 9mm mẹtadinlọgbọn, ọbẹ ''dagger'' kan, ẹrọ ibaraẹnisọrọ ''walkie-talkie'' mẹta ati iwe irinna mẹsan an fun oniruuru eeyan.
Kọmiṣọna ọlọpaa ti paṣẹ fun igbakeji rẹ wi pe ko dari iṣẹ iwadii ikọ ọlọpaa SCID lati mu gbogbo awọn ọdaran to n ṣiṣẹ pọ pẹlu Akinwande ki gbogbo wọn le foju wina ofin.
Ẹbi mẹrin ọtọtọ ti wa jẹrii wi pe afurasi Olori Eso lo ṣeku pa awọn ọmọ awọn.
Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Olohundare Jimoh, ti fi dawọn olugbe ipinlẹ Eko loju pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ni kaarẹ ninu igbiyanju ati akitiyan rẹ lati pese abo to peye fun wọn.
Olori Eso ti wa ni ahamọ ọlọpaa bayii, ileeṣẹ ọlọpaa si ti sọ pe yoo foju wina ofin.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















