Ọwọ́ ẹ̀ṣọ́ Fijilanté àti ọlọ́pàá ba afurasí ajínigbé méjì pẹ̀lú àjà ilẹ̀ nínú ilé àkọ́patì kan, jìnnì jìnnì ba aráàlú

Ariwo sọ lori ayelujara lori iroyin pe ileesẹ ọlọpaa ri aja ilẹ nilu Epinmi Akoko nipinlẹ Ondo, nibi ti wọn fura si pe awọn ajinigbe lo n lo ile naa lati fi awọn ti wọn ba ji gbe pamọ si.
Iroyin naa ni awọn Afurasi meji ti wọn jẹ ọmọ bibi ilu Epinmi-Akoko, ni ọwọ tẹ ninu ile kan ti wọn gbẹ koto si, ti awọn Vigilante ati Ọlọpaa si ni igbagbọ pe se ni wọn n ko awọn ti wọn ba ji gbe sinu koto naa.
Idi ree ti BBC Yoruba fi morile ilu naa lati tanna wadi ohun to sẹlẹ nibẹ.
Lasiko abẹwo BBC Yoruba silu naa, lati foju ri ile naa ati koto ti afurasi yii ati ojugba rẹ gbẹ, a ri wipe inu igbo, ni ọna oko ni ile naa wa, to si jẹ pe ile ọhun nikan lo da wa ni agbegbe naa.

Koto ti afurasi ajinigbe naa gbẹ sinu ile akọpati oniyara mẹta jin to bẹ gẹẹ, ti a ko le ri ori ẹni to ba wa ninu rẹ nita, o si ni atẹgun, o si rẹ inu rẹ daradara
Ile akọku yii jẹ oni yara mẹta, ti afurasi naa si ri daju pe ohun fi nnkan bo oju ferese rẹ daradara to bẹẹ gẹẹ, ti ẹni to wa nita ko le ri inu ile naa.
Ṣugbọn ohun to jẹ iyalẹnu ni wipe, afurasi ajinigbe yii gbẹ koto si ọkan ninu awọn yara naa, to si jẹ pe koto yii yoo gba o kere tan ẹni mẹrin.
Koto ti ọkunrin yii si gbẹ jin to bẹ gẹ ti wọn ko le ri ori ẹni to ba wa ninu rẹ nita, to si ni atẹgun, ti o si rẹ inu rẹ daradara.
Iwadi BBC Yoruba fihan pe ko ti i pẹ ti afunrasi naa gbẹ koto naa, nitori yẹpẹ to gbẹ jade ni yara naa si wa lẹyin ferese yara ti koto naa wa.
Ibusun ti awọn afunrasi naa sun si, si wa ni inu ile naa.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ Ọlọpaa ati Vigilante ṣe sọ, ọpọlọpọ oogun ati awọn ohun ija oloro, to fi mọ ibọn, ada ati awọn ohun miran ni wọn ri ninu ile naa.

Báwo ni asiri àwọn Afurasí naa se tu sawọn Fijilante lọwọ ?
Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ n'ilu Epinmi Akoko, ọga agba Vigilante ilu naa Yusuf Taofeek Adesanya sọ pe, ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Idowu Arohunmolase lo wa ba awọn wọn pe ohun ri ibọn kan.
Adesanya ni kete ti wọn gbọ ọrọ yii, wọn fi to ọba ilu naa leti, ti Kabiyesi si pasẹ pe ki wọn gbe ọgbẹni Arohunmolase wa si Aafin Ọba naa.
Ọga agba Vigilante naa sọ pe Kabiyesi pasẹ pe ki ọkunrin naa lọ mu ibọn naa wa, sugbọn o sọ pe o ti wa lọwọ Ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Bada Tosin.
Sugbọn Bada kọ lati fi ibọn naa silẹ pẹlu awijare pe Arohunmolase jẹ oun lowo.
Adesanya salaye pe kete ti Kabiyesi gbọ ọrọ naa, o pe Bada pe oun yoo san owo ti Arohunmolase jẹ ẹ, ki wọn le gba ibọn naa lati fun awọn agbofinro.
Ṣugbọn lẹyin gbogbo akitiyan Kabiyesi ilu naa, ti Bada si kọ lati fi ibọn naa silẹ, ni wọn fipa lọ ile awọn obi rẹ lati lọ wa ibọn naa ti wọn ko si ri.
O ni lẹyin o rẹyin, Bada mu wọn lọ ile miran, ile naa ni wọn ti ri ibọn naa, ti wọn si ri ọpọlọpọ oogun to ko sile naa eyi to jẹ iyalẹnu fun wọn.
Ọga Vigilante naa ni wọn funra lasiko ti wọn wọ ile naa, ti wọn si sọ fun pe wọn fẹ yẹ gbogbo yara to wa ninu ile naa wo.
"Sugbọn Bada fariga pe yara ti wọn gbẹ koto si naa jẹ yara ti ohun amusagbara rẹ wa ti ẹnikẹni ko si le wọ inu rẹ.
Amọ ọkan lara awọn akẹẹgbẹ mi ti a jọ jẹ fijilante lo ṣe bi ọkunrin to si wọ inu yara naa.
Kayeefi nla lo jẹ fun wa bi a ṣe ri ọgbun ti ọkunrin naa gbẹ si ọkan ninu yara naa.
Ni kete ti a si ri nnkan yii ni a ke sawọn Ọlọpaa lati wa wo ohun ti oju wọn ri.

Kí ni Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá sọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà?
Alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo, Olushola Alayande lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, sọ ọ di mimọ pe, awọn Vigilante ilu Epinmi lo mu awọn afunrasi naa, ti wọn si fa a le ileesẹ ọlọpaa lọwọ.
Alayande sọ pe ni kete ti wọn gbọ ọrọ naa ni ọga ọlọpaa ni agbegbe Epinmi gbe igbesẹ lori isẹlẹ naa.
"Iyalẹnu lo jẹ pe a ba ọgbun nla ninu ile naa pẹlu ọpọlọpọ ohun ija oloro ati ibọn pẹlu awọn oogun lorisirisi.
Gbogbo ohun ti ileeṣẹ Ọlọpaa ri loriko naa safihan pe afunrasi Ajinigbe ni awọn teeyan to hu iru iwa yii, iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa."
Alayande fikun pe ni kete ti iwadii ba pari, wọn yoo gbe awọn afunrasi naa lọ sile ẹjọ, awọn si ti ni ọpọlọpọ ẹri lati sagbekale ẹjọ naa niwaju adajọ.
Kí ni àwọn ará ìlú Epinmi Akoko sọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ naa?
Ọkan lara awon olugbe ilu naa, Femi Ojo ati Ajayi Atewogboye to ba BBC Yoruba sọrọ sọ pe iyalẹnu nla gba a lo jẹ fun wọn lasiko ti wọn de oriko naa.
Wọn sọ di mimọ pe, ibẹrubojo ti mu gbogbo awọn ara ilu nitori ọna oko ni ile naa wa, eyi to safihan pe, ko si aabo lori awọn ara ilu.
"Ilu Epinmi Akoko jẹ ilu alalaafia, inu wa si dun pe ọwọ tẹ awọn ẹda to n da ilu naa ru.
A wa n gboriyin fun awọn ẹsọ Figilante ati awọn Ọlọpaa fun isẹ takuntakun ti wọn se, awa araalu yoo si tubọ maa fọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro lati le fọ ilu yii mọ patapata".















