"Nnamdi Kanu ní kí a sin òkú adarí Ipob pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún méjì orí èèyan, a ti pa ọgbọ̀n èèyàn kí ọwọ́ ọlọ́pàá tó tẹ̀ wá"

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Igbẹjọ aṣaaju ikọ IPOB, Nnamdi Kanu, tun tẹsiwaju niwaju adajọ James Omotoso tile ẹjọ giga tilu Abuja.
Nibi igbẹjọ naa si ni ẹlẹri fun ikọ agbefọba ti salaye pe o to eeyan bii igba ti ẹgbẹ IPOB ti ijọba ti fofin de naa, pa lẹkun ila oorun Naijiria.
Ẹlẹri naa, Ọgbẹni DDD, lo jẹ ẹlẹrin kẹrin ti yoo jẹri fun ijọba Naijiria nile ẹjọ lati igba ti igbẹjọ naa ti bẹrẹ.
DDD yii si jẹ osisẹ ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS fun orilẹede yii, ẹni to sisẹ ni ipinlẹ Imo laarin ọdun 2019 si 2022.
Ẹlẹrin naa wa salaye ni ẹkunrẹrẹ bi ikọ ọtẹlẹmuyẹ DSS se lo awọn ẹrọ igbalode lati se awari ibi ti redio kan ti Kanu gbe wọ orilẹede yii wa, to si gba a kuro lọwọ rẹ.
O fikun pe "lẹyin akitiyan wa, a ri ẹrọ alatagba redio naa ninu ile ẹru kọntena kan nilegbe ọkunrin kan, Benjamin Madubugwu ni agbegbe Ubuluisiuzor nilu Ihiala nipinlẹ Anambra.
Koda, lasiko ti a wa inu ile Madubugwu naa, a ri ibọn igbalode meji ninu yara ibusun rẹ, a si ti mu ọkunrin naa.
Gẹgẹ bi ẹlẹri DSS se wi, Madubugwu sọ fun awọn pe ọkunrin kan to pe orukọ rẹ ni Igwe Anyiba, lo bẹ oun pe ki oun ba oun gbe ile ẹru ọhun si agbala ile oun, ti wọn yoo si fun oun ni ile ẹru naa lẹyin ti ẹni to ni i ba wa ko awọn ẹru to wa ninu rẹ.
Ọgbẹni DDD sọ pe nigba ti wọn mu Kanu, wọn jẹ ki oun ati Benjamin Madubugwu fojukoju, ti Kanu si sọ pe oun loun ni ile ẹru naa ati redio alatagba ọhun.
Amọ bi igbẹjọ naa ṣe n tẹsiwaju ni Onyechi Ikpeazu, to jẹ ọkan lara awọn agbẹjọro Kanu sọ pe, ileeṣẹ kan ti orukọ rẹ n jẹ "Denca clearing and forwarding agency" lo gbe ile ẹru naa wọ Naijiria lati ilẹ okere.
"Kanu paṣẹ fun IPOB lati pa agbofinro 200, wọn fi wundia mẹwaa ṣetutu aabo fun ara wọn, awọn si lo dana sun ọgba ẹwọn kan nipinlẹ Imo"
Lasiko to n jẹri naa, ọgbẹni DDD mẹnuba ọkan lara awọn adari IPOB, Benjamin Uzoma, ti apele rẹ n jẹ Onye Army ti ọlọpaa mu, to si jẹwọ pe oun ti wu oniruru iwa ọdaran sẹyin.
Adegboyega Awomolo, to jẹ agbẹjọro ijọba apapọ mu iwe iroyin Vanguard ti wọn gbe jade lọjọ kẹta, oṣu Keje, ọdun 2021 nibi ti iroyin bi wọn ṣe mu ọkunrin naa wa.
Ninu iroyin ọhun ni Onye Army ti sọ pe, Nnamdu Kanu sọ fun awọn pe ki wọn sin oku ọkan lara awon adari wọn, Iko Nso, ti ọlọpaa ṣekupa pẹlu ẹgbẹrun meji ori eeyan.
O wa kede pe awọn si ti pa ọgbọn eeyan ki ọwọ ọlọpaa to tẹ awọn.
Ninu iwe iroyin naa tun ni Onye Army ti jẹwọ pe, Kanu paṣẹ fun awọn lati maa pa awọn agbofinro, tí awọn si fi wundia mẹwaa ṣetutu aabo funra wọn ati pe awọn ọmọ ogun Ipob lo dana sun ọgba ẹwọn kan nipinlẹ Imo.
DDD sọ siwaju si pe DSS fẹ fi ọrọ wa afurasi naa lẹnu wo amọ ọlọpaa sọ pe o ti salọ kuro ni ahamọ awọn, awọn ko si ti i ri lati igba to ti salọ.
O ṣalaye nipa bi DSS ṣe ya bo agọ awọn ọmọ ogun Ipob ninu igbo kan ni ipinlẹ Imo ati Anambra, ti awọn si ri pe awọn eeyan naa n jẹ ẹran ara eeyan fun aabo.
Lapapọ, DDD sọ pe apapọ iye awọn agbofinro ti Ipob ti ṣekupa ko din 170 si 200.
O ni fun apẹrẹ, Ipob ti kọlu agọ ọlọpaa ri ti wọn pa gbogbo awọn to wa nibẹ, ti wọn si sọ agọ ọlọpaa ọhun di ibi ti wọn ti n ṣọṣẹ.
O fi kun pe Ipob lo pa Ahmed Gulak to lọ ṣabẹwo si gomina Hope Uzopdinma lọjọ Aje kan ti wọn ki n gba ki ẹnikẹni ṣiṣẹ.
"Kanu lo ṣokunfa iwọde EndSARS lọdun 2020, nibi ti ọlọpaa 128 ti ku, ọmọ ogun 37 ati oṣiṣẹ DSS mẹwaa"
Awọn agbẹjọro Nnamdi Kanu ti sọ pe awọn yoo pe ẹjọ kan tako ẹsun igbesunmọmi ti ijọba apapọ fi kan an.
Ọkan lara awọn agbẹjọro Kanu, Kanu Agabi lo sọ bẹẹ lẹyin ti Adegboyega Awomolo to jẹ agbẹjọro ijọba sọ pe, awọn ti pari awijare wọn lori ẹsun ti ijọba fi kan olujẹjọ naa.
Nibi igbẹjọ ọhun to waye lọjọbọ, Adegboyega ke pe ẹlẹri ijọba, ọgbẹni EEE (kii ṣe orukọ abisọ rẹ), to jẹ ọkan lara awọn oṣiṣẹ DSS.
Ẹlẹri naa ni oun wa lara awọn to ṣe iwadii atubọtan iwọde EndSARS to mi Naijiria titi lọdun 2020.
O ni lasiko iwadii naa loun rinrinajo kaakiri awọn ipinlẹ ti iwọde naa ti waye kaakiri Naijiria.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, abọ iwadii igbimọ naa fi han pe apapọ ọlọpaa to ba iwọde naa lọ jẹ 128, ọmọ ogun 37 ati oṣiṣẹ DSS mẹwaa.
O fi kun pe awọn eeyan dana sun agọ ọlọpaa 164 ati ọọfisi INEC mọkandinlogun.
Ninu alayẹ ọgbẹni EEE, o ni awọn ọrọ ti Kanu ti n sọ fun ọpọ ọdun wa lara nnkan to ṣokunfa iwọde endSARS naa.
O ni "Gẹgẹ bii onimọ nipa eto aabo, mo mọ pe ohun meji lo n ṣokunfa ifẹhonuhan, ohun ti awọn eeyan foju ri ati eyii ti wọn ko fi oju ri to jẹ gbogbo iwọde naa."
Lẹyin atotonunu awọn agbẹjọro ikọ mejeji, adajọ Omotosho ti sun ogbẹjọ naa si ọjọ Ẹti, ọjọ kejidinlogun, oṣu Keje, ọdun 2025.















