Ṣàdéédé ni ọkùnrin kan bọ sílẹ̀ lórí ọkàdá, yínbon lú oní POS àti ọmọ rẹ̀ ní ìlú Ibadan- Óṣojúmikòró

Aworan
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ati oṣojumikoro ti ṣalaye bi iṣẹlẹ idigunjale ṣe waye niluu Ibadan.

Iṣẹlẹ ọhun lo waye ni agbegbe Mokola niluu Ibadan.

Oṣojumikoro to ba BBC sọrọ ni bi aago mejila aabo ọsan ni okunrin kan ti ẹnikẹni ko ti mọ orukọ rẹ kuro ninu baanki igbalode kan to wa ni agbegbe Dugbe

O ni ọkunrin naa n ba ọmọ re obinrin sọrọ lẹba ọna, nigba ti okunrin kan ṣadede bọ silẹ lori keke alupupu Okada kan, to si sina bolẹ.

Ninu apejuwe odaran naa, ẹni ti iṣẹlẹ naa soju ni aṣọ dudu ni afurasi ọdaran naa wo, to si tun de fila dudu le lori, o ni awọn ro wi pe ẹni mimo okunrin oniṣowo POS ni sugbọn nigba ti o yinbon akọkọ ni ọpọ to mo wi pe adigunjale ni okunrin naa.

Aworan ile iwosan UCH

Oṣiṣẹ ajọ OYRTMA ti iṣẹlẹ naa soju rẹ ni igba meji ni okunrin ọdaran naa yinbo lu oniṣowo POS ọhun ṣugbọn ìbọn elekeji lo baa lẹyin mo ibi itan rẹ.

O ni nise ni gbogbo awọn to wa nibi iṣẹlẹ naa salo ki wọn to pada lati gbe okunrin oniṣowo POS naa lo si ile iwosan Alafia to wa ni agbegbe naa.

Dokita Adesanya Adeola ti ile iwosan Alafia to wa ni agbegbe Mokola ba BBC sọrọ,to si jẹ ko di mimọpe lootọ ni wọn gbe ọkùnrin naa wa si ile iwosan Alaafia, sugbọn itọju didola ẹmi nikan lawọn fun ki wọn to gbẹ lọ si ilewosan UCH fun itọju to peye.

Iwaadi akọroyin BBC Yoruba fihan wi pe aago mẹfa irolẹ ana ni wọn gbẹ ọkunrin ti ibọn ba naa lọ si ile iwosan UCH nibi ti wọn ti yoo ọta ibọn lara rẹ.

Oga agba kan ni UCH ẹni ti ko fẹ ka da orukọ ohun fidi rẹ mule wi pe looto ni wọn gbe ọkunrin naa waa ti wọn si ṣe ìṣe abẹ fun lesekese, lọwọlọwọ bayii ara rẹ ti n bo sipo.

Gbogbo igbiyanju akọroyin BBC Yoruba lati ri okunrin naa lọ jasi pabo.

Ki ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ?

Nigba ti a n kan si, Agbẹnusọ ileese olopaa Oyo, Adewale Osifeso fi idi isele naa mule, to si jẹ ko di mimọ pe ẹnikẹni kọ ba iṣẹlẹ naa lọ.

O fikun pe bo tilẹ jẹ wi pe ibon ba awọn eeyan meji, ti won si farapa, sugbon o tako ọrọ aheso kan to wi pe, ikolu naa sẹlẹ ni banki kan.

Osifesofidi rẹ mule wi pe labe afara Mokola ilu ibadan ni iṣẹlẹ naa ti waye.

O ni iwadii ti bere lori isele naa, o si ro awọn araalu lati ma ṣe iṣẹ wọn lọna to ba ofin mu.

Àlàyé rèé lórí ìkọlù àwọn adigunjalè ní Mokola, Ibadan, níbi tí èèyàn mẹ́ta ti fara gbọta

Àwòrán èèyàn tí ìbọn bá tí wọ́n ń gbé

Oríṣun àwòrán, connectibadan/Instagram

Níṣe ni ọ̀rọ̀ di ẹni orí yọ ó dilé lánàá, ọjọ́rú, ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kẹfà ní agbègbè Mokola ní ìlú Ibadan, olú ìlú ìpínlẹ̀ Oyo báwọn Adigunjalè sẹ ṣèkọlù sáwọn ilé ìtajà kan ní agbègbè náà.

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́, wọ́n ní níṣe láwọn adigunjalẹ̀ náà ṣíná ìbọn bolẹ̀ nígbà tí wọ́n dé ọjà náà.

Wọ́n ní kò dín ní èèyàn mẹ́ta tó farapa nínú ìkọlù àwọn adigunjalè ọ̀hún àti pé wọ́n gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó lọ.

Àwọn tí ọ̀rọ̀ ṣojú wọn sọ pé àwọn tó farapa nínú ìkọlù náà ni wọ́n ń gbìyànjú láti wọnú ilé ìtajà náà.

Báwo ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé?

Lára àwọn fídíò tó gba orí ayélujára èyí BBC News Yorùbá rí ṣàfihàn bí wọ́n ṣe ń gbé àwọn èèyàn tó fara gba ọta ìbọn níbi ìkọlù náà dìgbàdìgbà.

Nínú fídíò náà ni a ti rí ọkùnrin kan táwọn èèyàn méjì ń gbìyànjú láti gbé nítorí kò ríbi rìn mọ́ tí èèyàn kan sì ń sọ níbẹ̀ pé ọta ìbọn àwọn adigunjalè náà ló ba.

Bákan náà ni a rí àwọn òṣìṣẹ́ àjọ tó ń mójútó ojú pópó ní ìpínlẹ̀ Oyo tí wọ́n ń gbìyànjú láti ran arákùnrin náà lọ́wọ́, tí wọ́n sì fi ọ̀kadà gbe lọ sílé ìwòsàn.

Àwọn tí iṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn sọ pẹ níṣe ni àwọn adigunjalè náà yìnbọn sókè fún ọ̀pọ̀ ìṣẹ́jú láti fi dẹ́rù ba àwọn èèyàn, tí ìbọn náà sì lọ ba àwọn èèyàn.

Wọ́n ní láàárín ìṣẹ́jú péréte ni ìdigunjalè náà fi fáyé, táwọn adigunjalè ọ̀hún sì na pápá bora káwọn ọlọ́pàá tó dé síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Ìròyìn ní àwọn èèyàn tó farapa nínú ìkọlù náà ni wọ́n ti gbé lọ sílé ìwòsàn tó wà ní agbègbè náà fún ìtọjù.

Kí ni ọlọ́pàá sọ?

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Oyo, Adewale Osifeso fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, tó sì ṣàlàyé pé ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Osifeso fi kun pé kò sí ẹnikẹ́ni tó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìkọlù náà, tó sì ṣèlérí pé gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni àwọn máa fi póró òfin gbé.

Ó fi kun pé bí ìwádìí àwọn bá ṣe ń lọ lórí ìkọlù náà ni àwọn yóò máa fi tó aráàlú létí.