Farouk Oreagba ní ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti fún òun ní ìyàwó lórí ayélujára, tí wọ́n tún ń bá ara wọn jà torí òun

Àkọlé fídíò, Farouk Oreagba ní ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti fún òun ní ìyàwó lórí ayélujára, wọ́n tún ń bá ara wọn jà torí òun
Farouk Oreagba ní ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti fún òun ní ìyàwó lórí ayélujára, tí wọ́n tún ń bá ara wọn jà torí òun

Ni ọdọọdun ti ọdun Ojude Ọba ba n waye nilu Ijebu Ode, nipinlẹ Ogun, ọkan lara awọn gbajumọ ti ọpọ eeyan ba n foju sọna lati ri ni ọkunrin kan ti wọn n pe ni Farouk Adedayo Oreagba.

Idi ni pe o maa n gun ẹsin ni ọna to n da ọpọ eeyan lọrun, ti wọn si fun ni apejẹ orukọ kan, 'Mr Steeze'

Idi ree ti BBC fi wa ọkunrin yii kan lasiko ọdun Ojude Oba to kọja, ẹni to salaye fun wa nipa igbe aye rẹ, bi idile rẹ se ri, ifẹ ti awọn eeyan ni fun lori ayelujara ati awọn ipenija to ti la kọja.

Koda, o ni o le ni ọdun mẹẹdọgbọn ti oun ti n lọ si ọdun Ojude Oba, ki okiki oun to kan ni ọdun 2024, eyi to sọ oun di gbajumọ ati ilumọọka.

Farouk Oreagba

"Wọn n pe mi ni Mr Steeze, emi gan ko mọ itumọ rẹ, ohun ti mo n se lati ọdun mẹẹdogun sẹyin ni mo se, Ọlọrun ọba lo ni ko ri bẹẹ"

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Farouk Oreagba ni ọmọbibi ilu Ijebu Ode ni oun, agboole Oreagba si ni oun ti wa, ọdun 2005 si ni oun ti bẹrẹ si bawọn peju si ọdun Ojude Oba.

"O ti to ọgọrun ọdun ti wọn ti n gun ẹsin ni idile Oreagba ti mo ti wa.

Kii se pe a ti seto kalẹ pe ki okiki mi kan ni Ojude Oba, koda, ori ẹsin ni mo wa, ti ọmọ mi kan fi sọ fun mi pe okiki mi ti kan lori ayelujara nipa bi mo se n gun ẹsin.

Wọn n pe mi ni Mr Steeze, emi gan ko mọ itumọ orukọ naa, ọmọ mi kan lo n salaye rẹ fun mi.

Ohun ti mo ti n se lati ọdun mẹẹdogun sẹyin naa ni mo se, Ọlọrun ọba lo pinnu pe bo se maa ri niyẹn.

Wọn fi orukọ mi se orisirisi orin, wọn fi siga mi se ẹfẹ, amọ ko si eyi to bi mi ninu."

"Gbogbo awọn to ti fun mi ni iyawo lori ayelujara, n ko pade ọkankan ninu wọn, mi o ba ẹnikankan ninu wọn jade"

Farouk Oreagba siwaju pe oun maa n ba an ololufẹ oun se ẹfẹ lori ayelujara ni, boya Instagram ni abi Facebook.

"Gbogbo awọn to ti fun mi ni iyawo lori ayelujara, n ko pade ọkankan ninu wọn, mi o ba ẹnikankan ninu wọn jade.

Wọn maa n ni ololufẹ mi, ọkọ mi, daddy mi ni, awada to dara ni a n se lori ayelujara.

Wọn n pe mi ki n wa polowo ọja, mo n rin irin oge, fi ontẹ lu ọja kan ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ohun to se koko si mi ni isẹ to n san owo osu mi tori osisẹ ile ifowopamọ ni mi.

Gbogbo nnkan yoku, opin ọsẹ ni mo n se."

Farouk Oreagba ati ẹsin rẹ

"Ẹ wo, ile aye le, bi awọn kan n ba mi yọ, ni awọn kan n binu si mi"

Bakan naa ni Farouk Oreagba tun mẹnuba awọn idojukọ to n ri lọdọ awọn eeyan, paapaa awọn to duro bi ọta rẹ.

"Ẹ wo, ile aye le, bi awọn kan n ba mi yọ, ni awọn kan n binu si mi.

Bi awọn se n sọ pe Mr Steeze ni awọn kan wa ba mi pe se emi nikan ni.

Emi ko le maa da nikan jẹ, awọn ipolowo ọja kan ti mo kọ amọ ti wọn gbe fun ọmọ ẹgbọn mi kan."

"Nnkan le nigba ti mo se aisan, ọdun mẹjọ gbako ni mo fi gba oogun Chemotheraphy, o nira pupọ eyi si mu ki ayipada ba oju ti mo fi n wo ile aye"

Farouk Oreagba tun salaye fun BBC Yoruba nipa aisan to la kọja to nii se pẹlu arin jẹjẹrẹ inu egungun.

"Nigba ti mo se aisan, ohun ti mo mu ni koko yipada.

Nigba ti mo saisan, mo ni ọrẹ bii miliọnu kan amọ mo ri boya bii aadọta, bi owo ba wa lọwọ rẹ, ọrẹ maa pọ.

Nnkan le nigba ti mo se aisan, ọdun mẹjọ gbako ni mo fi gba oogun Chemotheraphy, o nira pupọ eyi si mu ki ayipada ba oju ti mo fi n wo ile aye.

Mo pada di eeyan jẹjẹ, mo n kirun si Ọlọrun mi, mo si n se faaji o amọ ibi ti mo ti n mu igo kan tẹlẹ, mo n mu ife kan pere."

"Ọmọ meji ni obi mi bi, ọmọ ọdun mẹrin ni mi nigba ti baba mi ku, ọjọ ti iya mi pari idanwo asejade nile ẹkọ fasiti ni baba mi ku"

Oreagba, ẹni to salaye itumọ awọn aworan Tatoo to ya sara sọ eyi to ya lati sọri iyawo rẹ, ọmọ ati iya rẹ.

Bakan naa lo salaye bi igba ewe rẹ se ri ati ọpọ iriri to la kọja.

"Iya ati baba mi bi ọmọ meji, ẹgbọn mi ati emi, amọ ọmọ ọdun mẹrin ni mo wa, nigba ti baba mi ku.

Ẹni ọgbọn ọdun ni mama mi wa nigba ti baba mi ku, ọjọ ti iya mi pari idanwo asejade nile ẹkọ fasiti ni baba mi ku.

Baba mi ko se aisan rara, wọn ba ara wọn sọrọ ni aarọ, ti baba si wi fun pe yoo se aseyọri nidi idanwo rẹ, amọ nigba ti iya mi yoo fi de, ọkọ rẹ ti ku.

Iya mi ko fẹ ọkọ miran, o n tju emi ati ẹgbọn mi, ti a si gbe ilegbe to wa fun awọn osisẹ ninu ile kan, titi ti a fi dagba."