Ojude Oba ti di ọjà àgbáyé, ètò ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ Ogun náà sì ti gun òkè àgbà - Dapo Abiodun

Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ti ṣe alaye wi pe ayẹyẹ ọlọdọọdun to maa n waye niluu Ijebu Ode, 'Ojude Ọba' ti di ọja ti gbogbo aye n na, ọja yii si ti pakun eto ọrọ aje ipinlẹ Ogun l'apapọ.
Ninu ọrọ ti o sọ nibi ayẹyẹ Ojude Ọba t'ọdun yii to waye lọjọ Aiku ni gbagede Ọba ti ọpọ eeyan mọ si 'Pavilion', Gomina Abiọdun ni gbogbo ile itura to n bẹ niluu Ijebu Ode ati ayika rẹ ni awọn alejo to wa fun ayẹyẹ naa gba tan, bẹẹ sini awọn oniṣẹ ọwọ naa ri ti aje ṣe.
Abiọdun fi kun ọrọ rẹ pe ayẹyẹ Ojude Ọba t'ọdun yii lo tobi julọ lati igba ti wọn ti n ṣe ayẹyẹ naa nitori ọkan ọpọlọpọ awọn ọdọ lorilẹede Naijiria ati ni oke okun ti fa si ajọdun naa.
Gomina ipinlẹ Ogun fi kun ọrọ rẹ wi pe Ojude Ọba kii ṣe ibi ayẹyẹ ti a ti n rin yan fanda ninu aṣọ alaranbara nikan, bikoṣe akanṣe eto ọlọdọdun ti a fi n ṣe akọsilẹ itan fun awọn iran to n bọ lẹyin.
O ni ayẹyẹ naa ti fi orukọ ilu Ijẹbu Ode ati ipinlẹ Ogun si ẹnu ọpọlọlọpọ eeyan lode agbaye, gẹgẹ bi o ṣe n pa kun eto ọrọ aje ipinlẹ naa.


Nitori idi eyii si ni ipinlẹ naa yoo si fi tẹsiwaju lati maa jiroro pẹlu awọn ileeṣẹ ati ajọ ti o le mu okiki ipinlẹ Ogun kan si i lode agbaye.
O ni gbagede ti wọn lo fun Ojude Ọba ko gba ero mọ, o si ṣe ileri wi pe ijọba oun yoo wa nnkan ṣe si i.
Gomina Abiọdun dupẹ lọwọ igbimọ to ṣe eto Ojude Ọba ọdun yii fun iṣẹ ribiribi ti wọn ṣe, o gbe oṣuba kare fun Awujalẹ ilẹ Ijẹbu, Ọba Sikiru Adetọna ati awọn alejo pataki to fi ara han nibi ipejọpọ naa.


Lara wọn ni Minisita fun aṣa ati idagboke eto ọrọ aje nipasẹ ọgbọn atinuda, Hannatu Musawa, igbakeji Gomina ipinlẹ Ondo, Olayide Adelami, Gomina tẹlẹri n'ipinlẹ Ogun, Oloye Oluṣẹgun Oṣọba, Olori Awujale ilẹ Ijẹbu, Adekemi Adetona ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Awọn oṣere tiata bii Wale Ojo, Adedimeji Lateef ati Femi Branch ko gbẹyin nibi ipejọpọ naa.
Ọkanojọkan idile ati ẹgbẹ ẹlẹṣin to wọ aṣọ alaranbara lo rin yan fanda niwaju awọn alejo pataki to fi ara ha nibi ayẹyẹ naa.
Gbajúmọ̀ òṣèré, Lateef Adedimeji, Femi Branch, Farooq Oreagba di arímálèélọ níbi ayẹyẹ Ojude Oba

Bi ayẹyẹ Ojude Ọba ọdun yii ṣe n lọ lọwọ ni ọpọ eeyan lati ẹka iṣẹ kaakiri n gunlẹ sibẹ.
Eyi ko yọ awọn onitiata ilẹ wa silẹ pẹlu, paapaa awọn ẹlere Yoruba.
Ọkanojọkan awọn eekan ilu lo wa nibi ayẹyẹ ojude ọba ti ilu Ijẹbu to waye lọdun yii. Lara awọn ilumọọka naa ni gbajumọ oṣere, Lateef Adedimeji pẹlu Fẹmi Branch.
Wiwọle ti awọn eekan mejeji yii wọle si ibudo ayẹyẹ naa ni ariwo sọ ti awọn ololufẹ wọn si n ki wọn ni mẹsan mẹwaa.

BBC ṣalabapade agba oṣere, Femi Branch ati Lateef Adedimeji toun naa jẹ gbajugbaja onitiata nibi ayẹyẹ yii.
Ki i ṣe pe awọn oṣere naa waa woran lasan, wọn mura to fi aṣa Yoruba han, wọn si kopa ninu eto naa bo ṣe n lọ.
Ọmọ Gbagura, l'Abeokuta ni Lateef Adedimeji, nigba ti Femi Branch jẹ ọmọ ilu Sagamu, nipinlẹ Ogun kan naa.

Bakannaa ni Ọgbẹni Farooq Ọrẹagba to di ilumọọka nipasẹ imura rẹ lasiko ayẹyẹ ojude ọba lọdun 2024 pẹlu ko gbẹyin.
Ggẹbi iṣe rẹ O tun ro dẹdẹ kan dudu ninu aṣọ igunwa rẹ lori ẹṣin pẹlu.

Lara awọn eekan ilu miran to wa nibẹ ni gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Ogun, Sẹnatọ, Gbenga Daniel, Olori Adekẹmi Adetọna to ṣoju Kabiyesi Awujalẹ, Igbakeji gomina ipinlẹ Ondo; Olaide Odunlami.



Lonii yii ti i ṣe ọjọ kẹta ọdun Ileya, iyẹn ọjọ Aiku, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa ọdun 2025 gan-an ni ayẹyẹ Ojude-Ọba niluu Ijebu-Ode, ipinlẹ Ogun.
Ẹ o ranti pe bi wọn ṣe n palẹmọ ọdun Ileya to waye lọjọ Ẹti to kọja yii naa ni irọkẹkẹ ti n waye fun ayẹyẹ Ojude-Ọba pẹlu.
Aago mẹwaa owurọ oni lo yẹ ki eto naa bẹrẹ ṣugbọn lati idaji ni ero ti yabo gbagede 'Pavilion' ti eto naa yoo ti waye.
Ọkanojọkan aṣọ alaranbara ni awọn idile ati ẹgbẹ kọọkan ti yoo rin yan fanda niwaju Awujalẹ ilẹ Ijẹbu wọ wa si ibi akanṣe eto naa.

Gbogbo obinrin ti ko we gele wa lati ile ati awọn ti ko ranti kun atike ni wọn lanfaani lati ṣe atunṣe nitori awọn abani we gele ati awọn to n mu oju rẹwa wa ni ikorita kọọkan nibi ti eto naa yoo ti waye.
Bi awọn onilu ṣe n ki awọn alejo kaabọ naa ni awọn ẹṣọ aabo duro wamuwamu.
Bo si tilẹ jẹ pe awọn Ijebu ni wọn gbe eto naa kalẹ lati ṣafihan bi aṣa Yoruba ṣe wuyi to si rẹwa to, Ojude-Oba ti di itẹwọgba kaakiri agbaye.
Ṣaaju ni BBC ti kalẹ si Ijebu-Ode ti ayẹyẹ alaranbara naa ti n waye, ti a si fi n to yin leti nipa ara oriṣiiriṣii ti awọn ọmọ Ijebu n da.
Wọnyi ni awọn iran aranbara ti ẹ o maa ba pade lonii lati Ojude Oba.



Ẹṣin gigun
Wọn maa n gbe Ẹyọ pẹlu.
Ere ibilẹ
Ibọn yinyin lati fi ki awọn ọlọla
Rẹgbẹrẹgbẹ:
Eyi ni akojọpọ awọn ẹgbẹ ọtọọtọ ti ọjọ ori wọn jẹ bakan naa.
Wọn aa mura lọna ibilẹ Yoruba, aṣo oke yoo maa pe ara wọn ran niṣẹ loju agbo.
Wọn yoo to lọwọọwọ, wọn yoo maa jo kọja niwaju Olori Ọba Ijebu, Kabiyesi Sikiru Adetona ti i ṣe Awujale ilẹ Ijebu.



Wọn yoo maa wure pẹlu, wọn yoo si maa fi ẹbun ọlọkan-o-jọkan funra wọn.
Oniruuru ounjẹ ilẹ Ijebu ati ti Yoruba lapapọ ni yoo kun ibi ayẹyẹ yii.
Bẹẹ ni awọn gbajugbaja kaakiri agbaye ni yoo wa nikalẹ, titi kan awọn alawọ funfun.
Ọna kan lati tun mu ọrọ aje ru gọgọ ni pẹlu, nitori karakara ati ṣiṣe onigbọwọ awọn eto kan tun maa n waye.
Awọn ileeṣẹ nla-nla yoo waa polowo, ṣafihan ọja wọn.
Ọpọ eeyan ti ki i ṣe ọmọ Ijebu paapaa maa n ti ilẹ okeere waa woran yii.
Bẹẹ ni awọn ọmọ Alarẹ kaakiri agbaye naa ti mu ikalẹ alaafia bayii, wọn ṣetan ti wọn fẹẹ kopa ninu Ojude Ọba 2025 bo ṣe n gbera sọ.














