"Mo pàdánù ogún èèyàn tó jẹ́ ẹbí mi, ilé, ṣọ́ọ́bù àti dúkìá sínú ìṣekúpani tó wáyé ní Benue, kò sí owó, kò sí aṣọ"

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ọkan ninu eeyan ti ori koyọ ninu iṣẹlẹ iṣekupani to waye ni Yelwata nijọba ibilẹ Guma nipinlẹ Benue sọrọ sita pẹlu ibanujẹ, to si sọ bi awọn agbebọn ṣe ṣekupa awọn mọlẹbi rẹ, tun dana sun ile wọn.
Ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu News Central, Michael Ajah ni ogun eeyan ni oun padanu lasiko iṣẹlẹ naa.
"Awọn eeyan mi, awọn mọlẹbi, wọn ku sinu ile yii.
Awọn kan ku ni yara, awọn kan ku sibi. Gbogbo mọlẹbi mi pata lo ku lana, ni ọjọ iṣẹlẹ ati ana ode yii."
"Awọn mọlẹbi mi niyẹn. N ko sọrọ nipa nnkan mii. Awọn eeyan mi niyẹn."
O fikun pe oun tun padanu dukia ati awọn ọja rẹ sọwọ ikọlu .
"Ile itaja mi ree, awọn sọọbu yii lo jẹ ti temi, awọn sọọbu yii ti jona, ile mi wa loke, oun naa ti jona.
"Gbogbo ibi ti mo awọn ọja mi si pata lo jona, Wọn jo aṣọ mi, ounjẹ mi, ati awọn mọlẹbi.
"Oun ti a wọ sọrun yii nikan ni aṣọ ti a ni, Bi mo ṣe wa, aṣọ yii nikan ni mo ni, ko si nnkan lọwọ mi."
Bawo ni iṣẹlẹ iṣekupani yii ṣe waye?
Gomina ipinlẹ Benue, Hyacinth Ajah sọ fun awọn akọroyin bi iṣẹlẹ naa ṣe waye, bi awọn agbebọn ṣe kọlu agbegbe Yelwatani ooru ọganjọ.
"Ni ọjọ ti a n wi yii, ojo bẹrẹ ni irọlẹ. A wọle, ti a si lọ sun. Ni bi ago mẹwaa ni a bẹrẹ si ni gbọ iro ibọn. Ka to ni ka beere ohun to sẹlẹ, awọn fulani yii ti wọle si wa lara.
O fikun pe o da oun joju pe awọn agbebọn yii jẹ Fulani nitori oun gbọ ọrọ bi wọn ṣe n sọrọ.
"Wọn n sọrọ, mo si wa ninu ile ti mo n gbọ wọn. Mo gbọ wọn daada, ko ki n ṣe pe eeyan kan sọ fun mi. Mo wa ninu yara nigba ti wọn yabo wa ṣugbọn ori ko mi yọ. Wọn sun ẹgbọn mi ati baba mi mọle. Ori ko awọn kan yọ.
Ninu ifọrọwerọ mi, olugbe mi, Bature Bartholomew, ni oun padanu aburo, ẹgbọn iyawo ati iya rẹ ninu ikọlu naa, o ni gbogbo wọn ni wọn sun mọle.
Bartholomew fikun pe oun tun padanu ọpọ dukia ati ọja tita ti wọn sun mọle.
He said, "N ko le sọ pato nitori owo ọja naa pọ. Mo ni agbado, irẹsi ninu sọọbu mi.
"Aburo to n gbe nibi, ti jade laye, wọn sun mọle. Oun pẹlu iyawo rẹ, iya ati ọpọ eeyan to n gbe ni ile yii."
Iléeṣẹ́ ológun fẹ́ gbé ìjà lọ káwọn agbébọn mọ́lé bí ọ̀pọ̀ aráàlú ṣe korò ojú síjọba lórí bó ṣe kúnà láti pèsè ààbò tó péye

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Gomina ipinlẹ Benue, Hyacinth Alia ti sọ pe ori omi lawọn agbebọn to kọlu ilu Yelewata, ni ijọba ibilẹ Guma gba wọle sibẹ.
Alia ni ibi ti awọn ọlọpaa atawọn ologun n duro si ni awọn agbebọn ọhun kọkọ kọlu, ki wọn to lọ kọju ija si awọn eeyan agbegbe ọhun.
O le ni igba eeyan ti awọn agbebọn naa gbẹmi wọn ni Yelewata.
Nigba to n sọrọ pẹlu awọn akọroyin, Alia ni nnkan bii wakati meji gbako lawọn agbebọn ọhun fi ṣọṣẹ.
O ni "Ohun to ṣẹlẹ ree; odo naa ko jina si agbegbe ọhun, ohun lo jẹ ki a mọ pe eti odo naa ni wọn gba wọle.
"Wọn le wọn pada lati Apa lasiko ti wọn n lọ si ipinlẹ Nasarawa, ala ile kan naa lo wa laarin Yelewata ati Nasarawa – asiko ti wọn n lọ si Nasarawa ni wọn ṣe ikọlu ọhun.
"Nigba ti wọn de ilu naa, ohun ti wọn kọkọ ṣe ni pe wọn kọlu awọn ọlọpa atawọn ologun to maa n ṣọ oju ọna agbagbe naa.
Ileeṣẹ ologun ati ọlọpaa ti n wa awọn to ṣiṣẹ laabi naa
Ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ati ileeṣẹ ọlọpaa ti pa ọwọ pọ lati ṣawari awọn agbebọn to gbebọn gbẹmi eeyan ti iye wọn to igba ni Benue.
Ọga agba ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria, Christopher Musa ati ọga ileeṣẹ ọlọpaa, Katode Egbetokun lọ si ipinlẹ naa lọjọ Aje lati ba awọn eeyan ipinlẹ naa kẹdun ati lati bẹrẹ iṣẹ lori bi ọwọ yoo ṣe tẹ awọn to ṣiṣẹ naa.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, Musa sọ pe "Iṣekupani yii ti to gẹ, a wa nibi lati ri daju pe irufẹ nnkan bẹẹ ko ni ṣẹlẹ mọ.
"A ko le danikan ṣiṣẹ ọhun, a nilo iranlọwọ ati ifọwọsowọpọ awọn araalu.
"Ti ẹ ba wo bi wọn ṣe dana sun awọn eeyan, ẹ maa ri pe niṣe ni wọn mọọmọ pinnu lati kọlu wọn.
"A ni lati lọ gbe ija ba wọn, a ko gbọdọ duro titi wọn yoo fi wa kọlu wa, to ba di lọla ọjọ Iṣẹgun, a maa lọ si Nasarawa nitori ala ipinlẹ naa ṣe pataki fun aṣeyọri ohun ti a fẹ ṣe."
Nigba to n sọrọ lorukọ ileeṣẹ ọlọpaa, Egbetokun ni awọn ko ni sinmi titi iwadii yoo fi pari ti ọwọ yoo si tẹ awọn to wa nidi iṣẹlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, @FrUgochukwu
Ijọba gbọdọ ko awọn ọmọ ogun lọ si Benue ko si ṣe iwadii – Labour Party
Ẹgbẹ oṣelu Labour Party ti ke si ijọba apapọ lati ko awọn ologun lọ si awọn agbegbe ti eto abo rẹ mẹhẹ ni aringbungbun iha ariwa Naijiria.
Ninu atẹjade kan, LP ni awọn to ku kii kan n ṣa onka nikan, amọ wọn jẹ eeyan ẹlẹran ara to nilo idaabobo.
Atẹjade naa ni "Awọn ọmọde to nilo abo ni wọn sun bii ẹran nigba ti wọn n sin awọn iya to yẹ ko ma tọju awọn ọmọ wọn sinu koto ọlọgọrọ ero."
LP sọ siwaju si pe iṣẹlẹ naa n ṣafihan pe ijọba Naijiria ti kuna ninu ojuṣe rẹ lati daabo bo araalu gẹgẹ bii ọkan gboogi lara iṣẹ rẹ gẹgẹ bii ijọba.
Ọpọ araalu n sọrọ lori ikuna ijọba lati daabo bo araalu
Wayi o, oniruru ẹgbẹ lo ti bẹrẹ si n fi oko ọrọ ṣọwọ si ijọba Naijiria latari bo ṣe kuna lati daabo awọn eeyan ipinlẹ Benue.
Lara awọn to ti sọrọ ni oludije fun ipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu LP, Peter Obi to sọ pe asiko ti to fun awọn ọmọ Naijiria lati dẹkun didi ibo wọn fun oloṣẹlu nitori ẹsin tabi ẹya wọn.
Gẹgẹ bii ohun to sọ loju opo X rẹ, Obi ni ijọba to wa lode lonii yii ko ni amuyẹ lati ṣeto abo to peye fun awọn ọmọ Naijiria.
Ẹgbẹ Jama'atu Nasril Islam (JNI), ti Alhaji Muhammad Sa'ad Abubakar n dari sọ pe Naijiria le doju de ti ijọba ba dakẹ gbera lori iṣẹkupani to n waye lemọlemọ ni Naijiria.
Ẹgbẹ Arewa Consultative Forum (ACF,) Middle Belt Forum, Christian Association of Nigeria (CAN), Ohanaeze Ndigbo Worldwide atawọn ẹgbẹ mii kaakiri Naijiria lo ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu naa.
















