Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Aarẹ Bola Tinubu ti ba awọn eeyan ipinlẹ Benue kẹdun lẹyin ikọlu awọn agbebọn to mu ẹmi eeyan to le lọgọrun lọ nibẹ
Tinubu ni oun ti ke si ileeṣẹ ọmọ ogun ko ṣe iwadii ikọlu naa, ko si fi oju awọn to ba lọwọ ninu rẹ wina ofin
Lara awọn to ku nibẹ ni obinrin atawọn ọmọde ti wọn dana sun wa
___________________________________
Ijọba Amẹrika ti sọ pe o ṣeeṣe ki oun fofin de Naijiria atawọn orilẹede marundinlogojii lati ma lee wọ ilẹ naa mọ
Ọrọ yii lo jẹyọ ninu lẹta abẹle kan ti ajọ to n ri si ọrọ iṣejọba Amẹrika, State Department kọ
____________________________________
Ajọ EFCC ti sọ pe opin ko le tii de ba Yahoo ṣiṣe ni Naijiria latari oniruru nnkan ti awọn ọdọ n ṣe bayii lati lu jibiti
Alaga ajọ naa, Olanipekun Olukoyede, sọ pe ọrọ ọhun ti egbinrin ọtẹ, to jẹ pe bi a ti n pa ọkan lominiran tun n ruwe
O ni awọn ọmọ Yahoo ti n gbebọn, wọn ti n ji awọn eeyan gbe, koda wọn ti n ba oloṣelu ko owo lọ ilẹ okere
Fun ẹkunrẹrẹ













