"Ẹ bá mi wa ẹni tó yìnbọn pa ọmọ mi, ọmọ ọdún kan àti oṣù mẹ́jọ tí a jọ sùn lórí ìbùsùn"

Oríṣun àwòrán, Eleweke Family
Àwọn ẹbí ọmọdé kan, ọmọ ọdún àti oṣù mẹ́jọ tí ìbọn déédé bà nínú yàrá tó sùn sí ti rọ ìjọba àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò míì láti báwọn ṣàwárí ẹni tó yìnbọn náà.
Ní ìlé ìgbé àwọn Emmanuel Eleweke ni ìbọn ti bà á ní ìlú Owerri, ìpínlẹ̀ Imo.
Ní alẹ́ ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Kẹfà ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé gẹ́gẹ́ bí àwọn òbí ọmọ náà, Okechukwu Eleweke, tó jẹ́ òṣìṣẹ́ káfíńtà àti Oriaku Kelechi Eleweke, tó jẹ́ olùkọ́ ṣe sọ.

Oríṣun àwòrán, Eleweke Family
Bàbá ọmọ náà, Okechukwu Eleweke sọ fún BBC News Igbo pé ní nǹkan bíi aago mẹ́wàá alẹ́, táwọn ń sùn lọ́wọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà wáyé.
"Ní alẹ́ ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Keje, ọdún 2025 ni ọmọ mi Emmanuel Chisimdiri Okechukwu, ọmọ ọdún kan àti oṣù mẹ́jọ, lẹ́yìn tó ṣeré tán lọ sórí ibùsùn láti sùn.
"Òun àti ìyá rẹ̀ ṣeré, gbàdúrà kó tó di pé ó bọ́ sórí ìbùsùn.
"Ohun tí mo gbọ́ lẹ́yìn náà ni ariwo tí ìyàwó mi pa. Mo fò dìde láti wo ibi tí ọmọ mi wà nítorí orí ìbùsùn kan ni gbogbo wa ń lò.
"Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀jẹ̀ ni mo rí níbi tí ọmọ mi sùn sí"
Ó sọ pé nígbà tí òun bèèrè pé kí ló ṣẹlẹ̀, wọ́n sọ pé ìró ìbọn ni àwọn gbọ́, tó sì jk ìyàlẹ́nu fún òun nítorí òun kò ì tíì sùn.
Lójú ẹsẹ̀ ni wọ́n gbé ọmọ náà lọ sílé ìwòsàn tó wà ní agbègbè náà àmọ́ tí ilé ìwòsàn náà kọ̀ láti gba ọmọ náà lọ́wọ́ wọn.
"Ilé ìwòsàn tí a lọ kò jìnà sí ilé wa, a bẹ̀ wọ́n láti dóòlà ẹ̀mí ọmọ náà ṣùgbọ́n wọn kò gba ọmọ náà lọ́wọ́ wa.
"Ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún mi pé ní Nàìjíríà yìí, dókítà tó wà lẹ́nu iṣẹ́ lálẹ́ ọjọ́ náà ń bèèrè fún ìwé láti ọdọ̀ ọlọ́pàá láti tọ́jú ọmọ ọdún kan àti oṣù mẹ́jọ."
Wọ́n ní èyí ló mú àwọn gbé ọmọ náà lọ sí ilé ìwòsàn Federal Medical Centre, Owerri níbi tí àwọn dókítà ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọmọ náà ti jáde láyé.
Ta lo yìnbọn pa ọmọ náà nínú ilé àwọn òbí rẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Eleweke Family
Àwọn èèyàn tó ń gbé ẹ̀gbẹ́ ilé tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé fẹ̀sùn kan pé àwọn ọlọ́pàá tó ń tẹ̀lé olówó kan, tí a kò fẹ́ dárúkọ ni wọ́n ń yìnbọn ní agbègbè náà.
Wọ́n ní ọta ìbọn àwọn ọlọ́pàá náà ló lọ ba ọmọ náà nínú ilé tó wà.
Àmọ́ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Imo kò fèsì sí èyí nígbà tí BBC kàn sí wọn.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Imo, Henry Okoye kò gbé ìpè tàbí fèsì sí àtẹ̀jíṣẹ́ BBC lásìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ.
Síbẹ̀ bàbá ọmọ ọ̀hún, Eleweke ń rọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá láti jáde sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, kí wọ́n sì fi ẹni tó ṣiṣẹ́ náà winá òfin.
Ọmọ náà ni ọmọ kẹta táwọn òbí rẹ̀ bí.
"Ohun tí mò ń fẹ́ ni kí n rí ìdájọ́ òdodo gbà lórí ikú ọmọ mi. Ọmọ kékeré tí kò mọ ohunkóhun ni.
"Báwo ni èèyàn ṣe máa yìnbọn níbi tí ile ìgbé àwọn èèyàn wà?
Eleweke ní ẹ̀gbẹ́ ilé àwọn ni wọ́n ti yìnbọn tó pa ọmọ òun, tí òun sì ń fẹ́ káwọn ọlọ́pàá ṣe iṣẹ́ wọn láti ṣe ìwádìí ikú ọmọ náà.
"Iṣẹ́ ọlọ́pàá ni láti ṣàwárí ẹni tó hùwà ibi náà," ó sọ.















