Mo ma gbé àpótí ìbò Gómìnà Oyo, máa sì wọlé - Oriyomi Hamzat

Aworan Oriyomi Hamzat

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gbajugbaja agbohunsafẹfẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ redio Agidigbo 88.7 FM, Oriyomi Hamzat, ti kede sita pe oun yoo di Gomina ipinlẹ Oyo ti oun ba jade gbe apoti ibo lọdun 2027.

Oriyomi sọ eyi lasiko to n fesi si ipe kan to wọle si oju opo rẹ lori eto kan to n ṣe lori redio rẹ.

Eeyan to pe Oriyomi ni o ki nilọ fun pe ko ma ni erongba lati jade gbe apoti ibo Gomina lọdun 2027.

"Ẹ ma da awọn eeyan kan ti wọn ni Oyo n pe Oriyomi Hamzat lohun. Irọ ni wọn n pa.

" Ẹ ma ni wọn ko ni dibo fun mi, o le jẹ iwọ gan lo fẹ ti mi lati gbe apoti ibo"

"Bo ti lẹ jẹ pe o n ran ọpọ eeyan lọwọ, ma gbe ara le wọn pe wọn yoo dibo fun ẹ lasiko eto idibo. Wọn ko ni dibo fun ẹ o.

"Ma jẹ ki wọn tan ẹ jẹ. Ko da ni agbegbe ti o ti ni ileeṣẹ redio, ti oloṣelu ba gbe owo lọ sibẹ, wa padanu nibẹ.

"Otitọ ni pe eeyan daada ni ẹ, to si jantọ ṣugbọn awọn araalu ko ni dibo fun ẹ."

Nigba to n fesi, Oriyomi wọgile amọran naa, to si jẹ ko di mimọ pe awọn ọrọ itakoni bayii ko le mu oun ya bara nitori o gbagbọ pe oun le gbe igbesẹ fun ara oun.

O ni ; " Ẹ ma ni wọn ko ni dibo fun mi. O lẹ jẹ iwọ gan lo ti mi lati gbe apoti ibo.

Mo ni ọpọlọ temi. N ko fẹ gbọ iru amọran bayii mọ laye.

"Ti mo ba du ipo, ko si nnkan ti yoo ṣẹlẹ. Ma a dupo, ti ma si bori. Ẹ ma sọ iyẹn fun mi.

"O n sọ mi pe n ko le wọle, ki ni itumọ iyẹn. Ṣe o mọ ọkan awọn eeyan to fẹ dibo fun mi ni? O n fi ana dajọ oni."

Ta ni Oriyomi Hamzat?

Oriyomi Abdulrahman Hamzat lo jẹ ilumọka sọrọsọrọ ati ajafẹtọ ọmọniyan to ni ileeṣẹ redio ti wọn n pe Agidigbo Fm niluu Ibadan.

Hamzat ni wọn bi niluu Ibadan nipinlẹ Oyo, baba rẹ, Asimiyu Adekunle Hamzat, naa jẹ akọroyin pẹlu ileeṣẹ Nigerian Television Authority (NTA).

Hamzat lo si ile ẹkọ girama Iroko Community Grammar School ko to morile ile ẹkọ giga Oyo State School of Sciences, Pade.

Bakan naa lo ti gba oye Diploma ninu Geology lati ile ẹkọ gbogbonise Poly to wa niluu Ibadan.

O tun tẹsiwaju lati gba oye ninu eto ẹkọ Mass Communication lati ile ẹkọ Adeseun Ogundoyin niluu Eruwa.

Ni oṣu kọkanla ọdun 2023, Hamzat tun gba iwe ẹri lati ile ẹkọ giga fasiti ilu Ibadan fun imọ ninu ẹkọ Degree in Linguistics and Language Arts.