Father's Day 2025: Kí ni pàtàkì àyájọ́ ọjọ́ bàbá àti ìtàn tó rọ̀ mọ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oni ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2025 ni ayajọ ọjọ awọn baba, Father's Day ti ọdun yii.
Gẹgẹ bi awọn eeyan ṣe maa n ṣe kaakiri agbaye ni ayajọ ọjọ Mother's Day, ọjọ naa ni ọpọ eeyan maa n ṣe iranti ifẹ, ifaraẹnijin ati igbiyanju awọn baba wọn atawọn to duro bii baba fun wọn.
Ọjọ Aiku kẹta ninu oṣu Kẹfa ni wọn maa n ṣa ayajọ naa ni ọpọ orilẹede.
Bo tilẹ pe inu oṣu Kẹfa ni awọn orilẹede bii Naijiria, India, United States, ati UK maa ṣeranti ọjọ naa ninu oṣu Kẹfa; ọjọ kọkandinlogun inu oṣu Kẹta ni awọn orilẹede bii Italy, Spain, Croatia, and Portugal maa n bẹrẹ ti wọn lati ba ayajọ Saint Joseph's Day dọgba.
Ki ni itan to wa nidi ayẹyẹ Father's Day?
Isẹlẹ ajalu nla kan to waye niluu West Virginia, nilẹ Amẹrika lo bi ayajọ Father's Day lọdun 1908.
Ibugbamu kan lo waye nibi ti wọn ti n wakusa eedu lọdun naa lọhun, eyii to mu ẹmi ọkunrin 361 lọ, ti pupọ ninu wọn jẹ baba.
Lẹyin ajalu naa ni wọn ṣe isin iranti fun awọn ti ẹmi wọn sọnu nibẹ.
Sonora Smart Dodd niluu Washington lo mu ki ayẹyẹ Father's Day to gbode lonii gbajumọ.
Obinrin naa fẹ ṣe ayẹsi baba rẹ to jẹ ajagunfẹyinti, to tun danikan tọ ọmọ mẹfa lai si iya wọn nibẹ.
Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 1910 ni wọn ṣe ayẹyẹ Father's Day akọkọ ki okiki ayajọ naa to bẹrẹ si n tan kalẹ bii ti Mother's Day.
Ki ni pataki ayajọ Father's Day?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọ yii jẹ ọjọ ti awọn eeyan n fi yẹ baba wọn si fun gbogbo akitiyan ati igbiyan rẹ lati tọ wọn ati lati fun wọn ni igbeaye to rọrun.
Boya baba to bi eeyan funra rẹ ni o tabi baba to gba eeyan tọ, to fi mọ eyii to fi ara rẹ si ipo baba nipa awọn ojuṣe rẹ, apẹrẹ rere ni baba yẹ ko jẹ fun awọn ọmọ rẹ.
Yatọ si ayajọ yii, gbogbo igba lo yẹ ki eeyan maa ṣe ayẹsi ko si maa mọ riri ohun ribiribi ti baba rẹ ti gbe ṣe ninu aye rẹ.
Bo tilẹ jẹ pe awọn baba miran kọ lati ṣe ojusẹ wọn lori ọmọ fun ọpọlọpọ idi, o tọ fun ọmọ lati maa yẹ awọn baba wọn si ni gbogbo igba.
Ojuṣe rẹ ni ayajọ oni
Ni irufẹ ayajọ oni, o le ya akoko sọtọ lati wa pẹlu baba rẹ ti ẹ ko ba jinna si ara yin.
Ẹ le lo akoko yin papọ nipa gbigbe irufẹ baba bẹẹ jade lati lọ ra tabi jẹ ohun to ba wu u lọkan.
Ẹ tun le lọ wo sinima papọ tabi ki ẹ lọ ṣe oniruru faaji ti baba naa ba fẹran.
To baba rẹ ba jẹ ẹni to n ṣiṣẹ, o le ba ṣe lara iṣẹ naa tabi ki o gba agbaṣẹṣe fun Iayajọ ọjọ oni ki o le sinmi.
Ohun to ṣe pataki julọ ni ki ẹ lo akoko papọ ki o si mu inu baba rẹ dun.
Ti o ba wa lara awọn to ti padanu baba wọn, akoko yii naa ni o le fi ṣeranti ohun rere to ti gbele aye ṣe ati ipa to ti ko ninu aye rẹ.
Wayi o, ti baba rẹ ba jẹ ọkan lara awọn ti ko wulo tabi to kọ lati tọju ọmo, akoko naa ni o le fi pinnu lati ri daju iwọ funra rẹ ko wu iwa bii baba rẹ, tabi ki o pinnu lati ri daju pe baba ti yoo pe ọmọ rẹ wa sile aye jẹ ẹni to n ṣe ojuṣe rẹ.















