Ká ní mo mọ̀ pé ọkọ mi yóò lọ kò ní dé padà, mi ò bá májẹ kó jáde - aya Abdulfatai tí ògiri wò pa ni Kwara

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Abdulfatai Hawau, ti o jẹ aya arakunrin kan Abdulfatai Muhammed, ti ogiri wo pa ni ilu Ilorin ti sọ pẹlu omije pe ka ni oun ni imọlara pe ọkọ oun n lọ pade iku rẹ ni, oun iba ma ti jẹ ko jade.
O wa rọ ijọba ki wọn saanu oun ati awọn ọmọ oun, ki wọn ba oun wasẹ, ki wọn si fun awọn ọmọ ni ẹkọ ọfẹ.
Lọjọ Isẹgun ọsẹ yii, ni iroyin gbode kan pe ogiri ile itura iba Kwara, (Kwara Hotel) ti ijọba n tun ṣe lọwọ ya lulẹ, o si wo pa, awọn osisẹ.
Iṣẹ atunṣe ile itura naa ni ijọba Kwara gbe fun ile-ise agbasẹse kan ti wọn n pe ni, Craneburg, ni owo to le ni billion mẹtadinlogun naira (N17billion).
Ni ọjọ Ẹti ni BBC Yoruba ṣabẹwo si ile ọkan lara awọn oṣiṣẹ to dologbe lẹnu isẹ naa lati mọ ohun to sẹlẹ
Ọjọ aisun ileya lọkọ mi bẹrẹ iṣẹ ki o to kagbako iku lọjọ Iṣẹgun - Iyawo Oloogbe
Abdulfatai Hawau, salaye pe osisẹ ina mọna mọna ni ọkọ oun, o si sẹsẹ risẹ pẹlu ile isẹ Craneburg ni Kwara Hotel ni.
Hawau sọ pe ọkọ oun ti le ni ogoji ọdún, pe ọjọbọ to jẹ aisun ọdun ileya ni o bẹrẹ isẹ, sugbọn ọga rẹ fun ni aye fun ọdun ileya, wi pe ko wọsẹ pada ni ọjọ Isẹgun ọsẹ yi.
"Ko si nkankan to ṣe ọkọ mi, a ki rawa ni odabọ ni ọjọ isẹgun, afi to di ago mẹsan-an alẹ, mo wa ni ibi ti mo ti n taja pẹlu awọn ọmọ mi ni mo gba ipe pe, ogiri wo pa ọkọ mi lẹnu isẹ
"Isẹlẹ naa bami ninu jẹ tori jijẹ mimu emi ati awọn ọmọ mi lo ba lọ ti ọlọjọ fi de.
"Ọmọ mẹrin ni mo bi fun ọkọ mi, oyun ẹkarun si wa ninu mi, oyun naa si ti pe osu kẹsan-an bayii.
Arabinrin Hawau ni oun ni iwe ẹri olukọni NCE ti oun fi sisẹ ni awọn ile ẹkọ adani kan ki oun to fibẹ silẹ nitori owo oṣu to kere jọjọ.
"Oun ti mo fẹ bayii ni isẹ fun ara mi ati ẹkọ ọfẹ fun awọn ọmọ mi...
"Ka ni ogiri naa duro o re ni, ọkọ mi o ba ma sagbako ẹ. Ka ni Ọlọhun fihan mi pe ọkọ mi fẹ lọ pade iku lọjọ naa ni, mi o ni jẹ ko lọ.
"Ọkọ mi jẹ eeyan to n tiraka to si ni itẹlorun nigba ayee rẹ, emi naa o si tii gbọn gbọn, gbogbo nkan to fun mi lo tẹmi lọrun.
Òṣìṣẹ́ Craneburg ṣàlàyé bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé
Ọkan lara osisẹ Craneburg to ni ka fi orukọ bo oun lasiri sọ pe, isẹlẹ naa soju oun,
O ni, "ohun to sẹlẹ ni pe, ina lafẹ ṣe sara ogiri to wo naa.
"Wọn ti sa ogiri naa lati maa ri awọn waya sinu rẹ ko to di pe wọn bo o pada.
"Awọn mẹrin lo n sisẹ lọwọ ni bẹ, sadede la gbọ ariwo gbi, igba ta fi de bẹ, bi ogiri naa se gun to, ẹkan ni gbogbo rẹ dawo le wọn mọlẹ.
"Ohun ti ko jẹ ki wọn raye sa asala ni pe gọta wa ni ẹgbẹ ogiri naa, ko jẹ ki wọn ni aye ati duro ju inu gọta naa lọ, ohun lo fa ti ofi dawo bo wọn mọ inu gọta.
"Igba ta gbe wọn, eeyan meji ti farapa yanayan, ati ibẹ lawọn eeyan ti n sunkun.
"Awọn meji yoo ku, ikan fapa sese, ikan yoku, ti rẹ o pọ rara. Wọn gbe wọn lọ ile iwosan Sadiku to jẹ ile iwosan ile-ise wa, sugbọn wọn o gba wọn ni bẹ.
"Wọn tun gbe wọn lọ ile iwosan gbogbo, ibẹ ni wọn ti sọ pe, awọn meji ti ku, ẹni kẹta to fapa sese gba itọju di ọjọkeji koun naa to jẹ Olorun nipe lẹyin to ti gba ẹjẹ ọra mẹjọ.
"Lọrọ kan, eeyan kan lo ye ninu awọn mẹrin.
Igba to n sọrọ nipa ohun to sokunfa ogiri towo naa, okunrin naa sọ pe asise ti wọn se nipe, bi ogiri naa se gun to, wọn sa gbogbo rẹ kalẹ ni, o ni ka ni wọn sa ni isọri isọri ti wọn si n bo bi wọn ṣe n sa ni, oseese ki o maa wo.
ìjọba Kwara fìdí ọ̀rọ̀ náà múlè
Agbẹnusọ agba fun gomina ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye, fidi isẹlẹ naa mulẹ ni ana ọjọru.
O ni o ṣeni laanu pe, ogiri kan wo, o si se awọn mẹta lese.
O fi kun-un pe, pẹlu gbogbo akitiyan lati dola ẹmi wọn, eeyan meji ku.















