Ẹnìkan ṣoṣo tó yè nínú ìjàmbá bàálù Air India tó pa èèyàn tó lé ní 200 sọ bó ṣe jáde

Oríṣun àwòrán, PA Media
Ọkunrin kan lati ilẹ Gẹẹsi nikan ni ori koyọ ninu ijamba baalu to ṣekupa eeyan to le ni igba lorilẹede India lọjọ kejila oṣu Kẹfa, ọdun 2025.
Ọkunrin naa, Vishwashkumar Ramesh, joko si aye 11A, to si n lọ si ilu London nigba ti ijamba naa waye ni kete ti wọn kuro ni Ahmedabad, ni iwọ oorun India.
Air India ni awọn eero ọkọ yooku to fi mọ awọn oṣiṣẹ to wa ninu baalu ni wọn ti jade laye. Ọmọ orilẹede India 169, 52 lati ilẹ Gẹẹsi.
Oku eeyan to le ni 200 ni wọn ti ri bayii, amọ ko si ẹni to le sọ iye to jẹ awọn to wa ninu baalu tabi awọn ti baalu ja le lori, nitori pe, agbegbe ibi ti awọn eeyan n gbe ni baalu naa jabọ si.
Nayan Kumar Ramesh, to jẹ ibatan Vishwanshkumar, sọ fun BBC pe " o dun mọ mi ninu pe mo ri pada, to si wa ni alaafia" ṣugbọn o ba lọkan jẹ nitori aburo rẹ keji Ajay, naa wa ninu baalu.
Bi ori ṣe ko Ọgbẹni Ramesh yọ ninu ijamba to pa ọpọ eeyan
Nigba to n ba awọn eeyan sọrọ lati ileewosan ti wọn ti n tọju rẹ, Ọgbẹni Ramesh, sọ pe bi baalu naa ṣe gbera, ni awọn ina to wa ninu rẹ ti n ṣẹju.
O ni ko to iṣẹju kan lẹyin naa to fi da bi i pe baalu naa duro pa si ofurufu
"Awọn ina n ṣẹju, to si n tan awọ eweko ati funfun. Ko to iṣẹju aaya mẹwaa ti baalu naa fi jabọ si ara ile kan nilẹ, to si gbina."
Baalu Boeing 787-8 Dreamliner ọhun jabọ le ileegbe kan ti awọn dokita ileewosan ikọṣẹ iṣegun Byramjee Jeejeebhoy Medical College and Civil Hospital, n gbe.
"Bi ilẹkun ṣe fọ, mo ri alaafo diẹ, bẹẹni mo gbiyanju lati jade kuro nibẹ.
"Ko si bi ẹnikẹni ṣe le raaye jade lati ẹgbẹ keji nitori pe, ara ogiri ile ni, ibẹ si ni baalu naa ja lulẹ si."
Koko nnkan to fa ijamba baalu naa ko ti i han si ẹnikẹni. Awọn ileeṣẹ iroyin sọ pe, awọn alaṣẹ ni awọn ti ri black box inu baalu naa, eyi ti yoo le sọ nnkan to ṣẹlẹ fun awọn oluwadii.
Fidio kan to wa lori ayelujara, ṣafihan bi Ọgbẹni Ramesh ṣe n rin lọ sibi ti ọkọ itọju pajawiri wa, ti eefin si n ru ni ẹyin rẹ.
O sọ fun ileeṣẹ iroyin India pe, oun ko gbagbọ pe oun jade ninu ijamba naa laaye.
"Mo ri bi awọn eeyan ṣe ku niṣoju mi - awọn ọmọge to n ṣiṣẹ ninu baalu, ati eeyan meji kan nitosi mi."
"O jẹ ohun iyalẹnu nigba ti a gbọ ohun to sẹlẹ, o ba wa lojiji. A ko lẹ sọ ohunkohun."
"Vishwashkumar gan an ko le ṣalaye bi ori ṣe ko yọ tabi bi o ṣe kuro ninu baalu naa.
"Nigba to pe wa, o kan n pariwo pe ki wọn ba oun wa Ajay to jẹ ọmọ iya rẹ. Ohun to jẹ ẹ logun lasiko naa niyẹn.
Mọlẹbi kan, Jay to ba PA news agency sọrọ ni "o farapa ninu oju rẹ. Ẹjẹ bo gbogbo aṣọ rẹ. Alaafia lo wa. O kan ba lojiji ni."
Fọnran kan to lu sita ṣafihan bi Ramesh ṣe n fi ẹsẹ ara rẹ rin lọ sibi ti yoo ti gba itọju
Nigba to ya ni wọn ri ni ile iwosan, lori ibusun nigba ti minisita ọrọ abẹle ni India, Amit Shah ṣe abẹwo si.
Dokita Dhaval Gameti, to n tọju Ramesh, sọ pe "ojiji ni nnkan yii de ba, pẹlu ọpọ ifarapa ṣugbọn ara rẹ ti n balẹ."
Ọkunrin yii ni o jẹ oniṣowo, ti wọn bi si orilẹede India ṣugbọn to ti n gbe ni UK lati ọdun 2003. O ni iyawo ati ọmọ ọdun mẹrin.













