Ọlọ́pàá mú ìyàwó ọ̀sìngín 'tó pa ọkọ rẹ̀', tó sì sálọ lásìkò tí wọ́n n ṣe honeymoon

Oríṣun àwòrán, Raghuvanshi family
- Author, Geeta Pandey
- Reporting from, BBC News, Delhi
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Ileeṣẹ ọlọpaa ni orilẹede India sọ pe iyawo aṣẹṣẹ gbe kan to di awati lẹyin ti wọn pa ọkọ rẹ, ti jọwọ ara rẹ, to si ti wa ni ahamọ.
Ṣaaju ni ẹbi tọkọtaya naa ti n fura pe boya wọn ji iyawo naa gbe lọ tabi wọn ti pa a , eyi to mu ki wọn o polongo fun ominira rẹ.
Ṣugbọn ni bayii, awọn ọlọpaa sọ pe iyawo ọhun gan-an ni awọn n fura si pe, o pa ọkọ rẹ.
Sonam Raghuvanshi, ẹni ọdun marundinlọgbọn, ni awọn ọlọpaa sọ pe o gba awọn janduku lati pa ọkọ rẹ, Raja, ẹni ọgbọn ọdun, lasiko ti wọn n ṣe faaji ẹyin igbeyawo, eyi ti wọn n pe ni honeymoon ni ede Gẹẹsi, ni ipinlẹ Meghalaya lorilẹede India.
Eeyan mẹrin mii ni ọwọ tun ti tẹ.
Baba iyawo, Devi Sigh, sọ pe oun jẹri ọmọ ti oun bi pe "ko le lọwọ si iru nnkan bẹ".
Tọkọtaya ọhun to ṣẹṣẹ ṣe igbeyawo, n gbe ni ilu Indore, ni ipinlẹ Madhya Pradesh, ṣugbọn ti wọn pinnu lati lọ fun isinmi honeymoon wọn ni Meghalaya, nitori wọn gbọ pe ipinlẹ naa ni awọn oke ati apata to rẹwa pupọ, gẹgẹ bi nnkan ti ẹgbọn Raja, Sachin Raghuvanshi, sọ fun BBC.
Ọjọ kọkanla oṣu Karun un ni wọn ṣe igbeyawo naa niluu Indore, nibi ti ẹbi mejeeji ti pejọ.
Aburo ọkọ ṣalaye pe "ni nnkan bi oṣu mẹrin sẹyin ni wọn ṣeto awọn mejeeji funra wọn lati di tọkọtaya, ti inu awọn mejeeji si dun si eto naa.
"Bakan naa ni ko si ija tabi ede aiyede kankan laarin wọn ṣaaju, lasiko tabi lẹyin ayẹyẹ igbeyawo ọn."
Ogunjọ oṣu Karun un ni tọkọtaya naa fi ile wọn silẹ, ti ẹnikẹni ko si gburo wọn mọ lẹyin ọjọ kẹrin.
Awọn ọlọpaa, oṣiṣẹ adoola ati awọn araalu ti wọn lọ si lo ti pawọpọ lati maa wa tọkọtaya naa.
Wọn wa wọn ninu oriṣiriṣi koto, amọ ti awọn alaṣẹ sọ pe ojo to n rọ ati kurukuru, mu ko nira lati wọ inu awọn koto naa.
Ṣé o fẹ́ràn láti má a ka ìròyìn nípa tọkọtaya?
Ọsẹ kan lẹyin rẹ ni wọn ri oku Raja ninu afonifoji kan, to ti jẹra, pẹlu apẹrẹ pe wọn fi nnkan dunbu ọrun rẹ. Bakan naa ni oruka ati ẹgba ọrun rẹ to jẹ wura, ati apo pọọsi rẹ di await.
Wọn ri oku ọkọ, ṣugbọn iyawo ko jẹ ri ri.
Eyi gan-an lo mu ki iporuru ọkan ba awọn ẹbi tọkọtaya naa, ti wọn si n polongo pe ki awọn ọlọpaa ṣe awari rẹ.
Koda, wọn kọ lẹta si Olootu ijọba India, Narendra Modi, pe ko ba wọn ṣe agbatẹru bi wọn o ṣe ri Sonam ni kiakia.
Ṣugbọn ni owurọ ọjọ Aje, ni ọga ọlọpaa niluu Meghalaya, Idashisha Nongrang, kede pe Sonam ti jọwọ ara rẹ ni agọ ọlọpaa kan to w ani agbegbe Ghazipur ni ipinlẹ Uttar Pradesh.
Lẹyin naa ni awọn ọlọpaa sọ pe ọwọ ti tẹ afurasi ọkunrin mẹta, to jẹ ọmọbibi ilu ibi ti tọkọtaya naa ti wa.
Lẹyin naa ni ọwọ tun tẹ afurasi kẹrin nilu Meghalaya.
Bo tilẹ jẹ pe ko ṣe alaye to pọ, ọga ọlọpaa sọ pe iyawo tuntun naa, Sonam, ni afurasi akọkọ.

Oríṣun àwòrán, Raghuvanshi family
Nigba to n dahun ibeere akọroyin kan pe ṣe iyawo tuntun naa ati ẹnikan lara awọn ọkunrin ti ọwọ tẹ jọ n yan ara wọn lale, ọga ọlọpaa sọ pe, ọrọ naa fẹ ẹ jọ bẹẹ, ṣugbọn o di igba ti wọn ba fi ọrọ wa awọn eeyan naa lẹnu wo ki wọn o to mọ idahun.
Baba iyawo sọ fun ileeṣẹ iroyin ANI pe, alẹ ọjọ kan ni Sonam deedee ba ara rẹ ni ẹgbẹ ojupopo kan niluu Ghazipur, nibi to ti ya foonu ẹnikan lati pe ẹgbọn rẹ, to pada fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti.
Baba naa sọ pe lootọ ni oun ko ti I ri ọmọ oun ba sọrọ lati igba naa, amọ oun ni aridaju pe, ko lọwọ si iṣẹlẹ naa.
Bakan naa lo tun fi ẹsun kan ileeṣẹ ọlọpaa pe, wọn n parọ ipaniyan, o si rọ minister fun ọrọ abẹle, Amit Shah, lati paṣẹ iwadii ti yoo fi otitọ han.
Ẹgbọn ọkọ, Vipin Raghuvanshi, ti kọkọ sọ pe oun ko gba pe, Sonam, le lọwọ ninu iku ọkọ rẹ. Amọ nigba to ya, o tun sọ pe ẹnikan lara awọn ọkunrin ti ọwọ tẹ ọhun, n ṣiṣẹ ni ọfiisi Sonam.












