Ọkọ̀ òfúrufú tó gbé èèyàn tó lé ní 200 já, iṣẹ́ ìdóòlà ẹ̀mí bẹ̀rẹ̀

Oríṣun àwòrán, AP
Àwọn aláṣẹ ti kéde pé kò dín èrò 232 àti òṣìṣẹ́ 12 tó wà nínú ọkọ̀ òfurufú Air India tó mórílé London láti India ti já lulẹ̀.
Kò pẹ́ tí ọkọ̀ òfurufú náà gbéra ní pápákọ̀ òfurufú Ahmedabad, ìwọ̀ oòrùn India ló já lulẹ̀.
Ọ̀gá àgbà ètò ìrìnnà òfurufú India, Faiz Ahmed Kidwai sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn Associated Press pé agègbè tó jẹ́ ilé ìgbé àwọn èèyàn, Meghani Nagar ni ọkọ̀ òfurufú náà já lulẹ̀ sí.
Agbẹnusọ pápákọ̀ òfurufú Ahmedabad, Sardar Vallabhbhai Patel sọ pé àwọn ti gbé pápákọ̀ òfurufú náà tì pa fún ìgbà kan ná báyìí. Ó ní ètò ìrìnnà ni àwọn ti gbé tì fún ìgbà kan ná.
Air India sọ pé ọkọ̀ òfurufú "Flight AI171 tó ń ná Ahmedabad sí London Gatwick ni ó ti ní ìjàmbá.
Ìròyìn ní ọkọ̀ òfurufú náà gbé ju èèyàn tó lé ní igba.
Mínísítà fétò ìrìnnà òfurufú ní àwọn ti wá ní ojú lálakàn fi ń ṣọ́rí àti pé àwọn òṣìṣẹ́ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ti ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Àwọn ọkọ̀ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ti wà ní gbogbo ọ̀nà, tí wọ́n sì dí ọ̀nà pa.
Àwọn òṣìṣẹ́ panápaná ti ń gbìyànjú láti pa iná náà.
Ní nǹkan bíi aago mẹ́wàá ku ìṣẹ́jú mẹ́wàá àárọ̀ ni ọkọ̀ òfurufú náà gbéra ní Ahmedabad pẹ̀lú ìrètí pé ó máa dé London ní aago mẹ́fà kọjá ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ní London.
Ṣùgbọ́n nǹkan bíi mẹ́wàá kọjá ìṣẹ́jú mẹ́jọ ni wọn kò rí ọkọ̀ òfurufú náà mọ́ lẹ́yìn ìṣẹ̀jú kan tó gbéra.
Àkọ́ọ́lẹ̀ ọkọ̀ òfurufú náà ṣàfihàn pé ọkọ̀ náà máa ń ná láti India lọ sí Paris, Frankfurt, Tokyo, Amsterdam, àti Melbourne.
Ohun tí a mọ̀ nípa ọkọ̀ òfurufú tó já náà

Oríṣun àwòrán, AP
- Lásìkò tí ọkọ̀ òfurufú náà ń gbéra lọ sí London lẹ́yìn tó gbéra kúrò ní Ahmedabad, ìwọ̀ oòrùn India
- Àwọn èèyàn 242 ló wà nínú ọkọ̀ náà tó fi mọ́ àwọn awakọ̀ méjì àti òṣìṣẹ́ mẹ́wàá
- Àwọn èrò náà ló jẹ́ ọmọ India 169, ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì 53, ọmọ Canada kan àti ọmọ Portugal méje
- Ní agbègbè tó jẹ́ ilé ìgbé ni ọkọ̀ òfurufú náà já sí
- Mínísítà fọ́rọ̀ ìrìnnà òfurufú ní iṣẹ́ ti ń lọ láti mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ náà
- Iṣẹ́ ìdóòlà ti ń lọ lọ́wọ́ ní agbègbè tí ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú náà ti wáyé















