Kí ló fa gbas-gbos láàárín Air Peace àti Adams Oshiomole?

Adams Oshiomole àti ọkọ̀ òfurufú Air Peace

Oríṣun àwòrán, Adams Oshiomole/Facebook/Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ní òwúrọ̀ ọjọ́rú ni fídíò kan gba orí ayélujára tó ń ṣàfihàn èèkàn olóṣèlú, Sẹ́nétọ̀ Adams Oshiomole tó ń dí ojú ọ̀nà láti wọkọ̀ òfurufú ní pápákọ̀ òfurufú Murtala Muhammed Airport.

Ìròyìn ní Oshiomole fi tipátipá di ẹnu ọ̀nà Zulu Terminal ní General Aviation Terminal (GAT) lẹ́yìn tó pẹ́ dé pápákọ̀ òfurufú ọ̀hún láti wọ ọkọ̀ òfurufú iléeṣẹ́ Air Peace.

Àmọ́ Adams Oshiomole nínú àtẹ̀jáde kan tó fi sórí ìkànnì Facebook rẹ̀ ní òun kò pẹ́ dé pápákọ̀ òfurufú náà.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jádé tí iléeṣẹ́ Air Peace fi léde, wọ́n ní àgbà olóṣèlú náà kò jẹ́ káwọn èèyàn tó fẹ́ ṣe ìrìnàjò ríbi wọ ọkọ̀ òfurufí bí ó ṣe dí ọ̀nà mọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn.

Air Peace ṣàlàyé pé aago mẹ́fà òwúrọ̀ kọjá ìṣẹ́jú mẹ́wàá ni Oshiomole dé pápákọ̀ òfurufú náà láti wọ ọkọ̀ òfurufú P47120 tó máa gbéra ní aago mẹ́fà ààbọ̀ láti ìpínlẹ̀ Eko lọ sí Abuja, ìgbésẹ̀ tí wọ́n ní ó lòdì sófin àwọn àti pé àwọn èrò inú ọkọ̀ òfurufú náà ti jòkòó, tí ọkọ̀ sì ti fẹ́ gbéra.

Wọ́n ṣàlàyé pé nígbà tí àwọn sọ fún Oshiomole pé kò lè wọ ọkọ̀ òfurufú náà mọ́ ló da wáhàlá sílẹ̀, tí kò sí jẹ́ káwọn èrò míì wónú ọkọ̀ náà.

Wọ́n fi kun pé àwọn nílò láti wá ọ̀nà míì fáwọn èrò láti gba wọ inú ọkọ̀ òfurufú kí wọ́n le gbéra lọ sí ibi tí wọ́n ń lọ.

Iléeṣẹ́ Air Peace ní àwọn dúró lórí òótọ́ àti ìbọ̀wọ̀ fún àwọn ètò àwọn, tí àwọn kò sì ní yí ìṣe àwọn padà fún ẹnikẹ́ni àti pé kò sí ẹni tó tóbi ju àwọn òfin àwọn lọ.

'Mi ò pẹ́ dé pápákọ̀ òfurufú, mi ò fẹ́ kí wọ́n rẹ àwọn èèyàn jẹ ni mo ṣe dí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé'

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ẹ̀wẹ̀, Oshiomole nínú àtẹ̀jáde tó wà lórí Facebook rẹ̀ sọ pé òun kò pẹ́ dé pápákọ̀ òfurufú bí iléeṣẹ́ Air Peace ṣe sọ bíkòṣe pé òun kọ̀ láti jẹ́ kí wọ́n tẹ ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn lójú mọ́lẹ̀, tí wọ́n sì ń gba owó gege lọ́wọ́ àwọn èèyàn.

Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, Oshiomole, tó ń ṣojú ẹkùn àríwá Edo ní ilé aṣòfin àgbà ṣàlàyé pé ohun tí òun kojú lọ́wọ́ iléeṣẹ́ Air Peace ṣàfihàn àwọn ìlàkàkà àwọn aráàlú lọ́wọ́ iléeṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú.

Ó sọ pé ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni ó yẹ kí òun ti gbéra lọ sí Abuja àmọ́ wọn kò jẹ́ kí òun wọ ọkọ̀ pẹ̀lú ẹ̀sùn pé òun pẹ́ dé pápákọ̀ òfurufú nígbà tí òun dé ibẹ̀ ní aago mẹ́fà kọjá ]ìṣẹ́jú mọ́kànlá fún ọkọ̀ tó máa gbéra ní aago méje ku ìṣẹ́jú mẹ́wàá.

"Lánàá, o kú ogójì ìṣẹ́jú ti ọkọ̀ òfurufú máa gbéra ni mo dé àmọ́ wọn kò jẹ́ kí n wọkọ̀. Wọn tik ó àwọn ẹrù mi sínú ọkọ̀ ṣùgbọ́n wọ́n sọ fún mi pé àwọn kò fún èèyàn ni ìwé láti fi wọ ọkọ̀ mọ́.

"Àmọ́ mò ń ri tí wọ́n ń gbà káwọn èèyàn míì wọnú ọkọ̀ èyí tó mu mi lọ sun ilé ìtura tó wà ní agbègbè náà mọ́jú."

Oshiomole ṣàlàyé pé ní òwúrọ̀ ọjọ́ Kejì ni òun tún gbìyànjú láti bá iléeṣẹ́ Air Peace lọ sí Abuja bákan náà, tí òun sì ti kàn sí wọn lórí ayélujára ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ ku ìṣẹ́jú mẹ́rìnlá.

Ó ní aago mẹ́fà kò ì tíì lù tí òun fi dé pápákọ̀ òfurufú náà fún ìrìnàjò aago mẹ́fà àbọ̀ síbẹ̀ Air Peace tún sọ fún òun pé òun pẹ́ dé.

Ó fi kun pé àwọn èrò míì náà wà níbẹ̀ tí wọn kò gbà láàyè láti wọ ọkọ̀ pẹ̀lú ẹ̀sùn pé àwọn náà pẹ́ dé.

"Mo fi ẹ̀rí hàn wọ́n pé mo tik ó àwọn ẹrù mi wọ inú ọkọ̀ láti àná àmọ́ wọ́n ní àwọn ti ti ọ̀nà síbẹ̀ mò ń rí àwọn míì tí wọ́n ń gbà láàyè láti wọ ọkọ̀."

"Lásìkò tí mò ń ṣàlàyé fún wọn lọ́wọ́ ni mo ṣàkíyèsí pé ọ̀pọ̀ èèyàn tó ti ṣáájú dé pápákọ̀ náà ni wọ́n wà nínú ipò mi tó fi mọ́ àwọn tó gbé ọmọ ìkókó dání.

Oshiomole fẹ̀sùn kan iléeṣẹ́ náà pé kàkà kí wọ́n gba àwọn tó ti ra tíkẹ́ẹ̀tì láti orí ayélujára láàyè láti wọkọ̀, níṣe ni wọ́n ń ta ààyè wọn fáwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dé lówó gege.

Ó ní N146,000 ni àwọn tó ra tíkẹ́ẹ̀tì lórí ayélujára ń rà á ṣùgbọ́n N250,000 ni wọ́n ń tà á fáwọn tó ń rà á lójú ẹsẹ̀.

Ó sọ pé òun kò ètò àwọn èèyàn rú bíkoṣe pé òun kọ̀ láti jẹ́ kí wọ́n yan àwọn èèyàn jẹ, tí òun sì fk kí wọ́n ṣe òun bí àwọn ọmọ Nàìjíríà yòókù.

Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn lórí ayélujára ni wọ́n ń kan sọ̀rọ̀ ìfaǹfà tó wáyé láàárín Oshiomole àti iléeṣẹ́ náà.

Àwọn èèyàn fẹ̀sùn kan Air Peace ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń dá àwọn èèyàn dúró láì sí ìdí kan pàtó tí wọn kò sì ní tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn èèyàn.