Ilé ẹjọ́ yí ẹ̀bẹ̀ Akpabio dànù lórí ẹjọ́ tó pe Natasha Akpoti-Uduaghan

Oríṣun àwòrán, Natasha Akpoti Uduaghan/Godswill Akpabio/Facebook
Ile ẹjọ kotẹmikọrun niluu Abuja ti yi ẹbẹ aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnẹtọ Godswill Akpabio, lori ẹjọ to pe Sẹnẹtọ Natasha Akpoti-Uduaghan danu.
Igbimọ adajọ ẹlẹni mẹta ọhunti Adajọ Hamman Barka dari wọn lo gbe idajọ naa kalẹ, ti wọn si tun ni ki Akpabio san N100,00 naira, gẹgẹ bi owo itanran.
Iwe igbẹjọ pẹlu nọmba CV/395/M1/2025 ati CV/395/M2/2025 fi han pe Akpabio pẹjọ kotẹmilọrun naa lọjọ kẹta oṣu Kẹta ati lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹta ọdun 2025.
Awọn nnkan ti Sẹnetọ Godswill Akpabio n fẹ ki ile ẹjọ ṣe?
Ṣaaju ni Akpabio beere lọwọ ile ẹjọ kotẹmilọrun naa pe ko fun oun lasiko to pọ lati pe ẹjọ kotẹmilọrun lori aṣẹ ile ẹjọ giga ijọba apapọ pẹlu ẹjọ to wa laarin Natasha, akọwe ile igbimọ aṣofin agba atawọn mẹta mii.
Akpabio tun bẹ ile ẹjọ kotẹmilọrun lati paṣẹ fun ile ẹjọ giga apapọ pe ko fun oun laaye to pọ lati pe ẹjọ kotẹmikọrun lori ẹjọ mii to wa laarin Natasha, akọwe ile aṣofin agba atawọn mẹta mii.
Bakan naa tun ni Akpabio tun beere lọwọ ile ẹjọ lati paṣẹ idaduro igbẹjọ ẹjọ to n lọ laarin Natasha, akọwe ile aṣofin agba atawọn mẹta mii, titi ti ile ẹjọ kotẹmilọrun yoo fi gbọ ẹjọ ti oun pe.
Lẹyin ti ile ẹjọ kotẹmilọrun yi ẹbẹ Akpabio danu tan pẹlu alaye wi pe ọjọ ti lọ lori ọrọ naa lati ṣe ohun ti Akpabio n beere, ni ile ẹjọ ni ko san N100,000.
Ohun to ṣẹlẹ ṣẹyin lori ẹjọ Natasha Akpoti-Uduaghan ati Akpabio
Ti ẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹfa ni Adajọ Binta Nyako ti ile ẹjọ giga apapọ fẹ da ẹjọ lori bo ya o tọna bi ile aṣofin ṣe da Natasha Akpoti-Uduaghan duro gẹgẹ bi sẹnẹtọ to n ṣoju ipinlẹ Kogi.
Adajọ Egwuatu lo bẹrẹ ẹjọ ọhun ṣugbọn o ni lati jawọ ninu ẹjọ naa lẹyin ti Akpabio fẹsun kan an wi pe o n ṣegbe lẹyin ẹni to pe oun lẹjọ.
Lẹyin ti Adajọ Egwuatu fi ẹjọ naa silẹ ni Adajọ Nyako tẹwọ gba ẹjọ naa.
Ṣaaju ni Natasha mori le ile ẹjọ giga lẹyin ti igbimọ olubawi fawọn ọmọ ile to ba ṣẹ paṣẹ pe, ko wa sọ tẹnu rẹ niwaju igbimọ naa lẹyin faakaja to waye laarin rẹ ati aarẹ ile logunjọ oṣu Keji ọdun yii.
Nigba ti Natasha n fi aidunnu rẹ han lori bi wọn ṣe paarọ ijokoo rẹ nile, ni ṣe lo n nawọ soke wi pe oun fẹ sọrọ, bo tilẹ jẹ pe aarẹ ile ti pasẹ pe ko gbọdọ sọrọ mọ.
Lẹyin eyi ni aarẹ ilẹ aṣofin gbe ẹjọ rẹ lọ siwaju igbimọ to n da ṣeria fawọn ọmọ ile to ba ṣẹ, igbimọ yii lo si pada da a duro.
Amọ, Natasha sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe lori tẹlifisan lọjọ kejidinlọgbọn oṣu Keji pe ede aiyede laarin oun ati Akpabio bẹrẹ lẹyin ti o dẹnu ifẹ kọ oun ti oun ko si gba.
Ẹjọ ti Natasha pe ni wi pe ki ile ẹjọ paṣẹ pe bi igbimọ ile ṣe da oun duro ko leṣẹ nlẹ labẹ ofin.















