Ohun tó ye kí o mọ̀ nípa òfin mátajà ní pópó èyí tó ti sọ èèyàn 34 sí àtìmọ́lé l'Eko

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọkunrin mẹtalelọgbọn (32), obinrin meji ni ile ẹjọ Majisreeti kan niluu Eko ti ju si ẹwọn bayii l'Ekoo, fun pe wọn n ta ọja lojuu popo.
Atimọle ọgba ẹwọn naa ni wọn yoo wa titi di ọjọ kejilelogun, oṣu Keje ọdun 2025, bi Adajọ ṣe paṣẹ.
Ana ode yii ti i ṣe ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹfa ọdun 2025 ni kootu naa to wa ni Bolade Osodi, niluu Eko paṣẹ yii.
Gẹgẹ bi kootu ṣe fidi ẹ mulẹ, awọn oṣiṣẹ ajọ Kick Against Indiscipline,(KAI), lo ko awọn ontaja naa loju ọna Alaba Rago, eyi to wa ni marosẹ Eko si Badagry.
Wọn fi kun un pe awọn LAWMA to n ri si ayika to mọ l'Ekoo naa lọwọ ninu bi wọn ṣe ko awọn ọlọja ọhun.
Awọn ibi to dọti ni a gbọ pe LAWMA tori ẹ lọ sibẹ, ki wọn too ri i pe awọn ontaja oju popo naa ti gba gbogbo ibẹ tan, wọn si ti kọ awọn ibugbe ti ko ba ofin mu sibẹ.
Lara awọn ti wọn tun ko ni awọn ọmọ ita ti wọn n sun ninu awọn ibugbe ti ko yẹ ọhun, wọn ni wọn n gba ibẹ huwa laabi.
Àwọn tí ọwọ́ òfin bà náà ni
Gẹgẹ bii akọsilẹ kootu, awọn to foju ba ile ẹjọ naa ni:
Ibrahim Abu, Isiaka Ashafa, Shaibu Isa, Abubakar Haruna, Aminu Haruna, Aminu Abdullahi, Zakariyahu Yahusa, Sunmola Musa ati Samsideen Ali.
Awọn mi-in ni : Anthony Oyibo, Abubakar Yusuf, Muhammed Oseni, Aliu Mohammed, Lookman Adebayo, Igudu Ibrahim, Awalu Umar, Sani Babangida, Abdullahi Usman, Aliu Ibrahim, Roland David ati David Timothy.
Bakan naa ni awọn wọnyi gbadajọ ẹwọn: Yusuf Adamu, Abdulsalam Sanusi, Nura Yusuf, Idris Isa, Nasiru Ali, Mayi Daniel, Isaac Samuel, Yahaya Mamuda, Salisu Ibrahim, Yusuf Adamu, Abdullahi Musa, Fadipe Bose ati Ebere Ndubuisi ti wọn jẹ obinrin meji to wa ninu wọn.
Ki ni ofin yii gan sọ nipa ọjà títà lójúu pópó nílùú Eko
Ko ruju rara pe ijọba ipinlẹ Eko koro oju si tita ọja lojuu popo.
Ofin ọdun 1984 to de ọja titi lojuu popo si wa titi di oni, eyi to jẹ ki ijọba maa fi mu awọn to ba lu ofin naa.
Alaye ijọba Eko ni pe imọtoto agbegbe ṣe koko, bẹẹ ni ẹmi awọn to n ta ọja ni titi yii naa si ṣe pataki.
Wọn ko si tun fẹ ohun ti yoo maa fa sunkẹẹre-fakẹẹrẹ
Wọnyi ni awọn koko to wa ninu ofin naa
Ofin naa tako tita ọja, ikiri tabi pipatẹ ọja si awọn agbegbe kan.
Ileeṣẹ eto ayika ati ẹka rẹ KAI, yoo maa mu ẹni to ba lufin.
Ìjìyà:
Owo itanran tabi ẹwọn ni ẹni to ba lufin yii yoo fi jura.
Awọn ibi ti wọn ti ofin naa ti mulẹ ju:
Third Mainland Bridge
Eko Bridge.
Ikoyi, Lekki ati Victoria Island.
Gbigba ọja awọn arufin
Awọn alaṣẹ maa n gba ọja awọn ọlọja to ba lufin yii, wọn yoo si ba wọn ṣe ẹjọ ni kootu alagbeka.














