Ohun tí a mọ̀ rèé nípa ìfẹ̀hónúhàn tó ń wáyé ní Los Angeles

Iwọde Los Angeles

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọpọ eeyan lo ti dero atimọle niluu Los Angele lẹyin ifẹhonuhan to waye latari bi awọn oṣiṣẹ aṣobode ṣe n ko awọn ti ko ni iwe igbelu l'Amẹrika.

Aarẹ Donald Trump ti da ẹgbẹrun meji ẹṣọ National Guard sigboro ilu naa, eyii to bi ẹgbẹ oṣelu alayako, Democrat ninu.

Lẹyin naa ni Trump tun da ẹgbẹrun meji ẹṣọ mii si igboro, to fi mọ ẹẹdẹgbẹrin ọmọ ogun US Marines.

Ifẹhonuhan naa bẹrẹ lẹyin ti awọn alaṣe bẹrẹ si n fi ṣikun ofin mu awọn ti ko ni iwe igbelu lagbegbe ti awọn ẹya Latino pọ si.

Bo tilẹ jẹ pe wọrọwọ ni iwọde naa bẹrẹ, awọn eeyan sọ ina si awọn ọkọ to n wa ara wọn ti wọn si di oju popo, eyii to jẹ ibẹrẹ rogbodiyan naa.

Ki ni idi ti awọn eeyan fi n ṣewọde ni LA?

Ọjọ Ẹti to kọja ni iwọde naa bẹrẹ nigba ti awọn oṣiṣẹ Immigration and Customs Enforcement (ICE) n lọ fi ṣikun ofin mu awọn ti ko ni iwe igbelu lagbegbe ti awọn ẹya Latino n gbe.

Awọn oṣiṣẹ ICE yii tunbọ mura si iṣẹ wọn lẹyin ti Donald Trump pada wọ White House gẹgẹ bii Aarẹ Amẹrika.

Ileeṣẹ iroyin CBS jabọ pe agbegbe Westlake ati Paramount, ni Los Angele, ti awọn Latino pọju si ni iṣẹ ICE ti milẹ titi julọ.

Ki lawọn nnkan to ti ṣẹlẹ ni LA lasiko iwọde naa?

  • Awọn oluwọde ti dana sun awọn ọko, bẹẹ lawọn ọlọpaa ti yin gaasi tajutaju si awọn eeyan
  • Ile ijọba 'Federal Building' wa lara awọn ibi ti awọn oluwọde dojukọ lẹyin ti wọn ni ibẹ gan ni ICE n ti awọn eeyan mọ
  • Ileeṣẹ ọlọpaa Los Angeles, LAPD, ti fi ṣikun ofin mu eeyan ti iye wọn to ọgọta lori ifẹhonuhan naa
  • Ọjọ Aje ni iwọde ọhun burẹkẹ si amọ awọn oluwọde pada dẹwọ iwọde ọhun
  • Yatọ si ọkọ ti awọn eeyan dana sun, awọn mii tun dada sun taya ọkọ laarin popo

Awọn wo ni ICE n le pada silẹ wọn?

Ninu oṣu karun ọdun yii, ICE kede pe oun ti mu eeyan to le ni igba ti wọn n gbe ni LA lai ni iwe igbelu.

Oṣu kan lẹyin naa ni atẹjade kan lati White House sọ pe awọn fẹ maa mu o kere tanẹgbẹrun mẹta eeyan lojumọ kan.

Lara awọn ibi ti wọn ti n mu awọn eeyan ni ile ounjẹ, ibisẹ, ile ẹkọ atawọn ibomii.

Pupọ awọn tiICE n dojukọ lawọn to wọ Amẹrika lọna ti ko bo ofin mu tabi awọn to kọ lati pada silẹ wọn lẹyin ti wọn ti lo ọpọ ọdun l'Amẹrika.