Àbọ̀ ìwádìí UN rèé lórí ìdì tí àwón èèyàn kò ṣe fẹ́ ẹ́ bí ọmọ púpọ̀ mọ́ ní Naijiria

Obinrin to ṣẹṣẹ bimọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Atẹjade kan lati ọdọ ajọ United Nations Population Fund (UNFPA), ti ṣalaye pe ọpọ lọkọlaya kaakiri agbaye lo ti n kọ lati bi ọmọ pupọ bayii latari bi ọrọ aje ṣe ri.

UNFPA sọ pe lara nnkan to ṣokunfa eyii ni bi ko ṣe rọrun lati maa tọ ọmọ lasiko yii, ati bi awọn mii kii ṣe n pade ololufẹ to dantọ.

Ninu egbẹrun mẹrinla eeyan ti ajọ ọhun ṣe iwadii nipa wọn ni orilẹede mẹrinla, esi iwadii naa fi han pe, eeyan kan ninu marun un lara wọn lo n sọ pe oun ko tii bi, tabi oun ko ni bi iye ọmọ to wa lọkan oun lati bi tẹlẹ.

Awọn orilẹede ti UNFPA ti ṣe iwadii naa ni South Korea, Thailand, Italy, Hungary, Germany, Sweden, Brazil, Mexico, US, India, Indonesia, Morocco, South Africa, ati Naijiria.

Awọn orilẹede yii lo jẹ akojọpọ awọn orilẹede to ri jajẹ, awọn to ṣẹṣẹ n goke agba to fi mọ awọn ti ko rọwọ họri lawujọ ẹgbẹ wọn.

Lara awọn ti UNFPA ṣe iwadii naa fun ni awọn ọdọ atawọn to ti kọja ipele ọmọ bibi.

Natalia Kanem, to jẹ adari ajọ UNFPA sọ pe kaakiri agbaye lawọn eeyan ti n din iye ọmọ ti wọn n bi ku.

Kanem ni "Pupọ ninu awọn ti a ba sọrọ ko fẹ bi ju ọmọ meji pere lọ.

"Ọpọ mọlẹbi ni ko fẹ bi ọmọ to pọ mọ latari iṣoro ati tọju wọn, ohun to buru julọ ninu ọrọ naa ree."

Nigba ti Anna Rotkirch to jẹ onimọ ijinlẹ nipa ọmọ bibi lagbaye n da si ọrọ naa, o ni yatọ si ọrọ aje, onikaluku lo ni idi ti wọn fi fẹ bi ọmọ to pọ amọ yoo ṣoro lati yọ eto iṣuna kuro nibẹ.

Ninu iwadii kan ti wọn ṣe nilẹ Yuroopu, o ni iyalẹnu lo jẹ pe ida 31% awọn ti wọn ba sọrọ ti ọjọ ori wọn ju aadọta ọdun lọ sọ pe awon ko biju ọmọ meji pere lọ.

Ninu gbogbo orilẹede ti iwadii naa ti waye, ida 39% awọn ti wọn ba sọrọ ni, ọrọ aje ni ko jẹ ki awọn bi ọmọ.

Lapapọ, ida mejila awọn ti wọn ba sọrọ lo sọ pe iṣoro airọmọbi ni ko jẹ ki awọn bimọ tabi ni iye ọmọ to wu wọn lọkan lati bi.