Aráàlú n ṣe ìwọ́de nítorí bí ọlọ́pàá ṣe ń mú àwọn tí Trump ní kó fi America sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ifẹhonuhan to n lọ niluu Los Angeles lorilẹede Amẹrika lori bi awọn ọlọpaa ati awọn aṣọbode ṣe n mu awọn ti ijọba Donald Trump sọ pe ki wọn fi orilẹede naa silẹ, ti wọ ọjo kẹta bayii.
Awọn oluwọde naa ati awọn ọlọpaa ijọba apapọ ti Trump ni ki wọn lọ pẹtu si iwọde to n lọ kọlu ara wọn.
Ifẹhonuhan ọhun bẹrẹ lẹyin tawọn agbofinro mu tọkọ-taya kan to n ṣe igbeyawo.
Awọn ẹṣọ alaaabo naa ti Aarẹ Trump paṣẹ pe ki wọn lọ si ilu Los Angeles lai sọ fun gomina ipinlẹ California ati adari ijọba ilu Los Angeles yin taju-taju ati ibọn to n lo ọta ti wọn fi rọba ṣe, lati tu awọn olufẹhohuhan ka.
Iwọde ọhun ti burẹkẹ sii lonii ọjọ Aje ti iwọde naa wọ ọjọ kẹta.
Ni ṣe lawọn olufẹhonuhan n dana sun ọkọ, bakan naa ni wọn n dana sun taya loju popo.
Ọpọ awọn oluwọde naa to kọlu awọn eleto aabo ni wọn ti fọwọ ṣinkun ofin mu bayii.
Aarẹ Trump ti ṣapejuwe awọn oluwọde naa gẹgẹ bii agbesunmọmi, ṣugbọn aarẹ ni awọn agbofinro gbọdọ pa ofin mọ ki wọn si ri pe alaafia jọba.
'Trump ti tapa sofin Amẹrika pẹlu bo ṣe ko awọn ẹgbẹrun meji ẹṣọ alaabo wa si Los Angeles'

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ẹwẹ, Gomina Gavin Newsom ipinlẹ California ti fẹsun kan Trump wi pe oun lo n da rogbodiyan silẹ lẹyin to ni ki awọn ẹṣọ eleto ẹgbẹrun meji wa si Los Angeles.
Ọgbẹni Newsom ni nnkan ti Trump ṣe lodi sofin, ati pe oun ṣetan lati gbe e lọ sile ẹjọ.
Gomina ipinlẹ California ni awọn ọlọpaa ipinlẹ naa koju oṣunwọn lati pana aawọ to bẹ silẹ.
O ni iyalẹnu lo jẹ fun oun pe Trump tun paṣẹ pe ki ẹgbẹrun meji ẹṣọ eleto abo tun wa si Los Angeles.
Gomina Newsom ni igbesẹ aarẹ yii lo bi awọn araalu ninu ti wọn fi bẹrẹ iwọde.
Labẹ ofin orilẹede Amẹrika, gomina lo maa n beere fun ẹṣọ eleto abo ijọba apapọ ki wọn to lọ si ipinlẹ kankan.
Eyi lo jẹ ki Newsom maa sọ pe, Trump ti tasẹ agẹrẹ si ofin Amẹrika.
Gomina Newsom to sọ pe ko si ijaya lori eto aabo ni Los Angeles, rọ awọn araalu pe ki wọn maa jẹ ki awọn agbesunmọmi ya wọn lo.
Gomina ipinlẹ mejilelogun l'Amẹrika ni wọn ti kede atilẹyin wọn fun Newsom bayii.
Lẹyin ti ilẹ ṣu tan lawọn ọlọpaa Los Angeles sọ pe awọn oluwọde ti lọ sawọn apa ibomiran.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti wa rọ gbogbo araalu atawọn olokowo wi pe, ki wọn fi to ọlọpaa leti ti wọn ba kofiri nkankan to mu ifura dani.
Ni bayii, awọn ọlọpaa ti n gba gbogbo idọti tawọn oluwọde naa ṣe kaakiri ojupopo niluu Los Angeles kuro.
Ọjọ diẹ sẹyin ni Aarẹ Trump tun kede pe, oun ti fi ofin de awọn orilẹede mejila kan pe, wọn ko ni anfaani lati wọ Amẹrika mọ.















