'Wọ́n fipá bá mi lò pọ̀ lẹ́ẹ̀mẹ́jọ láàárín wákàtí méje' - Obìnrin Benue ṣàlàyé ìkọlù

"Awọn darandaran ya bo agbegbe wa, wọn kọkọ mu awa obinrin, wọn fi wa pamọ si aaye ọtọ ki wọn too bẹrẹ si i kọlu awọn ọkunrin ti wọn si n yinbọn pa awọn ti ko ribi sa lọ ninu wọn."
Bayii ni obinrin kan to foju wina ikọlu ni agbegbe Edikwu Ankpali, nijọba ibilẹ Apa, ipinlẹ Benue, ṣalaye fun BBC.
Awọn eeyan ti wọn furasi pe darandaran ni wọn, ni wọn fẹsun kan wọn wa nidii ikọlu naa.
Ọjọ kin-in-ni si ọjọ keji oṣu Kẹfa, ọdun 2025 yii ni ikọlu ọhun waye.
Awọn obinrin bii mẹwaa ni wọn sọ pe ọpọ ọkunrin fipa ba lo pọ ninu ikọlu naa.
Wọn fi kun un pe awọn obinrin kan ṣi wa nileewosan bayii, ti wọn n gba itọju lọwọ latari ibalopọ ipa naa.
Ọkan ninu wọn sọ fun BBC pe ẹẹmẹjọ ni wọn fipa ba oun lo pọ laaarin wakati meje.
O ni lẹyin ti wọn ti kapa awọn ọkunrin ilu tan ni wọn bẹrẹ ibalopọ tulaasi naa laaarin ilu.
"Wọn ba mi lo pọ pẹlu ipa lẹẹmẹjọ ki ilẹ too mọ, awọn mi-in, ẹẹmẹwaa. Awọn darandaran naa to aadọta (50)"
Bẹẹ ni obinrin naa ṣalaye.
'A kò rí àwọn ìyàwó wa mọ́, àwọn tó wà nílé kò lè rìn dáadáa mọ́ nítorí ìbálòpọ̀ ipá tó ṣẹlẹ̀ sí wọn'

Ninu ọrọ Olori Ọdọ agbegbe yii, Odogbo Ngbede, o sọ fun BBC pe awọn ko ri awọn iyawo awọn mọ.
Ọkunrin naa ṣalaye pe awọn obinrin kan ti di awati lẹyin ikọlu buruku to kọlu wọn ọhun.
Ọmọbinrin kan ṣalaye pe jẹjẹ loun jokoo ti baba oun ti ara rẹ ko ya, ibi toun jokoo si naa ni awọn apaayan ti de.
"Wọn pa baba mi, wọn wa gbe mi lọ sibi kan lati fipa ba mi lo pọ ."
Ọmọbinrin naa lo fi ibanujẹ ṣalaye bẹẹ.
Ọpọ obinrin lo sọ fun BBC pe awọn ko le rin daadaa mọ bayii latigba ti ọkunrin pupọ ti ba awọn sun.
Ọjọ ori awọn obinrin to lugbadi ibalopọ ipa naa wa laaarin ọdun marundinlogoji si ọgọta (35 -60 years).
'Èèyàn tó di olóògbé nínú ẹbí mi ju mẹ́fà lọ'
Iya kan, Arabinrin Sarah (ti a fi orukọ rẹ gan-an bo laṣiiri), to sa kuro labule lọ si olu ilu naa, sọ fun BBC pe awọn darandaran ti le oun kuro labule bi wọn ṣe le awọn eeyan yooku.
O ni wọn pa baba oun to ti di arugbo, oun ko si ri awọn mọlẹbi oun kan naa mọ.
Arabinrin Sarah sọ pe to ba jẹ pe awọn ẹbi oun naa wa laye ni, wọn yoo ti kuro nibi ti wọn sa pamo si.
O ni aipada wale wọn ko nitumọ meji ju pe wọn ti pa wọn lọ.
"Gbogbo ẹbi mi ni wọn ti fẹrẹ pa tan, mi o ni i pada sabule, afi bijọba ba ran wa lọwọ.
"Bẹẹ naa ni ebi ṣe n pa wa, a o le lọ soko mọ, ita ni mo n sun latijọ yii, ki n too sa kuro labule, eeyan mọkandinlọgbọn (29) ni wọn ti pa".
Sarah sọ pe aanu Ọlọrun loun naa ri gba, toun ko fi riku he.
Gomina Benue sọrọ, o ni inú ìkọlu ńlá làwọn wà
Ninu ọrọ Gomina ipinlẹ Benue, Hycinth Alia, o ni inu ikọlu nla ni ipinlẹ naa wa, oun ko si ri ija naa bii ti agbẹ ati darandaran rara.
Lori tẹlifiṣan Channels ti Gomina Alia ti sọrọ lọsẹ to kọja lo ti ni ikọlu ti awọn eeyan naa n mọ-ọn-mọ ṣe lo n waye ni Benue.
"Ikọlu yii kọja ọrọ ẹlẹyamẹya laaarin agbẹ ati darandaran, igbesunmọmi ati atako gidi ni.
"Wọn ko mu ẹnikẹni ninu awọn to n kọlu wa naa ri, oru ni wọn n wa ti wọn n pa wa. Bi wọn ba pa wa tan, wọn a sa lọ".
Bẹẹ ni Gomina Alia wi.
O le ni aadọta eeyan to ku ninu ikọlu to waye yii, bẹẹ ni wọn ṣi n wa awọn eeyan kan.














