Àwọn afurasí darandaran yawọ ìlú, wọ́n kún àwọn èèyàn bí ẹran

Sàárè àwọn èèyàn tó ti kú

Oríṣun àwòrán, JOHNSON IKWULONO

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Àwọn tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìkọlù táwọn darandaran ṣe sáwọn èèyàn ìjọba ìbílẹ̀ Gwer West àti Apa ní ìpínlẹ̀ Benue ti wọ àádọ́ta báyìí gẹ́gẹ́ bí àwọn aláṣẹ ṣe sọ.

Àwọn afurasí darandaran ọ̀hún ni wọ́n yawọ Tse-Antswam ní Ìlú Naka tó jẹ́ olú ìlú ìjọba ìbílẹ̀ Gwer West àti Edikwu ní ìjọba ìbílẹ̀ Apa.

Ìròyìn ní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló kú, táwọn míì sì farapa nígbà táwọn míì sá àsálà fún ẹ̀mí ara wọn.

Gẹ́gẹ́ bí alága ìjọba ìbílẹ̀ Gwer West, Victor Ormin àti olóyè ìlú náà, Daniel Abomtse ṣe sọ, òkú èèyàn mọ́kànlélógún ni wọn ti rí.

Olóyè Abomtse sọ pé àwọn tó wà ṣe ìkọ́lú náà yawọ ìlú Tse Antswam, tí wọ́n sì ń fi àdá ṣá àwọn èèyàn.

Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló farapa yánnayànna.

"Mi ò gbàgbọ́ pé àwọn kan le móríbọ́ lọ́wọ́ ikú bí wọ́n ṣe ṣá àwọn èèyàn kódà ọ̀pọ̀ èèyàn ni àwọn ṣì ń wá nítorí ọ̀pọ̀ ló sá wọ inú igbó pẹ̀lú ọgbẹ́ ìbọn àti àdá lára, táwọn míì sì ń kó sínú kàǹga láti móríbọ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn tó wá ṣe ìkọlù ọ̀hún."

Olóyè náà fi kun pé ìlú tí ìkọlù náà ti wáyé ló wà ní ìdojúkọ ibi àyẹ̀wò àwọn ológun tó wà ní òpópónà Naka/Makurdi.

Èèyàn mẹ́tàdínlógójì pàdánù ẹ̀mí wọn ní Edikwu

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ní ìlú Edikwu ẹ̀wẹ̀, àwọn èèyàn tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìkọlù àwọn darandaran náà ti wọ mẹ́tàdínlógójì.

Alága ìjọba ìbílẹ̀ Apa, Adam Ogwola tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ sọ pé ó ṣeéṣe kí iye tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn tún pọ̀ si nítorí àwọn ṣì ń wá àwọn èèyàn àti pé àwọn ṣì ń rí òkú èèyàn si.

Ó ní ìkọlu náà jẹ́ èyí tó ba àwọn lọ́kàn jẹ́ gidi.

Ọ̀kan lára àwọn olórí ìlú náà, John Ikwu sọ pé òkú èèyàn márùndínlọ́gbọ̀n ni àwọn kọ́kọ́ rí lọ́jọ́ Àìkú ní Edikwu Ankpali.

Ikwu ní àsìkò tí to fáwọn láti máa kojú àwọn jàgùdà náà fúnra àwọn nítorí ìpànìyàn tó ń wáyé náà kò bá ojú mu rárá.

Ó fi kun pé àwọn tó ń ṣe ìkọlù náà kò ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run rárá, tí wọ́n sì ń da ìlú wọn láàmú ní gbogbo ìgbà.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Benue, Udeme Edet fi léde lọ́jọ́ Ajé sọ pé Kọmíṣánnà ọlọ́pàá Benue, Emenari Ifeanyi tin í kí wọ́n gbé Area Commander agbègbè náà lọ sí Apa.

Bákan náà ló ní kí ikọ̀ tó ń máa ń tọpinpin ìṣẹ̀lẹ̀ gba àkóso Naka tó sì tún da àwọn ọlọ́pàá sáwọn ààyè tó ṣe pàtàkì ní ìjọba ìbílẹ̀ Gwer West àti Apa.

Àtẹ̀jáde tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fi síta sọ pé èèyàn méjìlélógún ló pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ìkọlù náà lápapọ̀ àti pé èèyàn márùn-ún ló wà ní ilé ìwòsàn tí wọ́n ń gba ìtọ́jú fún bí wọ́n ṣe farapa.

"Láti bíi oṣù kan láwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tí wọ́n wà láwọn agbègbè yìí ti ń kojú àwọn tó ń ṣe ìkọlù yìí, tí wọ́n sì ti ń kojú wọn láwọn ibìkan," àtẹ̀jáde náà sọ.

Kọmíṣánnà ọlọ́pàá náà fi kun pé àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ti wà láwọn tó ṣe kókó láti mójútó ìwọlé àti ìjáde láwọn ìlú náà.

Ọ̀gá ológun balẹ̀ sí Benue

Sàárè àwọn èèyàn tó ti kú

Oríṣun àwòrán, JOHNSON IKWULONO

Ẹ̀wẹ̀, ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà, Olufemi Oloyede ti balẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Benue, tí yóò sì lo ọjọ́ díẹ̀ níbẹ̀ láti mójútó ìpèníjà ààbò tó ń bá ìpínlẹ̀ náà fínra kó tó padà sí Abuja.

Ọ̀gá ológun náà ṣe ìpàdé ìdákọ́ńkọ́ pẹ̀lú gómìnà Hyacinth Alia ní kété tó balẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Benue.

Lẹ́yìn ìpàdé náà, Gómìnà Alia ní ọ̀gá ológun náà mú ìròyìn bí ìdẹ̀kùn ṣe máa bá àwọn ìpínlẹ̀ náà lọ́wọ́ ìkọlù gbogbo ìgbà táwọn afurasí darandaran náà ń ṣe.

Ó sọ àrídájú rẹ̀ pé ìjọba àpapọ̀ yóò tún pọnkún ìgbìyànjú wọn láti kojú ìṣòro yìí.

Àwọn olórí ìlú àtàwọn alẹ́nulọ́rọ̀ lẹ́ka ètò ààbò ní ìpínlẹ̀ Benue ló wà níbi ìpàdé náà.

Ìpínlẹ̀ Benue jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìpínlẹ̀ tí àwọn afurasí darandaran máa ń ṣe ìkọlù sí, tí wọ́n sì máa ṣekúpa ọ̀pọ̀ èèyàn.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni gómínà ìpínlẹ̀ náà ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù yìí, síbẹ̀, ó ṣì ń wáyé lọ́pọ̀ ìgbà.