Wo bí o ṣe le dífá lọ́dọ́ babalawo láti orí fóònù rẹ láti ibikíbi l'ágbàáyé

Àkọlé fídíò, Àjọṣepọ̀ wo ló wá láàrín ìmọ̀ ẹ̀rọ àti kíkàn sí Ifá?
Wo bí o ṣe le dífá lọ́dọ́ babalawo láti orí fóònù rẹ láti ibikíbi l'ágbàáyé

Ọpọ nnkan ni aye iṣin yii lo ti ni ajọṣepọ pẹlu imọ ẹrọ, ti afikun yii si ti mu ọpọ ayipada ba awọn ohun isẹbanye, gbeaye ọmọ eniyan ati ọna ti wọn n gba ṣe oriṣiriṣi nnkan.

Eyi ko yọ biba Ifa sọrọ silẹ, koda imọ ẹrọ ti mu ayipada nla ba awọn ẹṣin babanla wa ni ilẹ kaarọ ojiire.

Lorilẹede Najiria, awọn eeyan to gbagbọ ninu ẹṣin Kristẹni ati Musulumi pọ ju awọn to gbagbọ ninu Ifa lọ.

Lọdun 2008, ajọ UNESCO fi Ifa kun ọna lati ba Eledua sọrọ ninu awon ohin isẹmbaye.

Lati ayebaye, ti ẹnikẹni ba nilo lati ba Ifa ni gbolohun tabi wa ojuutu si nnkan, onitọhun yoo nilo lati lọ si ile babalawo ni tabi ko pe babalawo wa sinu ile rẹ gẹgẹ bi awọn ọlọrọ ati awọn alagbara ṣe ma n sẹ ni igba atijọ.

Amọ ni bayii, o ti le ba Ifa sọrọ lati ori foonu rẹ lai kuro ninu ile rẹ.

Eyi ri bẹẹ pẹlu imọ ẹrọ ayelujara aapu akn ti babalawo kan, Olawole Olukunle, ṣẹṣẹ ṣe.

Olawole Olukunle

Bawo ni aapu naa ṣe n ṣiṣẹ?

Aworan Babalawo to gbe Ifa janle

Olawole Olakunle, to jẹ babablawo, ba BBC sọrọ lori ipa ti imọ ẹrọ n koninu ẹsin Ifa ati awọn nnkan aṣa miiran.

"Ọpọ ayipada rere ni imọ ẹrọ n mu ba awọn nnkan ẹmi, Imọ ẹrọ ti mu ayipada ba oju ti a n fi wo ẹṣin ati aṣa wa ."

Olakunle ni, ọpọ awọn eeyan ni wọn ko mọ ọna ti wọn le gba ri babalawo, lo mu ki oun ṣe aapu ori ayelujara kan nibi ti awọn eeyan ti le kan si babalawo lai kuro ninu ile wọn.

O ni awọn eeyan yoo ra owo ẹyọ ori ayelujara lati le ba Babalawo sọrọ, ti Babalawo yoo si fesi lori owo ti o fẹ gba lọwọ wọn.

Aapu naa ni Olakunle sọ pe o ni ọna lati da ojulowo mọ ninu awọn eeyan ti yoo ma lo.

Ninu oṣu kẹfa yii ni Aapu ọhun ti wọn pe orukọ rẹ ni Priest.Africa bẹrẹ iṣẹ, to si ti le ni aadọta babalawo to ti fi orukọ silẹ bayii.

Olakunle sọ pe aapu naa yoo mu idagbasoke ba iṣẹ awo.

"Ọpọ awọn Babalawo lo ti ni anfaani bayii lati fi iṣẹ wọn han fun araye."