'Àwọn èèyàn ma n sá, wọ́n sì má n bẹ̀rù ẹbí mi nítorí Trichoepithelioma tó mú wa'

Àkọlé fídíò, 'Àwọn èèyàn ma n sá, wọ́n sì má n bẹ̀rù ẹbí mi nítorí Trichoepithelioma tó mú wa'
'Àwọn èèyàn ma n sá, wọ́n sì má n bẹ̀rù ẹbí mi nítorí Trichoepithelioma tó mú wa'
    • Author, Busayo James-Olufade
    • Role, Senior Journalist
    • Reporting from, Lagos

Oriṣiriṣi ọna ni aisan ma n gba ṣiṣẹ ninu agọ ara ẹda, amọ ara ọtọ ni ti aisan Trichoepithelioma to jẹ pe lati irandiran lo fi n rin kaakiri ninu ẹbi.

Lara iyalẹnu to wa ninu aisan yii ni pe, kii ran ẹni ti ko ba ba ẹbi yii tan, awọn ọmọ inu ẹbi naa nikan ni.

O ti ẹ ṣe e ṣe ko fi iran kan silẹ, ko mu iran mii.

Bẹẹ gẹlẹ lo ṣe ri fun ẹbi Bassey, pẹlu bi aisan Trichoepithelioma ṣe ti ran wọn de iran kẹta bayii.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba, ni ẹbi naa ti sọ pe iya wọn to ti d'oloogbe, ni aisan naa kọkọ jade si lara.

Lẹyin ọdun diẹ lo bẹrẹ si ni jade si ara awọn ọmọ rẹ.

Koda, awọn ọmọ naa ti dagba daadaa ki wọn o to ni iriri yii.

Bẹẹ ni aisan naa ṣe ṣe to tun ran awọn ọmọọmọ.

Arabinrin Edem Bassy

Ẹni to dagba ju ti a ba sọrọ ninu ẹbi naa, Arabinrin Edem Bassey Eke ṣalaye pe, awọn eeyan ma n sa fun awọn.

"Paapaa emi ti toju mi pọ. Niṣe ni ẹlomii ti ẹ ma n pariwo Jesu, Jesu, ti wọn ab ti ri oju mi."

Arabinrin Bassey sọ pe koko kan lo kọkọ jade si oju oun, ko to o wa pọ bayii.

Ori lo ti kọkọ bẹrẹ pẹlu rẹ, ti wọn si ge e nigba to wa ni ọdọ. Lẹyin naa lo di nnkan to jẹ pe, gbogbo oju rẹ lo jade si.

Bakan naa lo sọ pe aisan ọhun ni ko jẹ ki ẹgbọn rẹ kan to ti di oloogbe bayii, ri ọkọ fẹ.

Idi ni pe, ọkunrin naa lẹyin ti wọn ti kọkọ bimọ fun ara wọn, kọ jalẹ lati fẹ ẹ nitori igbagbọ pe aisan naa yoo ran an.

Ẹwẹ, Arabinrin Edem sọ pe yatọ si iwa buruku ti awọn ọkunrin kan ma n wu, oun gbagbọ pe, bi oju oun ṣe ri ni ko jẹ ki oun ri ọkọ fẹ.

Ọmọ meji ni arabinyin yii ti bi, awọn ọmọkunrin naa, Damilare ati si lo ni Trichoepithelioma.

'Awa mẹrin ta a tẹle ara wa ninu ọmọ iya wa lo mu'

Ẹbi to ni Trichoepithelioma

Ni ti aburo rẹ ti oun naa jẹ obinrin, Arabinrin Asibong Kubiangha, o wa loju ti ẹ naa, amọ ko fi bẹẹ pọ to ti ẹgbọn rẹ, Edem.

Arabinrin Kubiangha ṣalaye pe aisan naa ko jade si ara ẹni to jẹ akọbi iya wọ.

"Ọmọ mẹfa ni iya wa bi, awa mẹrin to jẹ obinrin, ta a si wa laarin nikan ni aisan yii mu

"Ko mu ẹni to jẹ akọbi, ati ẹni to jẹ abigbẹyin."

Ko si si ẹnikan ninu wọn ti o kere tan, ọmọ rẹ , ko ni aisan naa.

Lara awọn iriri ti Arabinrin Kubiangha ti ni nitori aisan Trichoepithelioma ni pe, laipẹ yii to gbe ọmọ rẹ lọ si ileewosan, ni dokita kan fi ọrọ gba omije loju rẹ.

"Nibi ti a ti n duro lati ri dokita, ni dokita kan ti jade, to si bẹrẹ si ni pariwo pe ki emi ati ọmọ mi jade sita.

"O ni aisan monkey pox lo wa lara wa, ka jade ka ma ba a ko ran ẹlomii. Gbogbo alaye ti mo ṣe pe kii ṣe monkey pox, ni ko wọ eti rẹ rara."

Arabinrin Kubiangha sọ pe omije kikoro bọ ni oju oun, nitori pe dokita naa fi oun ṣẹsin laarin ọpọ eero.

"Ọmọ ti mo gbe lọ sile iwosan lo tun la dokita naa lọyẹ nipa Trichoepithelioma."

'Obi kan sọ fun mi nile ẹkọ mi pe, ki n fi itọ fọ oju'

Gershom Kubiangha

Ọkan lara awọn ọmọ Arabinrin Kubiangha, Gershom, sọ fun BBC pe iriri ti ko dun mọ ni ninu, ni aisan Trichoepithelioma, n fun oun.

Gershom ṣalaye pe, oriṣiriṣi awọn ọrọ ibanujẹ ati iwa ti ko bojumu ni awọn eeyan ma n sọ ti wọn si n hu si oun nitori aisan naa.

"Iṣẹlẹ kan ṣẹlẹ laipẹ yii nigba ti obi akẹgbẹ mi nile ẹkọ ri mi, bo ṣe ri mi bayii, lo n sọ lọ pe, o jẹ lọ fi ìtọ̀ fọ oju rẹ.

"Nnkan to sọ ba mi ninu jẹ, ṣugbọ̀n mo kan mi ori mi pe, o ma ṣe o."

Ọdọmọkunrin naa sọ pe oun ti gba kamu ipo ilera ara oun, nitori ti oun ko ba gba kamu, oun yoo kan ni irẹwẹsi ọkan ni.

'Iha ti awọn eeyan kọ si mi lo jẹ ki n bẹrẹ ilanilọyẹ nipa Trichoepithelioma'

Damilare ti gba kadara nipa aisan ara rẹ, o si n ṣe ipolongo lori ayelujara lati la awọn lọyẹ nipa Trichoepithelioma
Àkọlé àwòrán, Damilare ti gba kadara nipa aisan ara rẹ, o si n ṣe ipolongo lori ayelujara lati la awọn lọyẹ nipa Trichoepithelioma

Ọkan lara awọn ọmọ ti Arabinrin Edem Bassey Eke bi, Damilare Joseph, sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo naa pe, nnkan ti awọn eeyan ma n sọ lo mu ki oun bẹrẹ ipolongo lori ayelujara.

Damilare to jẹ akẹkọọ nile ẹkọ giga fasiti ilu Calabar, sọ pe niṣe ni awọn eeyan ma n bẹru lati sun mọ oun.

Nnkan to yẹ ki o mọ nipa Trichoepithelioma

Dokita Uche Ojinmah, onimọ nipa awọ ara, sọ fun BBC pe, aisan Trichoepithelioma jẹ ajogunba, to m an ran lati iran kan si omiran.

O ni "Trichoepithelioma kii ran ara ita, inu ẹbi lo ma n duro si i.'

Yatọ si eyi, aisan naa jẹ eyi ti ko wọpọ rara.

Bakan naa lo sọ pe aisan naa le mu iran kan, ko fo iran to tẹle wọn, ko si tun mu iran miran.

"O le wa ni oju, ori tabi ẹyin ọrun."

Dokita Ojinmah ṣalaye pe fi fi awọn nnkan bi iyọ ati itọ fọ ara nitori Trichoepithelioma, jẹ nnkan to lewu pupọ, to si le mu ki aisan naa di jẹjẹrẹ si ara.

Koko nnkan to ma n fa aisan yii gẹgẹ bi akọsilẹ to wa ni oju opo ayelujara Medline Plus, ẹka yara iyawekawe nipa ilera to tobi julọ l'agbaye, eroja ara kan ti wọn n pe ni CYLD gene, lo ma n fa Trichoepithelioma.

Ti CYLD gene yii ba pin yẹlẹyẹlẹ kaakiri ara lo ma n fa a.

Iṣẹ ti jinni naa n ṣe ni pe o ma n tọpinpin bi eroja protein to n mojuto iṣẹ eroja miran ti wọn n pe ni nuclear factor-kappa-B.

Nuclear factor-kappa-B yii jẹ apapọ protein to ma n daabo bo awọn sẹẹli inu ara ki wọn o ma ba a bajẹ nitori nnkan ti wọn doju kọ.

Awọn apẹẹrẹ ti Trichoepithelioma kọkọ ma n fihan

Gẹgẹ bi akọsilẹ ṣe sọ, ọdun 1962 ni wọn kọkọ kẹẹfin aisan naa.

Iwadii sayẹnsi loju opo sọ pe koko kekere lo kọkọ ma n jade si oju, ori, ipenpeju tabi ọrun ẹni ti aisan naa ba ti ran.

Koko naa kii mu inira dani tabi dun ẹni to ba ni i. O ma n le lọwọ, amọ kii di egbo

Oriṣiriṣi àwọ̀ lo ma n gbe jade lasiko ayẹwo, wọn si ma n fun ni awọn orukọ bii:

  • Basaloid Epithelioma
  • Basal Cell Carcinoma
  • Cylindroma
  • Syringoma
  • Epidermoid cyst
  • Sebaceous hyperplasia
  • Microcystic adnexal carcinoma
  • Trichoadenoma
  • Tumor of follicular infundibulum
  • Basaloid follicular hamartoma
  • Trichilemmoma
  • Trichofolliculoma
  • Trichilemmal Cyst (Pilar Cyst)

Iru itọju wo lo wa fun Trichoepithelioma?

Aisan kan to nira pupọ lati tọju ni Trichoepithelioma, eyi to fi le mu ki eeyan sọ pe, ko gboogun.

Lara awọn itọju ti awọn onimọ ilera kan n sọ ni ṣiṣe iṣẹ abẹ lati fi yọ awọn koko naa kuro ni ara, fifi irinṣẹ fa awọn koko naa, iṣẹ abẹ to n lo ina ẹlẹtiriiki.

Amọ ohun kan to wa nibẹ ni pe, ko si aridaju pe awọn itọju naa yoo ṣiṣẹ, to si le ba irisi oju jẹ.