Wo ìlú tó ti jẹ dandan fún ọkọ láti rà kẹ̀kẹ́ fún ìyàwó kí ìgbeyàwó tó ó le wáyé

Aworan ọkunrin ati obinrin lorii kẹkẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ohun to n dun ni lo n pọ lọla ẹni, ologun ẹru ku, aṣọ rẹ jẹ ẹyọ kan ṣoṣo.

Fun awọn obinrin ilu kan ti wọn n pe ni Askira, to wa nipinlẹ Adamawa, Ariwa-Ila-Oorun Naijiria, kẹkẹ lo jẹ wọn logun ju ohunkohun lọ ṣiwaju igbeyawo.

Nibi ti kẹkẹ gbayi de lọdọ awọn obinrin Askira, dandan ni ki ọkunrin to ba fẹẹ fẹ wọn ra kẹkẹ mọ ẹru obinrin ti yoo gbe niyawo.

Niṣe ni wọn maa n kọ kẹkẹ naa mọ ẹru iyawo gẹgẹ bi awọn ẹru iyawo yooku bii aṣọ, abọ ijẹun ati awọn nnkan eelo ile miran ti iyawo nilo.

Kẹkẹ ọhun gbayi to bẹẹ gẹẹ to fi jẹ pe awọn obinrin Askira maa n tori rẹ kọ fun ọkunrin, wọn ko ni i fẹ ẹ.

Awọn ọkunrin pẹlu si ti mọ pe bi owo kẹkẹ ko ba ti i si fun iyawo, iru ọkunrin bẹẹ ko ti i ṣetan lati fẹyawo niyẹn.

Kí ni ìdí ti àwọn obìnrin Askira fi ni dandan ni kẹ̀kẹ́?

Ninu alaye awọn obinrin Askira to ba BBC Pidgin sọrọ, wọn fidi ẹ mulẹ pe ki i ṣe pe awọn n fi kẹkẹ naa ṣe faari.

'' Ninu aṣa wa, lara ohun to gbọdọ wa ninu ẹru iyawo ni kẹkẹ.

''Idi keji ni pe a ko niṣẹ meji ti a n ṣe ju iṣẹ oko lọ, eyi jẹ ki kẹkẹ wulo fun wa, nitori oun la fi n ko ere oko wale.

''Kẹkẹ la fi n gbe awọn igi ti a ba ṣẹ loko wale, oun la maa fi lọ ọ ta a lọja.

''Awọn ọmọ wa yoo ṣaa jẹun, wọn yoo lọ sile ẹkọ, wọn yoo wọ mọto, igbesi aye ko dẹrun.

"Awọn owo ti a ba ri lati ara kẹkẹ ta a fi n gbe ara wa ati nnkan oko wa naa la n na.

''Emi o le fẹ ọkunrin ti ko ba le ra kẹkẹ fun mi ka too ṣegbeyawo o.''

Bẹẹ ni ọkan ninu awọn obinrin Askira ṣalaye.

'Mo ń tà tó ogójì kẹ̀kẹ́ lóṣù kan'

Huzairu Saidu, ọkunrin kan to n ta kẹkẹ ni Askira, sọ fun BBC pe oun maa n ta to ogoji kẹkẹ (40) laaarin oṣu kan.

O ni kẹkẹ tuntun maa n to ẹgbẹrun lọna àádọ́sàn-án naira (170,000).

Aloku lo ni o le maa ju ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan (100,000) lọ.

Ṣugbọn ati tuntun, ati aloku, ọkọ to fẹẹ fẹyawo gbọdọ gbe kẹkẹ kan kalẹ pẹlu awọn ẹru iyawo to ra.

Bi ko ba si kẹkẹ ninu ẹru iyawo, igbeyawo ko ṣe ni Askira bi wọn ṣe sọ.