'Pẹ̀lú ìbùsùn ní omí gbé ọ̀pọ̀ èèyàn lọ, kódà ọmọ ìyá kan nàá mẹ́rin wà lára wọn'

Àkọlé fídíò, 'Pẹ̀lú ìbùsùn ní omí gbé ọ̀pọ̀ èèyàn lọ, kódà ọmọ ìyá kan nàá mẹ́rin wà lára wọn'
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Ibusun

Awọn eniyan ilu Mokwa nipinlẹ Niger ṣi n ka adanu wọn, lẹyin ti ẹkun omi ba ọpọlọpọ dukia jẹ, to si tun gba ẹmi awọn eeyan.

Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni Naijiria, National Emergency Management Agency (NEMA) kede pe iye eeyan ti agbara omi gbe lọ nipinlẹ Niger ti pe aadọjọ niye.

Agbẹnusọ ajọ naa, Ibrahim Husseini, sọ fun ileesẹ iroyin AFP pe afikun yii waye lẹyin ti awọn tun ri awọn oku mii yọ ni nnkan bii kilomita mẹwaa si ilu Mokwa ti agbara omi naa ti kọkọ ṣọṣẹ.

O kere tan, ẹgbẹrun mẹta eeyan lo ti di alainilelori ti ile to le ni igba si ti ba iṣẹlẹ ọhun lọ.

Ile ti omi wo lulẹ

Ninu ifọrọwanilẹnuwo ti akọroyin BBC, Azeezat Olaoluwa, ṣe fun awọn olugbe ilu naa, lo ti di mimọ pe oju orun ni pupọ ninu awọn eniyan naa wa nigba ti agbara ojo ya de, to si gbe wọn lọ.

Arabinrin Ramat Suleiman sọ fun BBC pe, awọn ko le gbagbe iṣẹlẹ naa rara, nitori pe iru rẹ ko ṣẹlẹ ri.

O ni oun ṣẹṣẹ kirun idaji tan ni oun n gbọ ariwo ti awọn eeyan n ke fun iranlọwọ.

"Bi mo ṣe ṣi ilẹkun ni omi yabo ile wa, ti mo si bẹrẹ si ni pariwo ki awọn ara ile le jade."

O ni ọpẹlọpẹ ilẹkun ẹyinkule ni awọn to wa nile naa ni awọn fi raaye jade.

Arabinrin Suleiman ṣalaye pe obinrin kan to wa nitosi ile oun padanu ọmọ rẹ mẹrin sinu omiyale naa.

"Ariwo iya mi ẹ gba wa, ẹ gba wa, ni awọn ọmọ naa n pa amọ ti iya wọn ko le ran wọn lọwọ.

"Ọpọ eeyan lo jẹ pe ori igi ni wọn wa. Niṣe la ri awọn eeyan ti omi n gbe e lọ pẹlu ibusun wọn, atọmọde ati agba."

Bakan naa ni arabinrin naa fi kun ọrọ rẹ pe, eeyan marun un ni wọn n sin sinu iboji kan ṣoṣo.

O ni oun paapaa, iro ti oun ro lati fi kirun nikan ni dukia ti oun ni, amọ oun "dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o ko oun yọ.

Oju ọna ti agbara ojo wo lulẹ

Ijọba ti kọ ibudo ifiniwọ si fun awọn ti ile wọn wo lulẹ

Ọpọlọpọ ile ni omi gbe lọ pẹlu awọn eeyan to wa ninu rẹ
Àkọlé àwòrán, Ọpọlọpọ ile ni omi gbe lọ pẹlu awọn eeyan to wa ninu rẹ

Aarẹ Bola Tinubu paṣẹ pe ki NEMA ṣe ibudo kan sagbegbe naa lati maa doola awọn ti iṣẹlẹ naa pa lara julọ.

Husseini sọ pe "A yọ awọn oku kan labẹ awọn ile to dawo" lasiko to n ṣalaye pe ikọ oun yoo nilo awọn irinṣẹ nla lati maa ko awọn oku jade nibẹ.