Iye èèyàn tí àgbàrá omi gbé lọ ní ìpínlẹ̀ Niger tí lé ní 150

NEMA

Oríṣun àwòrán, NEMA

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni Naijiria, National Emergency Management Agency (NEMA) ti kede pe iye eeyan ti agbara omi gbe lọ nipinlẹ Niger ti pe ọgọrun ati aadọta bayii.

Agbẹnusọ ajọ naa, Ibrahim Husseini, sọ fun ileesẹ iroyin AFP pe afikun yii waye lẹyin ti awọn tun ri awọn oku mii yọ ni nnkan bii kilomita mẹwaa si ilu Mokwa ti agbara omi naa ti kọkọ ṣọṣẹ.

O kere tan, ẹgbẹrun mẹta eeyan lo ti di alainilelori ti ile to le ni igba si ti ba iṣẹlẹ ọhun lọ.

Iroyin yii lo n waye lẹyin ti Aarẹ Bola Tinubu paṣẹ pe ki NEMA ṣe ibudo kan sagbegbe naa lati maa doola awọn ti iṣẹlẹ naa pa lara julọ.

Husseini sọ pe "A yọ awọn oku kan labẹ awọn ile to dawo" lasiko to n ṣalaye pe ikọ oun yoo nilo awọn irinṣẹ nla lati maa ko awọn oku jade nibẹ.

O ṣalaye siwaju si pe ọpọ eeyan ni wọn ṣi n wa, ati pe ninu idile ẹlẹni mejila kan, eeyan mẹrin pere lawọn ṣi ri ninu wọn.

Ṣaaju ni Aarẹ Bola Tinubu ti kọkọ ba awọn eeyan naa kẹdun to si kan an nipa fun awọn adoola ẹmi lati ri daju pe wọn doola gbogbo awọn ti ọrọ naa kan.

Wayi o, NEMA ti sọ pe iṣẹlẹ yii n ṣapẹrẹ ewu to wa ninu ki eeyan maa kọ ile si agbegbe ti omi wa.

Iṣẹlẹ omiyale naa lo waye lẹyin ti ojo arọrọda kan waye lẹba dagun omi River Niger.

Omíyalé pa ọgọ́rùn-ún èèyàn ní ìpínlẹ̀ Niger, ọ̀pọ̀ dúkìá ṣègbé

Aworan iṣẹlẹ omiyale to gba gbogbo agbegbe kan ni Niger

Oríṣun àwòrán, Mukail Musa

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

O ti to ọgọrun-un kan ati mẹwaa eeyan to ti padanu ẹmi wọn bayii ninu ijamba omiyale to waye nipinlẹ Niger.

Adele ọga agba ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Niger, (Niger State Emergency Management Agency) NASEMA, Dokita Ibrahim Husain, fidi onka naa mulẹ fun BBC.

Gẹgẹ bo ṣe wi, Alẹ Ọjọruu ọsẹ yii ni iṣẹlẹ omiyale ọhun waye nijọba ibilẹ Mokwa.

Ojo nla to rọ lo fa a ti omi fi ya bo awọn ile kiri, to ba ọpọ ile itaja jẹ pẹlu awọn ọja ti wọn n ta.

Ojo naa ko ṣai ba awọn nnkan oko jẹ pẹlu, bi alaye ti wọn ṣe.

Atẹjade ti NASEMA fi sita l'Ọjọbọ, ṣalaye pe agbegbe meji ni idaamu omiyale naa ba.

Awọn adugbo naa ni Tiffin Maza ati Anguwan Hausawa to wa niluu Mokwa, nijọba ibilẹ Mokwa.

"Ojo nla rọ fun ọpọ wakati, bẹẹ ni àgbàrá ojo bẹrẹ si i pọ si i to si n bo awọn ile mọlẹ.

"Omi naa bo ile to le ni aadọta (50), mọlẹ pẹlu awọn eeyan to wa ninu rẹ."

Bẹẹ ni atẹjade NASEMA wi.

Ajọ naa ni oun yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba ibilẹ Mokwa, awọn omuwẹ ati awọn akin eeyan to ba le ṣe iranwọ lati maa doola awọn eeyan ti ko ba ti i ku.

Bakan naa ni wọn ni wọn yoo maa gbe awọn to ba ti ku jade.

'A ti rí èèyàn mẹ́ta dóòlà'

Diẹ lára àwọn oku ti wọn ri gbe

Oríṣun àwòrán, Mukail Musa

Atẹjade NASEMA tẹsiwaju, pe eeyan mẹta ti i ṣe obinrin kan ati awọn ọmọde meji lawọn ti doola ẹmi wọn.

Ileewosan ijọba to wa ni Mokwa ni awọn mẹta naa wa bayii bi NASEMA ṣe wi, wọn n gba itọju fun ijaya to mu wọn ati ara ti wọn fi ṣeṣe.

Ni ti awọn ti wọn ti ba iṣẹlẹ naa lọ, ajọ yii sọ pe oku eeyan mọkanlelogun (21) ni awọn gbe jade.

Ṣugbọn iroyin to gbode bayii ni pe o ti le ni oku ọgọrun-un (100) ti wọn gbe jade latari ijamba naa.

Ninu ọrọ olori agbegbe Mokwa, Muhammad Shaba Aliyu, o ni o ti le ni ọgọta ọdun (60), ti iru iṣẹlẹ bayii ti waye gbẹyin.

O rọ ijọba lati ran wọn lọwọ ni gbogbo ọna.

Iṣẹ idoola ẹmi ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ yii, a o maa mu iroyin wa bo ba ṣe n lọ.