Kí nídìí táwọn obìnrin kan fi máa ń jẹ olubi ọmọ lẹ́yìn ìbímọ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Tibi tire la wá sílé ayé, kò sí ọmọ tí wọ́n bí láyé tí olubi rẹ̀ kìí tẹ̀le wáyé.
Olubi ọmọ ló ń fún ọmọ lẹ́mìí nígbà tó bá níní oyún, tó sì jẹ́ pé ní kété tí ọmọ bá ti dáyé ni olubi ti parí iṣẹ́ tirẹ̀, tó di ohun tí wọ́n máa ń gbé jù nì sí ààtàn.
Àmọ́ àwọn kan kò rí olubi ọmọ bí ohun tó yẹ kí èèyàn sọnù, tó sì jẹ́ pé dípò kí wọ́n sọ olubi ọmọ náà nù níṣe ni wọ́n máa ń fún ìyá ọmọ náà jẹ.
Mo mọ̀ pé ìbéèrè tó wà lọ́kàn yín ni pé kí ló le mú èèyàn jẹ olubi ọmọ?
Àwọn kan gbàgbọ́ pé àwọn èròjà aṣaralóore wà nínú olubi ọmọ èyí tí ọmọ ń gbà lára ìyá rẹ̀ nínú oyún àti pé kò yẹ káwọn èròjà náà ṣòfò lẹ́yìn tí ọmọ bá dáyé tán.
Wọ́n gbàgbọ́ pé olubi ọmọ le pèsè àwọn èròjà tí yóò mú ìyá ọmọ ìkóókó bọ̀ sípò padà lẹ́yìn tó bímọ tán àti bí yóò ṣe máa fún ọmọ lọ́yàn.
Àwọn obìnrin kan máa ń lọ olubi ọmọ yìí mọ́ àwọn èso míì tí wọ́n sì máa gbe mu lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí wọ́n bá bímọ tán nígbà àwọn míì sì máa ń sa kó gbẹ kí wọ́n tó máa lò ó bíi oògùn.
Ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn yìí ni pé olubi ọmọ náà yóò fún ìyá ọmọ ní okun, yóò mú kí ọyàn ìyá ọmọ tuntun náà máa sẹ̀ dáadáa, tó sì máa ń dènà àwọn àìsàn tó máa ń ṣúyọ lẹ́yìn ìbímọ.
Charlie Poulter from Reading, Berkshire, England, gbàgbọ́ pé bíbu ẹ̀kún ọwọ́ olubi ọmọ sínú èso red berries àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ máa ń fún òun lókun lẹ́yìn tí òun bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ tán.
"Mi ò kí ń fẹ́ rò ó rárá, mó máa ń sáré mu-ún ni," ó sọ.
"Mo máa ń rò ó pé tí mímu olubi ọmọ yìí bá máa fún mi lókun, tí kò ní jẹ́ kí n ṣe àárẹ̀ lẹ́yìn ìbímọ, kó sì ohum tó burú níbẹ̀."
Ó ní òun gba ìtọ́jú fún ìrẹ̀wẹ̀sí ọkàn fún ọ̀sẹ̀ méjìdínlógún nígbà tí òun wà nínú oyún, tí òun sì ti ń bẹ̀rù pé ó ṣeéṣe kí òun tún kojú ìṣòro bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí òun bá bímó tán.
Ó sọ pé òun kò gbọ́ nípa sísọ olubi ọmọ di oògùn rí tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n tí wọ́n sọ fún òun pé ó le ṣe ìrànwọ́ láti dènà àárẹ̀ tó le wáyé lẹ́yìn ìbímọ.
"Mo ti mú ọkàn mi le láti gbìyànjú ohunkóhun, tí ọkọ náà sì sọ pé kò ní ṣe ìpalára kankan fún mi."
Ó sọ pé òun kò rí ìṣòro kankan lẹ́yìn ìbímọ tó sì gbàgbọ́ pé olubi ọmọ tí òun lò ló ṣe ìrànwọ́ fún òun.
Àwọn èèyàn tó máa ń jẹ olubi ọmọ kò pọ̀ tó bẹ́ẹ̀.
Yàtọ̀ sáwọn ẹranko inú omi, àtàwọn ẹranko tó ń gbé ilé, ọ̀pọ̀ àwọn ẹranko ló máa ń jẹ olubi ọmọ wọn lẹ́yìn tí wọ́n bá bímọ tán.
Wọ́n máa ń lo olubi ọmọ tó ti gbẹ fáwọn oògùn kan ní ilẹ̀ China, tí wọ́n sì gbàgbọ́ pé ó máa ń ṣiṣẹ́ gidi àmọ́ ni ìhà ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ òkèèrè ni àṣà jíjẹ olubi ọmọ ti wọ́pọ̀, tó sì máa ń mú awuyewuye dání.
Ṣé jíjẹ olubi ọmọ ní àǹfàní kankan fún ara?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kò sí ẹ̀rí kankan lẹ́ka ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé jíjẹ olubi ọmọ le dènà àwọn àìsàn lẹ́yìn ìbímọ tàbí fún ìyá ọmọ lókun gẹ́gẹ́ bí ìwádìí ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan ṣe sọ.
Ọ̀rọ̀ táwọn kan máa ń sọ pé olubi ọmọ ní àwọn èròjà vitamin kan tó dára fún ìlera obìnrin ti ń mú àlékún bá àṣà jíjẹ olubi ọmọ.
Ìwádìí ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Northwestern University sọ pé àwọn kò ṣàwárí àǹfàní kankan nínú jíjẹ olubi ọmọ.
Ilé ẹ̀kọ́ Royal College of Midwives ní ọwọ́ obìnrin ló wà tó bá ù wọ́n láti máa jẹ olubi ọmọ.
Àwọn olùwádìí náà sọ pé àṣà jíjẹ olubi ọmọ ti ń gbilẹ̀, tí èyí sì ń rí bẹ́ẹ̀ látàrí báwọn èèyàn ṣe ń sọ lórí ayélujára.
Ìwádìí wọn tí wọ́n gbé síta lórí ìkànni Archives of Women's Mental Health ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìwádìí mẹ́wàá tí àwọn kan tí gbé jáde lórí jíjẹ olubi ọmọ.
Ṣùgbọ́n kò sí ẹ̀rí tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú àwọn ìwádìí náà pé jíjẹ olubi ọmọ yálà ní tútù, sísè tàbí ṣísọ ọ́ di oògùn ní àǹfàní kankan fún ìlera.
Bákan náà ni wọ́n ní àwọn ìwádìí náà kò ṣàyẹ̀wò àwọn ewu tó wà nínú jíjẹ olubi.
Olubi ọmọ jẹ́ ẹ̀yà tó máa ń dá ààbò bo ọmọ nínú oyún lọ́wọ́ àwọn nǹkan tí kò dára, tó le ṣàkóbá fún ọmọ.
Àwọn olùwádìí náà ní ó ṣeéṣe káwọn kòkòrò àìfojúrí bíi virus àti bacteria ṣì wà lára olubi náà lẹ́yìn ìbímọ.
Ẹni tó ṣáájú ìwádìí náà, Cynthia Coyle, tó jẹ́ onímọ̀ nípa ọpọlọ sọ ní Northwestern University sọ pé àwọn obìnrin tó ń jẹ olubi ọmọ ni wọn kò ṣe ìwádìí lórí ewu tó wà fún wọn àtàwọn ọmọ wọn nínú ohun tí wọ́n ń jẹ.
Ó ní kò sí ààtò lórí bí wọ́n ṣe ń pèsè olubi ọmọ náà àti iye tí wọ́n le lò.
"Àwọn obìnrin kò mọ ohun tí wọ́n ń dà sínú ara wọn."
Louise Silverton tí ilé ẹ̀kọ́ Royal College of Midwives sọ pé kò sí ẹ̀rí tó bẹ́ẹ̀ láti fi gba àwọn obìnrin lámọ̀ràn lórí jíjẹ olubi ọmọ.
"Ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun tó wu obìnrin tó bá fẹ́ jẹ ẹ́.
"Àwọn obìnrin gbọdọ̀ mọ́, gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ yòókù, pé olubi ọmọ náà le gbòdì lára wọn, wọ́n nílò láti ṣọ̀ra nígbà tí wọ́n bá ń pèsè rẹ̀."
Ó fi kun pé obìnrin tó bá fẹ́ jẹ olubi ọmọ rẹ̀ nílò láti bá àwọn dókítà sọ̀rọ̀ kí wọ́n tó gbẹ̀bí ọmọ rẹ̀ lój;unà àti lè ṣàmójútó olubi ọmọ náà dáadáa.
Dókítà Daghni Rajasingam tó jẹ́ onímọ̀ nípa ẹ̀yà ara ìbímọ obìnrin sọ pé olubi ọmọ ní ẹ̀jẹ̀ tó pọ̀ dáadáa, àwọn ewu tó rọ̀ mọ́ jíjẹ rẹ̀ pọ̀ púpọ̀.
"Ohun tó bá wu àwọn obìnrin ni wọ́n le fi olubi ọmọ wọn ṣe àmọ́ mi ò gbà wọ́n lámọ̀ràn láti jẹ́."















