Wo ààrùn márùn-ún tí èèyàn le kó látara ìbálòpọ̀ àti ìtọ́jú wọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Abdalla Seif Dzungu
- Role, BBC Swahili
- Reporting from, Nairobi Kenya
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń rí sí ètò ìlera ní àgbáyé, World Health Organization, WHO ṣe sọ, àwọn ààrùn tí èèyàn ń kó látara ìbálòpọ̀ wà lára àwọn ìpèníjà tí ètò ìlera ń kojú káàkiri àgbáyé.
WHO ní ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àwọn ààrùn tó ṣe é tọ́jú láwọn èèyàn ń kó látara ìbálòpọ̀ lójoojúmọ́.
Àwọn ààrùn yìí, èyí tó máa ń wáyé nípa ìbálòpọ̀ tó fi mọ́ ojú ara obìnrin, ojú ìdí tàbí ìbálòpọ̀ láti ẹnu le fa ìpèníjà ìlera tó lágbára.
Èyí ni àwọn ààrùn tó lágbára márùn-ún tí èèyàn le kó látara ìbálòpọ̀ àti bí èèyàn ṣe le tọ́jú wọn.
Ìkìlọ̀: Ìròyìn jẹ́ láti fi ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lásán ni. Kàn sí dókítà tí o bá ń rí àmì àpẹẹrẹ kankan.
1. HIV/AIDS
AIDS jẹ́ ààrùn tó lágbára tó máa ń bá àwọn ẹ̀yà ara fínra. HIV ló máa ń fa AIDS.
Gẹ́gẹ́ bí WHO ṣe sọ, HIV máa ń ba kojú ìjà sáwọn ẹ̀yà ara tó máa ń mú ara jí pépé tí èèyàn bá ti ni, tó sì máa ń mu ṣòro fáwọn ẹ̀yà tó máa ń kojú àìsàn láti lè ṣe iṣẹ́ wọn.
Èèyàn le kó HIV látara ẹ̀jẹ̀, àtọ̀ tàbí tí omi ara ẹni tó bá ni bá kan èèyàn nínú ara. Kò ì tíì sí òògùn láti tọ́jú ààrùn HIV/AIDS àmọ́ àwọn oògùn wà láti ṣàmójútó àwọn àìlera àti àìsàn tí ààrùn náà máa ń fa sí ara.
Láàárín ọ̀sẹ̀ méjì sí mẹ́rin ni ẹni tó bá kó ààrùn HIV lé máa rí àwọn àìlera bí ikọ́, kàtá, ara gbígbọ́nà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn tó bá ń lo òògùn láti fi ṣàmójútó àwọn àìlera HIV le má ní àmì àpẹẹrẹ kankan fún ọ̀pọ̀ ọdún.
Kòkòrò àìfojúrí virus ló máa ń fa HIV tò sì máa ń yára pọ̀ si lára.
Tí kò bá sí ìtọ́jú fún ẹni tó ní HIV láàárín ọdún mẹ́jọ sí mẹ́wàá ló máa ń di AIDS.
Ìtọ́jú
Ààrùn HIV/AIDS kò gbọ́ òògùn, kò ì tíì sí ìtọ́jú fún-un àmọ́ ẹni tó bá ni ààrùn yìí le máa lo àwọn òògùn tí kò ní jẹ́ kí ààrùn náà pọ̀ si lára. Pẹ̀lú lílo àwọn òògùn náà, HIV kò ní lágbára láti di AIDS.
2. Hepatitis B àti C
Hepatitis B àti C jẹ́ ààrùn tí kòkòrò àìfojúrí virus máa ń fà, tó sì máa ń mú kí ẹ̀dọ̀ èèyàn wú. Látara ẹ̀jẹ̀ ni ó ti máa ń ràn àmọ́ èèyàn tún le kó hepatitis B látara omi ara bíi àtọ̀.
Àwọn ààrùn méjéèjì yìí le fa àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ tàbí ọlọ́jọ́ kúkurú. Tí hepatitis B àti C bá lágbára, wọ́n le fa ìṣòro ńlá fún ẹ̀dọ̀ tó sì lè bí àìsàn cirrhosis àti jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀.
Èèyàn le kó hepatitis B àti C látara ìyá sí ọmọ lásìkò ìbímọ, nípa ìbálòpọ̀ tàbí lílo abẹ tí ẹni tó ní àìsàn náà bá ti lò.
Ìtọ́jú
Kò ì tíì sí ìtọ́jú fún hepatitis B ṣùgbọ́n àwọn òògùn wà láti dènà bí ipa rẹ̀ ṣe le le tó lára àti láti mú àdínkù bá bó ṣe le bá ẹ̀dọ̀ jẹ́ sí.
Abẹ́rẹ́ àjẹsára wà láti dènà níní ààrùn hepatitis B.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
3. Herpes (Ìṣìrun)
Herpes simplex virus (HSV) jẹ́ ààrùn tí kòkòrò àìfojúrí virus máa ń fà èyí tó máa ń dá egbò sí ojú ara tàbí ẹnu.
Ó jẹ́ ààrùn tó wọ́pọ̀, tó sì máa ń mú ìnira dání. Láti ara sí ara ni ààrùn náà fi máa ń tàn.
Oríṣìí ìṣìrun méjì ló wà. Àkọ́kọ́ ni HSV-1, èyí tó máa ń múni lẹ́nu. Òhun máa ń ran èèyàn láti ara itọ́. Bákan náà ni o le fa ìṣìrun ojú ara. Ọ̀pọ̀ àgbàlagbà ló máa ń ní ìṣìrun.
Ìkejì ni HSV-2 èyí tí èèyàn máa ń kó látara ìbálòpọ̀ tó sì máa ń dá egbò sí ojú ara.
Ìtọ́jú
Gẹ́gẹ́ bí WHO ṣe sọ, òògùn wà tí wọ́n fi máa ń tọ́jú àwọn àìlera ìṣìrun.
Àwọn òògùn yìí yóò mú àdínkù bá iye ọjọ́ tí ààrùn náà le lò lára àwọn ìnira tí ààrùn náà le fà fún ara àmọ́ kò lè tán kòkòrò náà.
Ó dára láti bẹ̀rẹ̀ sí ní lo òògùn rẹ̀ láàárín ọjọ́ méjì tí ààrùn náà bá dé sára.
Lára àwọn òògùn tí wọ́n fi máa ń kojú rẹ̀ ni acyclovir, famciclovir, àti valacyclovir.
Àwọn òògùn tí ẹni tó bá ní ọgbẹ́ inú tẹ́lẹ̀ le lò ni paracetamol (acetaminophen), naproxen, tàbí ibuprofen. Àwọn oògun tí wọ́n le fi máa pa ojú egbò náà benzocaine àti lidocaine.
4. Syphilis
Syphilis jẹ́ ààrùn tí kòkòrò àìfojúrí bacteria máa ń fà. Ó máa ń fa egbò sí ojú ara tàbí ẹnu, tó sì lè tàn dé àwọn ẹ̀yà ara tó kù tí wọn kò bá tètè tọ́jú rẹ̀.
Ààrùn syphilis ṣe é dènà, tó sì tún ní ìtọ́jú pẹ̀lú ṣùgbọ́n tí wọn kò bá tọ́jú rẹ̀, ó lè fa àìlera tó lágbára.
Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ní syphilis ni wọ́n kìí ní àpẹẹrẹ kankan tàbí kí wọ́n má mọ àwọn àmì àpẹẹrẹ rẹ̀.
Tí obìnrin bá ní syphilis nínú oyún le fa àbíkú, ikú ọmọ ọwọ́ tàbí kí ọmọ náà ní syphilis tí wọ́n bá bi tán.
Lílo rọ́bà ìdáàbòbò lásìkò ìbálòpọ̀ le dènà syphilis.
Ṣíṣe àyẹ̀wò le ṣàfihàn syphilis láàárín ìṣẹ́jú péréte èyí tó le mú ìtọ́jú rẹ̀ yá ní kíákíá.
Ìtọ́jú
Syphilis ṣe é tọ́jú. Àwọn tó bá ní syphilis nílò láti kàn sí ilé ìwòsàn.
Tí syphilis kò bá tíì wọ ara púpọ̀ jù, wọ́n le fi abẹ́rẹ́ benzathine penicillin (BPG) tọ́jú rẹ̀.
Abẹ́rẹ́ benzathine penicillin (BPG) ni ìtọ́jú àkọ́kọ́ syphilis, òhun sì ni WHO buwọ́lu láti fi máa tọ́jú olóyún tó bá ní syphilis.
Fún syphilis tó bá ti wọra, àwọn dókítà le kọ oògùn bíi doxycycline, ceftriaxone tàbí azithromycin, tí wọ́n jẹ́ òògùn láti kojú àwọn bacteria.
Bákan náà ni wọ́n tún le fi abẹ́rẹ́ BPG tọ́jú syphilis tó bá ti wọra, iye tí wọ́n máa fún èèyàn kàn máa pọ̀ jù tí ẹni tí kò ì tíì wọra ni.
Abẹ́rẹ́ tún le dènà kí ìyá tó bá lóyún láti kó ààrùn náà ran ọmọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
5. Chlamydia
Chlamydia jẹ́ ààrùn tó máa ń rà látara ìbálòpọ̀ èyí kòkòrò àìfojúrí bacteria Chlamydia trachomatis máa ń fà.
Ó jẹ́ ààrùn tó wọ́pọ̀ tí wọ́n le fi "antibiotics" wò àmọ́ tí wọn kò bá tọ́jú rẹ̀, ó le fa àìlera tó lágbára pàápàá fún obìnrin.
Látara omi ara ni bíi àtọ̀ obìnrin àti ọkùnrin ni chlamydia fi máa ń tàn. Chlamydia kìí sábà ní àpẹẹrẹ kan lọ títí àmọ́ àwọn ara àmì àpẹẹrẹ tó máa ń ní nígbà míì ni kí nǹkan máa jáde lójú ara obìnrin, kí èèyàn máa rí ìnira tó bá fẹ́ tọ̀ tàbí kí ìsàlẹ̀ ikùn máa dun èèyàn tàbí kórópọ̀n.
Ìtọ́jú
Gẹ́gẹ́ bí WHO ṣe sọ, Chlamydia ní ìwòsàn.
Chlamydia tí kò lágbára ṣe é wòsàn pẹ̀lú àwọn òògùn doxycycline tàbí azithromycin.
Ó le tún èèyàn tí ẹni tí èèyàn bá ń bá ní ìbálòpọ̀ kò bá tọ́jú ara.
Àwọn ọmọdé tí wọ́n bá ní chlamydial ti ojú, wọ́n le ṣe ìtọ́jú rẹ̀ pẹ̀lú òògùn azithromycin.
Ó dára fún ẹni tó bá ń tọ́jú chlamydia láti dúró fún ọjọ́ méje kí wọ́n tó ní ìbálòpọ̀ àma tí wọn kò bá lè mára dúró, ó dára láti lo rọ́bà ìdáàbòbò.
WHO ni orísun gbogbo tó wà nínú àkọ́ọ́lẹ̀ yìí.















