'Mo ṣiṣẹ́ abẹ, wọ́n tún pàárọ̀ itan mi nítorí àìsàn ikọ́-ife inú egungun tó mú mi'

Àkọlé fídíò, Ajibola Bamgbose
'Mo ṣiṣẹ́ abẹ, wọ́n tún pàárọ̀ itan mi nítorí àìsàn ikọ́-ife inú egungun tó mú mi'

Bi ikọ-ife ti a mọ si Tuberculosis ṣe gbajumọ to, ọpọ eeyan ni ko mọ pe o tun maa n ṣe eeyan ninu egungun pẹlu.

Lodi si ikọ hihu to maa n mu eeyan gbẹ ti a mọ ikọ-ife fun, ti inu egungun naa wa pẹlu iṣoro tirẹ.

Ọmọbinrin kan, Ajibola Bamgbose, naa ko mọ pe aisan tuberculosis inu egungun wa pẹlu, afi nigba to kọlu itan rẹ, to si pada sọ ọ di ẹni to n fi irin rin.

Gẹgẹ bi Ajibola, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ṣe ṣalaye fun BBC, o ni, ọmọ ọdun mẹfa ni oun wa ti mama oun fi fura pe, oun o ki n le dide lori ibusun, ẹsẹ ti kinni ọhun si kọlu maa n gbona gan-an, to si tun maa n tiro to ba n rin.

"Wọn gbe mi lọ si ile iwosan, wọn ni ko si nnkan to ṣe mi.

A ṣaa n ba a lọ bẹẹ titi ti mo fi pe ọdun mẹrinla ti a lọ si ileewosan mii.

"Wọn ni ki n lọọ ṣe ayẹwo miran, nibẹ ni wọn ti sọ fun mi pe mo ni tuberculosis inu egungun. (Tuberculosis of the bone).

"Mi o gbọ ohun to jọ bẹẹ ri laye mi. Nigba ti wọn sọ fun mi pe mo maa lo oogun fun oṣu mejidinlogun, ẹru ba mi, nitori ọmọ kekere ni mi.

Kokoro aarun naa ti tan de inu ẹya ara to pọ lara Ajibola, eyi to mu ko tun ṣe iṣẹ abẹ miran.

'Wọn yọ itan mi kuro, wọn gbe atọwọda si i'

Ajibola Bamgbose
Àkọlé àwòrán, Aworan Ajibola Bamgbose

Nigba to n tẹsiwaju ninu alaye rẹ, Ajibola sọ pe awọn dokita ni lati yọ itan ti tuberculosis fọwọ ba kuro, wọn si gbe itan atọwọda si i.

''Ẹsẹ atọwọda naa ni ẹsẹ osi mi bayii.

''Ko rọrun rara, inira to pọ ni mo n koju lorii rẹ. Mi o le dide, igba mii, ma a ṣubu nile ẹkọ, mo maa n ṣubu nita gbangba tawọn eeyan pọ si .

''Ohun to n ṣe mi ko ye awọn eeyan, nitori ko sẹni to ri mi to le mọ pe nnkan kan n ṣe mi.

Aisan tuberculosis inu egungun yii maa n gba ọna ọtọọtọ farahan lara awọn ẹni to ba mu, ero ọpọ eeyan ni pe ikọ hihu nikan lo maa n ba de.

''Ni temi, mi o hukọ kankan latigba ti mo ti wa lọmọ ọdun mẹfa, koda titi di ọdun mẹrinla, mi o hukọ kankan ti mo fi bẹrẹ itọju.

''Fun idi eyi, tuberculosis inu egungun ki i ṣe ikọ hihu rara.

''Amọran mi fun awọn obi nipa iru nnkan bayii ni pe ki wọn maa ni akiyesi daadaa.''

Bẹẹ ni Ajibola Bamgbose to ti kẹkọọ gboye nipa ipẹtu saawọ, Conflict Resolution, ṣalaye.

O si ti n fi ohun to ṣẹlẹ si i naa la ọpọ eeyan lọyẹ nipa tuberculosis inu egungun.

Ko ṣai sọ pe awọn kan maa n fi oun ṣe yẹyẹ, ṣugbọn iyẹn ko ṣee jokoo ti, ariwo ọja lasan ni bo ṣe sọ.

Kí ni ikọ-ife inú egungun gan?

Ikọ-ife inu egungun ni awọn dokita tun maa n pe ni 'Skeletal tuberculosis tabi Pott's disease, nigba to ba kan egungun ogooro ẹ̀yìn.

Gẹgẹ bi ikọ-ife ti gbogbo eeyan mọ, ti inu egungun yii naa maa n ràn lati inu ẹdọforo lọ sinu egungun ni.

Bakan naa lo jẹ pe kokoro to n fa ikọ-ife ẹdọforo naa lo n fa ti inu egungun ti a n sọ yii.

Bo tilẹ jẹ pe ikọ-ife inu egungun ko wọpọ bii ti ẹdọforo to gbajumọ, aisan to ṣoro pupọ loun naa.

O le ba egungun eeyan jẹ, o si le fa aisan fun ogooro ẹyin, o si le de ibi ọpọlọ pẹlu.

Awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa ikọ-ife inu egungun

O le ran lati ẹdọforo de inu egungun, o si le gba inu ẹjẹ wọle.

Awọn ẹya ara to n ru ẹru ara bii ẹsẹ, lo maa n saba kọlu.

Apẹẹrẹ to le mu wa

Awọn apẹẹrẹ naa yoo bẹrẹ diẹdiẹ, o le bẹrẹ pẹlu ara riro, ara wiwu, ki apa ibẹ ma ṣiṣẹ mọ, egungun naa le yipada, ko ma ri bo ṣe yẹ ko ri mọ.