Àlàyé rèé lórí ìbáṣepọ̀ tó wà láàrin ọpọlọ àti ikùn ẹ̀dá

obinrin to n jẹun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Andre Biernath
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọpọlọpọ iṣan ati ẹya ara mii lo wa ninu ikun wa eyii to n mu ki a gbe igbeaye irọrun.

Laipẹ yii ni iwadii kan fi han pe ẹgbẹgbẹrun awọn kokoro aifojuri lo n gbe ninu ikun wa, eyii to n ṣe wa lanfaani.

Eyii n ṣafihan ibaṣepọ to wa laarin ikun ati ọpọlọpọ wa, eredi ree to jẹ pe nigba mi ti nnkan ba fẹ ṣẹlẹ a maa n mọ ninu wa pe nnkan fẹ ṣẹlẹ bo tilẹ jẹ a ko le ṣalaye bi a ṣe mọ.

Amọ bawo ni ibaṣepọ inu ati ọpọlọ wa ṣe n waye, ati pe njẹ o ṣeeṣe fun wa lati mu ki ibaṣepọ naa dan mọran ju bo ṣe wa lọ?

Ibaṣepọ ikun ati ọpọlọ

Ọmọwe Saliha Mahmood Ahmed ni ajọ Bowel Research UK ṣalaye pe oniruru ọna ni ẹya ara meji naa fi so pọ.

Akọkọ ni eyii ti wọn pe ni "vagus nerve" to so ọpọlọ pọ mọ oniruru ẹya ara mii bii ọkan ati ifun.

Ekeji ni bi ọpọlọ ati ikun ṣe n ba ara wọn sọrọ pẹlu eroja ti wọn n pe ni "ghrelin" ati "GLP-1" to n gbe iroyin kaakiri inu agọ ara.

Ikẹta ni eroja ara to n gbogun ti aisan ninu ara wa.

Ọmọwe naa sọ pe ọpọ eeyan ni ko mọ pe oniruru ẹya ara lo n ni ibasẹpọ pẹlu ọpọlọ ẹda.

Onimọ nipa "gastroenterology" nile iwosan Mayo, nilẹ Amẹrika, Pankaj J Pasricha, ṣalaye pe ibaṣepọ naa ma n waye latari bi ọpọlọ ṣe nilo ọpọ agbara lati ṣiṣẹ, to si jẹ inu ikun wa ni ọpọlọpọ agbara to nilo naa n gbe.

Pasricha jẹ ko di mimọ ida meji pere ni ọpọlọ koninu gbogbo ẹru to wa ni agọ ara wa amọ ọpọlọ naa n lo ida ogun agbara to n jade ninu gọ ara wa.

Amọ ṣa, ẹya ara mejeji ọhun - ọpọlọ ati ikun ni wọn jọ n ṣe anfani fun ara wọn.

Fun apẹrẹ, ti eeyan ba yofẹ ẹnikan, inu rẹ yoo maa dun ni ọna ti ko ni le fẹnusọ, ara ibaṣepọ to wa laarin ikun ati ọpọlọ ti a n gbiyanju lati ṣalaye ree.

Ile itaja igbalode ni India

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ile aye miran ninu ikun ẹda

Nnkan bii tiriliọnu mẹwaa si ọgọrun un tiriliọnu kokoro aifojuri lo n gbe ninu ikun ọmọ eeyan.

Iye awon kokoro naa ju gbogbo iye ẹya inu agọ ara lọ.

Awọn onimọ ṣalaye pe awọn kokoro naa maa n jẹ lara ounjẹ ti a n jẹ, wọn si maa n ṣe iranwọ fun wa lati jẹ ki awọn ohun ti a n jẹ gba ibi ire.

Ahmed sọ pe imọ ẹrọ ti jẹ ko rọrun fun awọn onimọ lati mọ iye kokoro inu agọ ara ni pato ati ipa ti wọn n ko lori aisan ninu agọ ara.

Awọn iwadii kan ti fi han pe awọn kokoro mii lo n ṣokunfa awọn arun bii ara sisan ju, aisan ọkan ati arun jẹjẹrẹ.

Obirin to duro nile itaja igbalode

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn onimọ sọ pe awọn kokoro aifojuri to n ṣe ara loore wa ninu awọn ounjẹ kan ti a n jẹ

Kokoro aifojuri to n ṣe ara loore

Ahmed sọ pe o le ṣoro lati ṣalaye ni pato ibaṣepọ ikun ati ọpọlọ latari pe irufẹ kokoro to wa ninu onikaluku yatọ sira wọn.

O ni "Irufẹ kokoro inu onikaluku kii ṣe ọkan naa, ọtọtọ ni ẹda wa nile aye."

Wayi o, awọn onimọ naa ti sọ pe jijẹ awọn ounjẹ aṣaraloore loorekoore yoo ran ikun ati agọ ara wa lọwọ.

Obinrin to n bu ounjẹ inu igo sinu abọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn onimọ sọ pe eso ati ẹfọ dara fun agọ ara

Wọn ni awọn ounjẹ kan to ni awọn eroja aṣaraloore ti wọn n pe ni "probiotics" yoo jẹ ki ounjẹ tete maa gba ibi ire ninu ikun ẹni.

Lara irufẹ ounjẹ bẹẹ ni ẹfọ ati atawọn eso wa.

Ahmed sọ pe agọ ara awọn to n jẹ onururu ewe ati eso wa ni alaafia ju ti awọn ti ko jẹ irufẹ nnkan bẹẹ lọ.