Wọ́n sọ iná sí ibùdó epo ní Port Sudan, aráàlú ń kérora

Eefin ṣi n ru tuu nibudo epo ti wọn kọlu lọsẹ to lọ

Oríṣun àwòrán, AFP/ Getty images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Lẹyin ikọlu to waye ni Port Sudan, iṣoro ai si omi ati ina ti bẹ silẹ niluu naa, owo gọbọi ni wọn fi n ra omi bi wọn ba tilẹ ri.

Ilu ti a mọ si Red Sea, ni Port Sudan, jẹ aaye isadi fun awọn eeyan tẹlẹ, wọn n sa sibẹ nitori ogun to n waye ni Sudan.

Ṣugbọn fun odidi ọsẹ kan sẹyin ni ikọlu fi kan Port Sudan naa, ikọ ologun RSF ti wọn ti n fẹsun kan tẹlẹ naa lo si wa nidii ikọlu ọhun bi wọn ṣe wi.

Ọjọ kẹfa lẹyin ti wọn lo drone kọlu wọn, eefin ina ṣi n ru jade lati ibudo epo mẹta ti wọn sọna si.

Niṣe ni ikọ alaabo duro wamu sibẹ, ṣugbọn wọn ko ti i ri ina naa pa.

Idaamu naa ti mu ina ọba ku, bẹẹ ni awọn eeyan ko ri omi lo mọ.

Mutasim, ọkan ninu awọn olugbe ibẹ, sọ fun BBC pe '2,000 pounds' owo Sudan($3.30; £2.50) loun fi ra omi loṣẹ kan sẹyin.

O ni ilọpo marun-un rẹ loun n san bayii lati ra iye om ikan naa.

Mutasim ati awọn ẹbi rẹ meje ko ri omi dana, wẹ debi ti wọn yoo ri fi tun ile ṣe.

Omi nìkan kọ́ ni ìṣòro tó ń kojú wọn ní Port Sudan

Awon eeyan maa n ṣe faaji alẹ tẹlẹ ni Port Sudan, ki ikọlu too de. Ko sohun to jọ bẹẹ mọ latigba ti wọn ti koju iṣoro ogun bayii.

Oríṣun àwòrán, Bloomberg/ Getty images

Àkọlé àwòrán, Awon eeyan maa n ṣe faaji alẹ tẹlẹ ni Port Sudan, ki ikọlu too de. Ko sohun to jọ bẹẹ mọ latigba ti wọn ti koju iṣoro ogun bayii.e

Bo tilẹ jẹ pe nnkan ti n pada bọ sipo, ti wọn ti n ṣi awọn ile itaja pada, epo rọbi ko ti i si ni Port Sudan.

Ọpọlọpọ ọkọ lo n to kaakiri awọn ileepo lati ri epo ra.

"O fẹrẹ le gba mi to wakati marun-un ki n too ri epo ra. Awọn eeyan ti n koju iru nnkan bayii tipẹ ni Sudan, ṣugbọn ko kan wa ri."

Mutasim lo sọ bẹẹ.

"Nnkan bii ọdun meji sẹyin la ko wa sibi lati Omdurman," Mutasim tẹsiwaju bẹẹ nipa Port Sudan, ilu kan to wa lodi keji ọdo Nile.

Gbogbo ohun ti wọn ni, ni wọn ko jọ lati kọ agbegbe naa. Owo naa jẹ $3,000 (£2,250).

"Awọn RSF lo le wa jade nilee wa, nnkan itura lo jẹ fun wa lati wa sibi. Ṣugbọn a ti n ronu lati kuro nibi naa bayii, nitori ẹmi wa o dè mọ.

Bi nnkan ṣe n wọn si i ni aabo ko tun si mọ, nibo la si fẹẹ lọ.?"

Ni bayii, o ti pe ọsẹ meji ti ina ko ti si ni Port Sudan, ikọlu naa lo si mu ko buru si i.

'Mi ò mọbi tí mo fẹ́ẹ́ lọ mọ́ bí nǹkan bá burú sí i ní Port Sudan'

Hawa Mustafa

Iṣẹ olukọ ni Hawa Mustafa n ṣe ni el-Geneina, Darfur, ko too sa fun ogun to si wa n gbe ni Port Sudan.

Ibudo awọn alaini ni obinrin naa n gbe pẹlu awọn ọmọ rẹ mẹrin, o si ti le lọdun meji ti wọn ti n gbe nibẹ lai si baba wọn .

Ṣugbọn ikọlu ọsẹ to kọja ti ko ipaya ba iya naa, o ṣalaye fun BBC pe:

"A bẹrẹ si i gbọ iro ikọlu pada, a ti pada si akoko ogun ati ai si aabo

"Mi o mọbi ti mo fẹẹ lọ bi nnkan ba buru ju bayii lọ ni Port Sudan.

"Mo ti lero pe ma a tun sa lọ si ọkan ninu awọn ilu to wa nitosi ni, ṣugbọn o jọ pe iyẹn naa ko le bọ si i mọ bayii."

"Ibi ìsadì kò ṣeé wọ̀ mọ́"

Latigba ti ogun abẹle ti bẹrẹ ni Sudan,Port Sudan yii nikan naa ni ibi ti wọn n gba gbe iranwọ wọle.

Ibẹ ni ibi isadi awọn eeyan ati ikọ to n ri si ọrọ ọmọniyan.

Eyi ri bẹẹ nitori papakọ ofurufu kan ṣoṣo to wa niluu naa, ti wọn fi kalẹ si Port Sudan.

Awọn ajọ bii UN ti lo ibẹ lati gbe ounjẹ ati iranwọ miran wọle daadaa ri.

"Port Sudan ni koko ibi ti a n lo fun iranwọ ọmọniyan"

Leni Kinzli, agbẹnusọ WFP fun Sudan lo sọ bẹẹ.

"Loṣu Kẹta, toonu ounjẹ to fẹrẹ to ẹgbẹrun lọna ogun (20,000) la gbe wọle, o si ju idaji lọ ti a gbe wọle lati Port Sudan."

Ni bayii, ẹkun mẹwaa ni iyan ti bẹrẹ si i mu ni Sudan, mẹtadinlogun lo si wa ninu ewu iyan ati ebi bi WFP ṣe sọ.

Ki ikọlu too de, awọn eeyan maa n kora jọ lalẹ ni Port Sudan lati ṣe faaji, ko siru ẹ mọ bayii.

Tẹ o ba gbagbe, ọdun meji sẹyin ni ogun abẹle bẹ silẹ ni Sudan, ẹgbẹlẹgbẹ eeyan lo ti ku, miliọnu rẹpẹtẹ lo si ti filu silẹ nitori ogun.