Bàbá Mohbad le pe ẹjọ́ tako ìdájọ́ tó tú Naira Marley àti Sam Larry sílẹ̀ - Ilé ẹjọ́

Mohbad

Oríṣun àwòrán, Mohbad

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ile ẹjọ giga kan to wa ni Ikeja, niluu Eko ti sọ pe ọgbẹni Joseph Aloba, baba to bi olorin takasufe to di oloogbe, Mohbad, le pe ẹjọ tako idajọ to ni Naira Marley ko lọwọ ninu iku ọmọ rẹ.

Adajọ Taiwo Olatokun lo paṣẹ naa niluu Eko pe Joseph Aloba le pe ẹjọ tako idajọ to tu afurasi naa silẹ ṣaaju.

Baba Mohbad sọ pe idajọ to tu Naira Marley silẹ lori ipa to ko ninu iku ọmọ oun ko tẹ oun lọrun.

Yatọ si Naira Marley, baba Mohbad tun ni ko ba ofin mu bi wọn ṣe tu Samson Balogun ti ọpọ mọ si Sam Larry, Owoduni Ibrahim ti ọpọ mọ si Prime Boy ati Pere Babatunde silẹ.

Lẹyin ti ile ẹjọ naa gbọ awijare agbẹjọro ọgbẹni Aloba, iyẹn Wahab Shittu, SAN, o ni ọkunrin naa le pe ẹjọ tako itusilẹ awọn afurasi ọhun.

Ile ẹjọ ti wa sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2025 yii.

Ninu iwe to wa niwaju ile ẹjọ, baba Mohbad sọ pe igbẹjọ to tu awọn eeyan naa silẹ ko fun gbogbo awọn ti ọrọ naa kan lanfani lati wa sọ tẹnu wọn.

O fi kun pe itusilẹ awọn afurasi ọhun tako esi ayẹwo oku ọmọ oun ti wọn ṣi n reti.

Ninu alaye rẹ, o ni gbogbo awọn to le tan imọlẹ si irufẹ iku to pa ọmọ oun ni pato ni wọn ti tu silẹ.

Ọkunrin naa ti wa ṣleri pe oun ko ni sinmi ayafi ti aṣiri gbogbo awọn to lọwọ ninu iku ọmọ oun ba tu ti wọn si jẹ iya to tọ labẹ ofin.

Ọjọ kejila, oṣu Kẹsan an, ọdun 2023 ni Mohbad jade laye.

Baba rẹ kọkọ sin oku rẹ amọ wọn wu oku naa lẹyin ọpọ awuyewuye lori ayelujara ki ọlọpaa to bẹrẹ iwadii.