Kí nídìí tí Póòpù tuntun fi yan Leo XIV gẹ́gẹ́ bí orúkọ oyè rẹ̀ tuntun?

Oríṣun àwòrán, Reuters
- Author, Maria Zaccaro
- Role, BBC World Service
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Wọ́n ti yan Cardinal Robert Prevost gẹ́gẹ́ bíi póòpù tuntun fún ìjọ Àgùdà tí wọ́n yóò sì máa pè é ní Pope Leo XIV.
Òun ni ọmọ Amẹ́ríkà tí yóò kọ́kọ́ di póòpù, tí yóò sì máa ṣáájú àwọn èèyàn ìjọ Àgùdà tí àppapọ̀ wọn jẹ́ 1.4bn káàkiri àgbáyé.
Ní ìlú Chicago ni wọ́n ti bí Póòpù Leo, ẹni ọdún mọ́kàndínláàádọ́rin, tó sì ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ajíyìnrere fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní Peru kó tó di "archbishop" níbẹ̀.
Bákan náà ló ní ìwé ọmọ onílùú Peru, tí wọ́n sì máa ń rántí rẹ̀ fún iṣẹ́ tó ṣe lórí àwọn ìlú tí wọ́n ń yànjẹ àti ṣíṣe ìrànwọ́ pé kò sí àlààfo láàárín àwọn ilé ìjọsìn abẹ́lé.
Kí ló dé táwọn póòpù máa pààrọ orúkọ?
Iṣẹ́ àkọ́kọ́ tí póòpù tuntun máa ń ṣe ni pípàrọ̀ orúkọ tí wọ́n sọ ọ́ sí orúkọ tuntun.
Èyí ti wà fún ọjọ́ pípẹ́ àmọ́ kìí ṣe bẹ́ẹ̀ lórí ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀.
Fún bíi ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́ta ọdún, orúkọ wọn gangan ni àwọn póòpù máa ń lò.
Lẹ́yìn ìgbà náà ni èyí yí padà láti máa fún wọn ní orúkọ àmì lójúnà àti mú kí orúkọ rọrùn láti pè tàbí láti máa jẹ́ orúkọ póòpù tó ti kọjá míì.
Fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn póòpù máa ń mú orúkọ àwọn póòpù tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbésẹ̀ tàbí àwọn tó bá ti gbésẹ̀ fún ìgbà pípẹ́ ní ìbọ̀wọ̀ fún àwọn ará ìṣáájú tàbí láti ṣàmì pé àwọn máa tẹ̀lé ìgbésẹ̀ àwọn irú póòpù bẹ́ẹ̀.
Bí àpẹẹrẹ, Pope Francis ní òun yan orúkọ St Francis láti fi bọ̀wọ̀ fún St Francis ti Assisi àti pé òun ní ìmísí látara ọ̀rẹ́ òun ilẹ̀ Brazil Cardinal Claudio Hummes.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Kí ló dé tí Póòpù tuntun ṣe yan orúkọ Leo XIV?
Póòpù tuntun kò ì tíì sọ ìdí tó fi yan láti máa jẹ́ orúkọ Pope Leo XIV.
Onírúurú ìdí ló le jẹ́ àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn póòpù ló ti máa ń lo Leo láti ọdún pípẹ́ sẹ́yìn.
Ẹni àkọ́kọ́ ni Pope Leo I, tí wọ́n tún máa ń pè ní St Leo the Great, tó jẹ póòpù láàárín ọdún 440 sí 461AD.
Òun ni póòpù karùndínláàádọ́ta, tó sì gbajúmọ̀ fún ìfarjìn rẹ̀ sí ìpè fún àlááfíà káàkiri àgbáyé.
Gẹ́gẹ́ bí ìtàn, bí àwòrán òkú St Peter and Paul lásìkò tí Pope Leo I àti ọba àwọn Huns Attila lọ́dún 452 AD mú kí ọba náà dènà gbígbógunti Italy.
Ta ni Leo XIII?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Póòpù tó lo orúkọ Leo gbẹ̀yìn ni Pope Leo XIII, ọmọ ilẹ̀ Italy tí orúkọ àbísọ rẹ̀ jẹ́ Vincenzo Gioacchino Pecci.
Ní ọdún 1878 ni wọ́n yàn-án gẹ́gẹ́ bíi póòpù 256th tó sì darí ìjọ Àgùdà títí di ìgbà tó jáde láyé lọ́dún 1903.
Ó jẹ́ póòpù tí wọ́n máa ń rántí rẹ̀ fún ìfarajìn rẹ̀ sí ríri pé ìdájọ́ òdodo wà láwùjọ àti àwọn ètò gbogbo.
Bákan náà ni ó gbajúmọ̀ fún lẹ́tà kan tó pín káàkiri tó pe àkọ́lé rẹ̀ ní "Rerum Novarum" – èdè Latin tó túmọ̀ sí "Ohun tuntun".
Àwọn nǹkan tó sọ nínú lẹ́tà náà ni ẹ̀tọ́ àwọn òṣìṣẹ́.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Orúkọ wo ló gbajúmọ̀ jù táwọn póòpù máa ń lò?
Leo wà lára àwọn orúkọ tó gbajúmọ̀ táwọn póòpù máa ń lò.
Orúkọ tí wọ́n ti lò jùlọ ni John, èyí tí Saint John I kọ́kọ́ lò lọ́dún 523.
Ẹni tó lo orúkọ náà kẹ́yìn ni ọmọ ilẹ̀ Italy, Angelo Giuseppe Roncalli tí wọ́n yàn ní Pope John XXIII lọ́dún 1958.
Ọdún 2014 ni Pope Francis pè é ní "Saint".

Oríṣun àwòrán, Reuters















