Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Robert Prevost Leo XIV, Póòpù tuntun fún ìjọ Kátólíìkì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Koda ki wọn to kede orukọ rẹ gẹgẹ bi Poopu tuntun ni awọn ero to wa niwaju ile ijọsinSt. Peter's Basilica ti n pariwo "Kẹmi poopu o gun".
Robert Prevost, ẹni ọdun mọkandinlaadọrin, ni popu ọtalerugba ati meje ti yoo gun ori akeefa ni St Peter, orukọ apejẹ ti wọn si fun un ni, Leo kẹrinla, XIV.
Robert Prevost ni Popu akọkọ lati orilẹede Amẹrika, bi o tilẹ jẹ wi pe ọpọlọpọ eeyan lo tun n fi oju ara ilẹ Larin Amerika wo o nitori ọpọlọpọ ọdun to fi ṣe iṣẹ oniwaasu lorilẹede Peru, ki o to di Biṣọọbu nibẹ.
- "Kí àlááfíà wà pẹ̀lú yín" Pope tuntun, Leo XIV bá àgbáyé sọ̀rọ̀ fún ìgbà àkọ́kọ́
- Àlàyé rèé lórí ìdí tí Póòpù fi máa ń wọ bàtà pupa àti ìdáhùn àwọn ìbéèrè míràn tó rú ọ lójú
- Ìjọ Àgùdà korò ojú sí Trump lórí àwòrán ara à rẹ̀ bíi Póòpù tó gbé síta
- Ètò yíyan Póòpù tuntun ń tẹ̀síwájú bí èéfí dúdú ṣe jáde láti Sistine Chapel
- Báwo ni wọ́n ṣe ń yan Póòpù tuntun?

Ni ọdun 1955 ni wọn bii ni Chicago. Prevost ṣíṣe gẹgẹ bi oṣiṣẹ ori pẹpẹ ki wọn ti ta ororo lee lori si ipo alufaa lọdun 1982. Bi o tilẹ jẹ pe o pada si Peru lẹyin ọdun kẹta, sibẹ kii ye ṣe abẹwo si orilẹede Amẹrika loorekoore lati ṣiṣẹ oluṣọaguntan nibẹ.
Poopu Leo XIV tun ni iwe omo onilu orilẹede Peru lọwọ, bẹẹni wọn ko gbagbe awọn iṣẹ takuntakun ti ṣe fun awọn to ku diẹ kaato fun lawujọ ati mimu alaafia ati iṣọkan wa fun awọn eeyan nibẹ.
Ọdun mẹwaa lo lo gẹgẹbi olusọaguntan agbegbe ati olukọni nilẹekọṣẹ alufaa ni ilu Trujillo lẹkun iwọoorun ariwa orilẹede Peru.








