Ìjọ Àgùdà korò ojú sí Trump lórí àwòrán ara à rẹ̀ bíi Póòpù tó gbé síta

Oríṣun àwòrán, X/White House
- Author, Max Matza
- Role, BBC News
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Ọpọ eeyan lo ti n bu ẹnu atẹ lu Aarẹ orilẹede Amẹrika, Donald Trump paapaa lati ijọ Aguda lẹyin to gbe aworan ara rẹ gẹgẹ bii Poopu, eyi to fi AI pilẹ, sita lori ayelujara.
Aworan naa, to jẹ pe oju opo ile ijọba White House lori ayelujara lo ti jẹyọ lo waye lẹyin ti ọpọ ọmọ ijọ Aguda n ṣe idaro Pope Francis, ẹni to jade laye ni ọjọ Kọkanlelogun, oṣu Kẹrin, ti wọn si n gbaradi lati yan Poopu mii.
Ẹka ijọ Ajuda ni New York fẹsun kan Trump pe o n fi ẹsin igbagbọ ṣe yẹyẹ. Aworan jade lẹyin bi ọjọ meloo sẹyin ti Trump kede pe o wu oun lati di Poopu.
Trump kii ṣe aarẹ akọkọ ti yoo fi igbagbọ ijọ Aguda ṣe yẹyẹ. Aarẹ ana ni Amẹrika, Joe Biden naa da ọpọ wahala silẹ ni bi ọdun diẹ sẹyin ni Tampa niluu Florida.
Agbẹnusọ Vatican, Matteo Bruni kọ lati dahun si ibeere nipa ohun ti Trump ṣe nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lọjọ Ṣatide. Vatican ti bẹrẹ igbaradi lati yan ẹlomiran ti yoo rọpo Pope Francis to di oloogbe.
Aworan ti Trump gbe sita lọjọ Ẹti lo ṣafihan rẹ ninu aṣọ funfun ti awọn Bisọọbu maa n wọ. O gbe agbelebu si ọrun, to si na ika kan soke.
Lẹsẹkẹsẹ ni Ẹka ijọ Aguda niluu New York bu ẹnu atẹ lu aworan naa.
"Ko si nnkan to mu ọpọlọ wa ninu aworan yii, Aarẹ wa.
"A ṣẹṣẹ sin Pope Francis, ti a si fẹ bẹrẹ igbaradi wa lati yan ẹlomiran. Ma fi wa ṣe yẹyẹ."
Olootu ijọba tẹlẹri ni orilẹede Italy, Matteo Renzi naa pẹlu awọn to sọrọ si Trump lori aworan naa.
"Aworan to le fi ṣẹ awọn onigbagbọ ree,"
Ṣugbọn ijọba Amẹrika ti sọrọ sita, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe Aarẹ Trump ko fi ẹnikẹni ṣe yẹyẹ.
"Aarẹ Trump lọ si ilu Italy lati lọ bu ọla fun Pope Francis, o si tun wa nibi eto isinku rẹ", agbẹnusọ ijọba, Karoline Leavitt sọ.
















