Ǹjẹ́ òfin fàyè gba Gómìnà láti fẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ sílẹ̀ darapọ̀ mọ́ òmíràn? Ohun tí a mọ̀ rèé

Aworan Gomina ipinlẹ Delta Sheriff Oborevwori

Oríṣun àwòrán, Delta State Government/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Agbẹjọro agba ni Naijiria, Yomi Aliu (SAN), ti ṣalaye pe awọn gomina naa laṣẹ lati fi ẹgbẹ oṣelu wọn silẹ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu mii to ba wu wọn.

Amofin Aliu sọ fun BBC Yoruba wi pe ofin to mu egungun naa lo mu ẹlẹha, eyi to tumọ si pe bawọn aṣofin ba le kuro ninu ẹgbẹ oṣelu to gbe wọn wọle ibo darapọ mọ ẹgbẹ mii to wu wọn, ko si nnkan to da awọn gomina naa duro lati ṣe bẹẹ.

Ọrọ yii jẹyọ lẹyin ti igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP sọ pe awọn yoo gbe Gomina ipinlẹ Delta, Sheriff Oborevwori, to ṣẹṣẹ darapọ mọ ẹgbẹ osẹlu APC lọ ile ẹjọ.

Ninu ọrọ rẹ, agbẹjọro Aliu (SAN) sọ fun BBC Yoruba wi pe ''ẹgbẹ oṣelu PDP ti daru debi wi pe oludije sipo aarẹ ẹgbẹ naa n wa ẹgbẹ oṣelu mii to le darapọ mọ bayii ṣaaju eto idibo gbogbogbo ọdun 2027.

Ẹgbẹ oṣelu PDP ko ṣe ipade igbimọ alaṣẹ wọn fun ọpọlọlọpọ ọdun.

Awọn aṣiwaju ẹgbẹ ko fi awokọse rere tori ọpọ awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa n jẹ oriṣiiriṣii ẹjọ lati ile ẹjọ giga to fi de ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria.

Awọn idi niyii ti ọmọ ẹgbẹ PDP le fi pinnu lati kuro ninu ẹgbẹ naa darapọ ẹgbẹ oṣelu miran.

Gomina Oborevwori, igbakeji rẹ atawọn oloṣelu PDP mii darapọ mọ APC ni Delta

Lọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹrin ọdun yii ni Gomina Oborevwori ipinlẹ Delta, igbakeji rẹ, Monday Onyeme, awọn kọmiṣọnna, alaga ijọba ibilẹ atawọn olosẹlu mii ni Delta kọwọọ rin lọ si APC lati PDP.

Igbakeji Aarẹ Kashim Shettima, alaga gbogbogbo APC, Abdullahi Ganduje, Sẹnẹtọ Adams Oshiomole ati Gomina Hope Uzodimma wa lara awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu APC to gba wọn sinu ẹgbẹ naa.

Gomina ipinle Delta tẹlẹ Ifeanyi Okowa to jẹ oludije igbakeji aarẹ pẹlu Atiku Abubakar ninu eto idibo aarẹ ọdun 2023 naa wa lara awọn ọmọ ẹgbẹ PDP to fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ lọ si APC lati ipinlẹ naa.

Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu PDP ti fi aake kọri wi pe awọn yoo gbe gomina ipinlẹ Delta atawọn ti wọn jọ lọ si APC lọ ile ẹjọ.

Igbimọ alaṣẹ PDP leyin ipade wataki mẹfa ti wọn ṣe niluu Abuja lana ọjọ Iṣẹgun sọ fun oludamọran ẹgbẹ naa lori ọrọ ofin lati bẹrẹ igbesẹ ati gbe ọrọ naa lọ sile ẹjọ.

PDP ṣalaye ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lẹyin ipade to waye l'Abuja wi pe awọn yoo gba gbogbo ọmọ ẹgbẹ awọn to lọ si ẹgbẹ APC pada nipinlẹ Delta.

Ẹgbẹ naa yan Ọgbẹni Emma Ogidi lati ṣagbatẹru atunṣe ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Delta.