Àwọn Boko Haram tí fídíò ṣàfihàn pé wọ́n balẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Oyo, ohun tí a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Boko Haram
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti fesi lorii fidio kan to ṣafihan awọn ikọ Boko Haram ti wọn ni wọn balẹ sipinlẹ naa.
Fidio naa ni wọn lo ṣafihan tirela to ko ọpọlọpọ ọkada ati nnkan ija sinu.
Oju ọna marosẹ Ibadan ni wọn ni awọn Boko Haram ọhun ti n sọkalẹ sipinlẹ Oyo, ki wọn too da wọn duro.
Eyi ko ipaya ba ọpọ eeyan, iroyin naa si bẹrẹ si i tan kiri.
Kí ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá wi?
Atẹjade ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Oyo, CSP Osifeso Adewale, fi sita, ṣalaye pe fidio naa ki i ṣe tuntun.
Osifeso ṣalaye pe fidio iṣẹlẹ to ti waye ni 2022 ni awọn kan tun ṣẹṣe ju sori ayelura lasiko yii, ti wọn si fi n ko ipaya ba awọn eeyan.
O ni awọn fi n da gbogbo olugbe Oyo loju, pe ko si ewu kankan fun wọn.
''Bi wọn ṣe tun gbe fidio yii jade, paapaa lasiko yii ti a n so okun aabo le dan-in-dan-in, fi han pe awọn eeyan ti ko ni ero rere lọkan lo wa nidii irọ ti wọn n gbe kiri, ti wọn si n ko awọn eeyan lọkan soke.
''Ileeṣẹ ọlọpaa rọ awọn araalu lati maa fura, ki wọn si kọyin si iru etekete bawọnyi.
''Lati le fidi ẹ mulẹ pe fidio yii ki i ṣe tuntun, a ri DCO igba naa, DSP, Segun Adeyemo, to ti fẹyinti lati oṣu Kẹjọ ọdun 2024, to farahan diẹ ninu fidio naa.
''Fun idi eyi, a rọ araalu lati dẹkun pinpin fidio ohun to ti kọja ti a si ti yanju.
''Bakan naa la rọ wọn lati maa ṣọra ki wọn too maa pin iroyin kiri lori ayelujara.
''Ki wọn ri i pe wọn ti fidi ẹ mulẹ lati ẹka to yẹ ki wọn too maa pin iroyin kiri lori afẹfẹ.''
Ileeṣẹ ọlọpaa Oyo sọ pe eyi yoo din iroyin ofege ati ipaya ku.
Bi iṣẹlẹ pajawiri ba waye, wọnyi ni awọn nọmba ipe ti araalu le fi kan si ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, gẹgẹ bi Kọmandi naa ṣe fi sita: 08081768614, 09054133071 ati 09061299291
Bi ẹnikẹni ba kẹẹfin ohun ifura kan, wọn ni ki wọn tete fi to awọn leti, fun alaafia ati aabo agbegbe gbogbo.














