Ilé-ẹjọ́ dájọ́ ikú fún ọkọ akọrin ẹ̀mí, olóògbé Osinachi

Oríṣun àwòrán, Other
Ile-ẹjọ giga ti ijọba apapọ to wa niluu Abuja, ti da ẹjọ iku fun ọkọ olorin ẹmi to ti d'oloogbe, Osinachi, Peter Nwachukwu.
Ọjọ Aje, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2025, ni idajọ naa waye.
Inu oṣu Kẹfa, ọdun 2022, ni ijọba gbe Ọgbẹni Peter Nwachukwu, lọ sile ẹjọ fun ẹsun mẹtalelogun to ni i ṣe pẹlu ipaniyan, iẹrubani, dida aya ja awọn ọmọde, lilu iyawo rẹ, ati awọn ẹsun mii.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Channels ṣe jabọ, ẹlẹrii mẹtadinlogun, ninu eyi ti meji lara awọn ọmọ ti oloogbe bi fun ọkọ rẹ wa, lo jẹri tako Nwachukwu nile ẹjọ.
Bakan naa ni wọn ko iwe ẹri bii mẹẹdọgbọn da ni lati fi gbe ẹjọ wọn lẹsẹ.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidajọ Nwosu-Iheme, sọ pe oun da ẹjọ ki wọn o yẹgi fun Nwachukwu titi ẹmi yoo fi bọ lara rẹ.
Yatọ si idajọ iku, o tun dajọ ẹwọn ọdun meji-meji fun ikọọkan awọn ẹsun meje miran.
Fun ẹsun kẹwaa, idajọ ẹwọn oṣu mẹfa, ẹwọn ọdun mẹta fun ẹsun kọkanla, ati owo itanran 700,000 naira fun ẹsun kẹfa ati ikeje.
Kini o ti ṣẹlẹ sẹyin?
Arabinrin Osinachi ti awo orin "Ekwueme" tan irawọ rẹ kariaye jade laye lọjọ kọjọ oṣu kẹrin ọdun 2022 lẹyin ti wọn ni o ni ọgbẹ inu lookan aya rẹ nitori iya ati lilu lọwọ ọkọ rẹ.
Wọn sin oku rẹ ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹfa ọdun 2022.
Oniruuru ẹsun lawọn mọlẹbi arabinrin yii pẹlu awọn ọmọ ati awọn to sun mọ ọ fi kan kọ rẹ pe lilu bi baara nii maa n lu akọrin ẹmi naa lati igba ti wọn ti fẹra wọn.
Eyi ti fa ọpọ awuyewuye lorilẹede Naijiria lori iwa ifiyajẹ ọkọ tabi aya ẹni.
Awọn ọlọpaa fi panpẹ ofin mu Peter Nwachukwu, ọkọ akọrin ẹmi naa ti wọn si bẹrẹ iwadii lọgan lara eyi ti ṣiṣe ayẹwo iku rẹ ni ilana iṣegun oyinbo ti jẹyọ.
Lasiko ipade kan to waye laarin ọga ọlọpaa Naijiria ati minisita fọrọ awọn obinrin, Pauline Tallen atawọn mọlẹbi oloogbe naa, ileeṣẹ ọlọpaa fi da araalu loju pe iwadii finifini yoo waye lori iṣẹlẹ iku oloogbe Osinachi Nwachukwu, lati lee ri pe gbogbo awọn taje rẹ ba ṣi mọ lori finmu ko ata ofin.
Ki lo ni lati mọ nipa Osinachi Nwachukwu
Ṣaaju iku rẹ, olorin ni Osinachi, akọrin si tun ni to di gbajugbaja nitori orin Ekwueme ti o pawọpọ pẹlu olorin mii Prospa Ochimana kọ.
Orin naa ti ni o le ni eeyan mọkanlelaadọrin miliọnu to wo o ni Youtube.
Bakan naa, Osinachi ti kọrin ninu awọn orin bii Nara Ekele pẹlu Pasitọ ijọ rẹ, Paul Eneche ati "You no dey use me play" pẹlu Ema. Bakan naa lo ti gbe orin tirẹ jade, "God of all Power".
O saba maa n kọ orin ni ede rẹ, Igbo amọ ko sẹni ti kii ranti ọrun to ba n kọ orin tẹkun tẹkun.
Ẹni ọdun mejilelogoji ni o fi aye silẹ to si fi ọmọ mẹrin ati ọkọ rẹ saye lọ.












