Ṣé lóòótọ́ ni pé Naijiria ti di orílẹ̀èdè ẹlẹ́gbẹ́ òṣèlú kan?

Oríṣun àwòrán, President Bola Tinubu/Facebook
Ẹgbẹ oṣelu pọ lorilẹede Naijiria, paapaa to ba di lasiko ipolongo ibo, kaluku wọn yoo maa yọju lati dije.
Ṣugbọn meji ninu awọn ẹgbẹ oṣelu to foju han ju ni Naijiria naa ni APC to n dari orilẹede yii lọwọ, ati ẹgbẹ alatako wọn ti i ṣe PDP.
Ẹgbẹ Labour naa n gbiyanju, oun wa nipo kẹta ninu alatako. Apapọ wọn naa ni wọn maa n fin APC lape.
Laipẹ yii lo di pe awọn oloṣelu inu PDP bẹrẹ si i darapọ mọ APC, bẹẹ ni awuyewuye ati aigbọra ẹni ye ko yee waye ninu PDP ati Labour ni tiwọn.
Eyi to mu ariwo waye ju laipẹ yii ni ti gomina ipinlẹ Delta, Sherif Oborevwori, to fi PDP to gbe e wọle silẹ lọsẹ to kọja, to si darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.
Yatọ si Oborevwori, Ifeanyi Okowa to wa nipo gomina Delta ṣiwaju rẹ naa darapọ mọ APC, bakan naa si ni Monday Onyeme ti i ṣe igbakeji gomina Delta lọwọlọwọ pẹlu awọn kọmiṣanna ati awọn alaga ibilẹ lati PDP kan naa tun ba wọn lọ si APC.
Oloṣelu ki i deede fi ẹgbẹ to gbe wọn depo silẹ bẹẹ ki wọn lọọ maa darapọ mọ ẹgbẹ alatako, ṣugbọn ohun to n ṣẹlẹ lọwọ ni Naijiria ree.
Eyi lo mu ọpọ araalu ati awọn amoye nipa oṣelu, ti wọn fi n sọ pe ẹgbẹ APC ti Aarẹ Bola Tinubu n dari ti di alagbara nla ti awọn oṣelu alatako n bẹru.
Wọn ni Naijiria ti di orilẹede ẹlẹgbẹ oṣelu kan, iyẹn APC nikan.
Ati pe ayipada ojiji to n waye yii ko ṣẹyin bi awọn to n sa kiri naa yoo ṣe rọwọ mu ninu idibo 2027.
Ọpọ lo n sọ pe ibẹru Aarẹ Tinubu ni ipilẹṣẹ ọgbọn fun awọn oloṣelu.
Wọn ni ki Aarẹ le fi oju ire wo wọn ni wọn ṣe n darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.
Ṣe bẹẹ leyi ri loootọ?
Ko ṣeni to fipa mu awọn to n darapọ mọ APC lati wa, wọn mọ pe awọn atunṣe ti Aarẹ n ṣe yoo pada wulo fawọn ati fun arọmọdọmọ ti wọn ko ti i bi rara ni -Ileeṣẹ Aarẹ
Lọjọ Aiku ọsẹ yii ni ileeṣẹ Aarẹ fesi lori ọrọ ẹgbẹ oṣelu kan to n lọ lọwọ.
Agbẹnusọ Aarẹ lori iroyin, Bayo Onanuga, ṣalaye ninu atẹjade kan pe ko sẹni to fipa mu awọn to n darapọ mọ APC.
Onanuga ṣalaye pe ifẹ inu wọn ni wọn fi n fi ẹgbẹ PDP silẹ, ti wọn n wọ APC wa.
Ileeṣẹ Aarẹ sọ pe ko si ohun to n jẹ ẹgbẹ oṣelu kan ni Naijiria, bẹẹ lo ni kinni kan ko ṣe ilana ijọba Dẹmokresi ti Naijiria n lo.
"Nitori pe awọn eeyan n lo ẹtọ ti wọn ni gẹgẹ bii oloṣelu lati wọ ẹgbẹ to wu wọn ko tumọ si pe iṣoro wa fun Dẹmokresi.
"Awọn ọmọ Naijiria to n wọ APC n fi atilẹyin wọn han fun Tinubu lati ọkan wọn ni.
"Wọn mọ pe awọn atunṣe ti Aarẹ n ṣe yoo pada wulo fawọn ati fun arọmọdọmọ ti wọn ko ti i bi rara ni.
Nipa awọn to n ṣo pe awọn kan lo fẹẹ jẹ ẹgbẹ oṣelu alatako run ki 2027 too de, ileeṣẹ aarẹ sọ pe:
"Ẹgbẹ alatako ko le di ẹbi aiṣe deede, ailẹkọọ ati aikunju oṣuwọn ẹgbẹ wọn ru Aarẹ.
"Ohun to n daamu ẹgbẹ alatako ti wọn ko ri yanju, o dun wa pe oun ni wọn ṣe n sọ ohun ti ko ri bẹẹ nipa Aarẹ Bola Tinubu.
Aarẹ to n ṣiṣẹ takun-takun lati da ọrọ aje Naijiria ti wọn ti bajẹ pada sipo.''
Òtítọ́ tó wà nídìí àwọn ọmọ ẹgbẹ̀ PDP tó ń lọ sí APC yóò fojú hàn bi 2027 ṣe n sunmọ -Ọjọgbọn Oyebode
Lati mọ oju ti awọn awoye oṣelu fi n wo ọrọ yii, BBC ba Ọjọgbọn Akin Oyebode, onimọ ati awoye oṣelu sọrọ.
Alaye ti Ọjọgbọn Oyebode ṣe ni pe:
"Bi ohun to n rùn ba tan nilẹ, ibi ti awọn oloṣelu wa n lọ gan-an yoo ye awọn ọmọ Naijiria. Otitọ to wa nidii ọrọ naa yoo si foju han.
"Bi awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP kan ṣe n darapọ mọ APC ko tumọ si pe Naijiria ti n di orilẹede ẹlẹgbẹ oṣelu kan.
"Itumọ to ni ni pe o n fi aiṣododo to wa laaarin awọn oloṣelu wa han.
" Ọdun 2027 naa jẹ nnkan pataki ninu ẹru ti awọn oloṣelu n di lọwọ, ba a si ṣe n sunmọ ọdun naa, àrà ọ̀tun ọlọkan-o-jọkan la o tun maa ri lati ọdọ wọn. ''
Ọjọgbọn Akin Oyebode lo ṣalaye bẹẹ.
Ṣugbọn ero araalu ni pe awọn to n fi ẹgbẹ wọn silẹ wọ APC naa mọ idi ti wọn fi n ṣe bẹẹ, fun anfaani ara wọn si ni.














