Àjọ NAPTIP dóòlà ọmọ Naijiria mẹ́sàn-an tí wọ́n fẹ́ẹ́ tàn ṣòwò ẹrú lọ si Libya

Aworan awọn eeyan ti NAPTIP doola

Oríṣun àwòrán, NAPTIP

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ to n gbogun ti fifi ẹtan tabi ipa ko awọn eeyan lati ilu kan lọ sibomi-in, 'Nigerian Agency for the Prevention of Trafficking in Persons', (NAPTIP), sọ pe awọn ti gba ọmọ Naijiria mẹsan-an kalẹ lọwọ awọn to fẹẹ tan wọn lọ si orilẹede Libya.

Aliyu Abubakar, adari ajọ naa fun ipinlẹ Zamfara, ṣalaye pe ẹnu ibode Babura, nipinlẹ Jigawa ni awọn ti doola awọn eeyan mẹsan-an naa.

O ni obinrin mẹta ti wọn jẹ ọmọ abule Yankuzo, nipinlẹ Zamfara, wa lara awọn ti wọn fẹẹ ko wọ Libya naa.

Ikọlu ibọn to n kojuu wọn nipinlẹ abinibi wọn lo mu wọn sa kuro nibẹ, ti wọn si lọọ n gbe ni Kaduna.

O ni Kaduna naa ni wọn wa ti wọn ti ṣalabapade awọn to fiṣẹ olowo nla tan wọn pe wọn yoo maa ṣe bi wọn ba de Saudi Arabia, bẹẹ Libya ni wọn n tan wọn lọ.

Abubakar ṣalaye pe bi wọn ba de Libya, ajẹkun iya, ibalopọ ipa ati ilokulo ni wọn yoo lọọ koju nibẹ.

O ni awọn to n fẹẹ ko wọn lọ yii n lo iṣoro airilegbe ati ikọlu to n koju awọn eeyan naa lati fi tan wọn ni, paapaa awọn obinrin inu wọn.

Wọ́n ti fa àwọn tórí kó yọ náè lé alága ìjọba ìbílẹ̀ wọn lọ́wọ́

Lẹyin ti ori ko awọn eeyan naa yọ, NAPTIP sọ pe awọn ti fa wọn le alaga ijọba ibilẹ wọn ti i ṣe Tsafe, lọwọ.

Ninu ọrọ alaga naa lo ti ṣeleri lati ṣe itaniji fun awọn eeyan agbegbe Zamfara, lati ma ṣe jẹ ki awọn to n fi ẹtan ko wọn lọ wọle si wọn lara mọ.

Akọwe ẹka NAPTIP to n ri si aṣilo oogun ni Zamfara, Ishaq Anka, kilọ fun awọn olugbe ibẹ, paapaa awọn to n gbe labule lati ma ṣe gọ fun awọn ẹlẹtan to n ṣeleri ilẹ okeere fun wọn.

Anka sọ pe ẹtan buruku lo wa nidii iṣẹ olowo nla ti wọn n ṣeleri pe wọn yoo fun wọn niluu ọba.

O fi kun un pe ifiyajẹni ati kiko wọn kiri lọ sibomi-in pẹlu ipa ni yoo ṣẹlẹ bi wọn ba da awọn ẹlẹtan lohun.

Kiko awọn eeyan kọja lati ẹnu ibode ilu kan si ikeji ki i ṣe nnkan tuntun mọ lawọn apa ibi kan lorilẹede yii.

Ninu oṣu Keji ọdun yii, eeyan mọkanlelogun ni ijọba ipinlé Niger ri gba pada, lasiko ti wọn fẹẹ ko wọn sọda si igberi okun.

Ọmọde ni awọn eeyan naa.

Ajọ to n ri si iwọle-wọde arinrinajo (Immigration), lo gba wọn kalẹ lagbegbe Gaidam, ipinlẹ Yobe, lasiko tawọn kan n tan wọn lọ si orilẹede Olominira Niger.