Ìbúgbàmù Iran gbẹ̀mí èèyàn méjìdínlógún, 800 míì farapa

Ibugbamu Iranq

Oríṣun àwòrán, EPA

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

O kere tan, eeyan mejidinlogun lo ti jade laye, ti awọn 800 mii si farapa lẹyin ibugbamu to waye ni Iran.

Shahid Rajaee, to jẹ ibudokọ oju omi to tobi julọ lorilẹede naa ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.

Ibugbamu ọhun fọ awọn gilaasi ferese awọn ile to wa nitosi , bẹẹ lo tun yọ orule ọpọlọpọ ile nibẹ yatọ si awọn ọkọ ayọkẹlẹ to bajẹ.

Awọn to n gbe lagbegbe ibudokọ oju omi naa ṣalaye pe awọn gbọ iro ibugbamu ọhun titi de nnkan bii aadọta kilomita sibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Fidio agbegbe naa ti BBC ri ṣafihan ina kan to kọkọ n jo kikankikan ki ibugbamu ọhun to waye.

Bi awọn eeyan ṣe n sa asala fun ẹmi wọn lẹyin ibugbamu naa lawọn mii n ṣubu lẹba ọna latari ifarapa wọn.

Oṣojumi koro kan sọ fun ileeṣẹ iroyin orilẹede Iran pe "Gbogbo inu ile nla to wa nibẹ ni eefin gba patapata, mi o ranti boya abẹ tabili ni mo sa pamọ si ni tabi ibugbamu naa lo ju mi sibẹ."

Ijọba ilẹ ọhun ti paṣẹ ki wọn gbe gbogbo ileeṣẹ ati ile ẹkọ to wa lagbegbe naa tipa bayii.

Bi ina naa ṣe n ran lati ara kọntena kan lo n ran mọ ekeji.

Ajọ Ambrey Intelligence sọ pe awọn ohun elo ti wọn n lo fun ado oloro ileeṣẹ ologun orilẹede naa lo wa ninu awọn kọntena ọhun.

Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle jabọ pe ibugbamu naa bẹrẹ lẹyin ti ina kan to ṣẹyọ nibẹ ran mọ awọn kọtenna ti ohun to le bu gbamu wa ninu rẹ.