Awakọ̀ kan wa ọkọ̀ wọ ààrin èrò níbi tí wọn tí ń ṣ'àjọ̀dún, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí sùn

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọpọ eeyan lo padanu ẹmi wọn lẹyin ti awakọ kan wa ọkọ wọ aarin awọn to n ṣajọdun niluu Vancouver lorilẹede Canada.
Ọpọ eeyan lo fara pa bakan naa nibi iṣẹlẹ ọhun to waye ni nnkan bi ago mẹjọ alẹ ọjọ Abamẹta.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn ti mu awakọ naa, o si ti wa atimọle ọlọpaa.
Olori ijọba ilu Vancouver, Ken Sim, sọ pe iṣẹlẹ naa ba oun ninu jẹ gan an, ati pe ohun to buru jai ni.
Ọgbẹni Sim ni awọn ọlọpaa ti fidi rẹ mulẹ pe ọpọ eeyan lo ba iṣẹlẹ naa lọ nigba tawọn mii si fara ṣeṣe.
O ni oun kẹdun pẹlu awọn ẹbi tawọn eeyan wọn ba iṣẹlẹ naa lọ ati gbogbo awujọ awọn eeyan Philippines niluu Vancouver.
Ajọdun ayajọ Lapu Lapu lawọn eeyan Philippines n ṣe ti awakọ kan fi wa ọkọ wọ aarin wọn lọjọ Abamẹta.
Ọdun yii wa lara awọn ajọdun to lamilaaka julọ lorilẹede Philippines.
Ileeṣẹ ọlọpaa Vancouver ni ''a le fidi rẹ mulẹ pe awọn eeyan kan ti ku tawọn mii si farapa lẹyin ti awakọ kan wa ọkọ wọ aarin ero nibi ti wọn ti n ṣajọdun ni E.41st Avenue and Fraser ni nnkan bi ago mẹjọ kọja iṣẹju diẹ.
Awakọ naa ti wa ni atimọle bayii, nigba ti iwadii si n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ naa.''















