Wọ́n ti sin òkú Pope Francis - Ẹ wo bí ètò ìsìnkú nàá ṣe lọ

Cardinal Giovanni Battista Re, lasiko ti isin n lọ, fi omi mimọ ya posi Pope si mimọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Cardinal Giovanni Battista Re, lasiko ti isin n lọ, fi omi mimọ ya posi Pope si mimọ.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Eto isinku olori ijọ Aguda, Pope Francis, ti wa sopin, niluu Romu, orilẹede Italy.

Owurọ ọjọ Abamẹta ni eto isin naa bẹrẹ ni nnkan bi aago mẹwaa.

Ṣaaju ki wọn to o sin oku naa si Santa Maria Maggiore , ni isin ti waye ni gbagede St Peter's Basilica, to wa niluu Vatican.

Lẹyin naa ni wọn fi ọkọ to lo nigba aye rẹ, eyi ti wọn n pe ni "popomobile", gbe e lọ si ile ijọsin Santa Maria Maggiore ni Romu, fun isinku.

Ile ijọsin naa lo jẹ irin kilomita mẹfa si ilu Vatica, wọn o si gba ori odo Tiber, kọja.

Awọn araalu ko ni ba wọn wọle si inu ṣọọṣi ti wọn o sin oku naa si.

Olu-ijọ Katoliiki l'agbaye, Vatican, niluu Rome, orilẹede Italy, ni wọn ti kọkọ ṣe isin.

Ọjọ keji ọjọ Ajinde, ni Francis ku lẹnu ọdun mejidinlaadọrun.

Pope Francis

Oríṣun àwòrán, EPA

Ọkọ yii, popemobile, ni wọn fi gbe oku Pope Francis lọ si iboji. Ọkọ naa lo lo nigba aye rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọkọ yii, popemobile, ni wọn fi gbe oku Pope Francis lọ si iboji. Ọkọ naa lo lo nigba aye rẹ.

Ogunlọgọ awọn olori orilẹ-ede, ati awọn gbajumọ lagbaye lo korajọ pọ sibi eto naa.

Lara wọn ni aarẹ America, Donald Trump, Volodymyr Zelensky lati Ukraine, ati Ọmọọba ilẹ Gẹẹsi, Williams.

Gbagede St Peter's Basilica ni eto naa ti n waye.

Eeyan to to 250,000 lo korajọ si St Peter's Square ati awọn agbegbe to wa nitoosi rẹ, gẹgẹ bi ikede ti ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede naa fi sita.

Ẹgbẹẹgbẹrun ero lo korajọ si Rome, lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun Pope Francis

Oríṣun àwòrán, EPA-efe/rex/shuttetstock

Àkọlé àwòrán, Ẹgbẹẹgbẹrun ero lo korajọ si Rome, lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun Pope Francis

Ki lo ku lẹyin ti wọn sin oku poopu?

Lẹyin ti isinku pari, ni awọn olori orilẹede to peju sibẹ yoo kuro ni Romu, ti yoo si ku awọn arinrinajo ẹsin ati abanikẹdun.

Ọjọ oni si lo jẹ ibẹrẹ ọjọ mẹsan an ti wọn o fi ṣe ọfọ, eyi ni wọn n pe ni, Novemdiales, ti wọn o si maa ṣe isin ojoojumọ ni iranti Francis.

Yatọ si eyi, afojusun awọn ọmọ ijọ Katoliiki lẹyin isinku ni awọn eto lati fi yan arọpo fun Francis. Eto naa ni wọn n pe ni Conclave - ikorajọpọ awọn cardinal niluu Vatican, lati dibo ni idankọnkọ.

Awọn cardianl ko tii yan ọjọ kan patoo ti wọn yoo bẹrẹ, ṣugbọn eto naa ma n waye laarin ọjọ mẹẹdogun si ogun, lẹyin iku poopu.

Eyi tumọ si pe, o ṣee ṣe ko waye lati bi ọjọ kẹfa, oṣu Karun un.

Ta a lo n dari eto isinku naa?

Cardinal Giovanni Battista Re, lasiko ti isin n lọ, fi omi mimọ ya posi Pope si mimọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Cardinal Giovanni Battista Re, lasiko ti isin n lọ, fi omi mimọ ya posi Pope si mimọ.

Ẹni to jẹ olori igbimọ awọn alufaa agba, Cardinals, Giovanni Battista Re, lo n dari eto isinku Pope Francis.

Ẹni ọdun mọkanlelaadọrun ọhun, to jẹ ọmọ orilẹede Italy alufaa ni Diocese of Brescia lọdun1957. Lọdun 2001, Pope John Paul II kede rẹ gẹgẹ bii cardinal.

Cardinal Giovanni Battista Re, lasiko ti isin n lọ, fi omi mimọ ya posi Pope si mimọ. Lẹyin naa lo sun turari - eyi to tumọ si iwẹnumọ.

Nigba to pari awọn iṣẹ isin naa ni awọn agogo to wa ni bẹ dun, ni igba mẹta, ni deedee aago mejila ọsan.