Báwo ni wọ́n ṣe ń yan Póòpù tuntun?

Awọn alufaa lasiko ti wọn n yan Pope John Paul II lọdun 2005.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Jeremy Howell
    • Role, BBC World Service
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ta lo le di Poopu ati pe awọn wo lo n yan Poopu?

Awọn alufaa to n gbadura ni St Peter's Basilica lọdun 2005

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn alufaa to n gbadura ni St Peter's Basilica

Lẹyin iku Poopu to wa lori alefa ni wọn maa n yan Poopu miran.

Wọn tun maa n yan Poopu mii ti Poopu naa ba kọwe fi ipo rẹ silẹ gẹgẹ bi Pope Benedict XVI ṣe ṣe lọdun 2013.

Poopu naa ni yoo jẹ adari ijọ Aguda kaakiri agbaye.

Ẹnikẹni ninu ijọ Aguda to ba jẹ ọkunrin, to ba si ti ṣe iribọmi lo le di Poopu.

Amọ ṣa, awọn to wa ni ipo giga julọ ninu ijọ naa ti wọn n pe ni 'cardinals' lo n du ipo Poopu.

Awọn cardinals naa lo tun maa n yan Poopu tuntun.

Lọwọ yii, awọn cardinal 252 lo wa ninu ijọ Aguda kaakiri agbaye, awọn naa tun ni o wa nipo Biṣọọbu.

Awọn ti ọjọ ori wọn ko tii to ọgọrin ọdun nikan lo lanfaani lati dibo yan Poopu.

Ṣaaju asiko yii, ọgọfa alufaa pere lo maa n dibo yan Poopu, amọ ni bayii wọn ti pe 135 lẹyin ti Pope Francis to di oloogbe yan awọn cardinal mọkanlelogun tuntun lọdun 2024.

Bawo ni awọn cardinal ṣe maa n yan Poopu?

Asiko ti wọn n dibo yan Poopu ninu ile ijọsin Sistine lọdun 2005

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Asiko ti wọn n dibo yan Poopu ninu ile ijọsin Sistine

Ti asiko ba ti to lati yan Poopu tuntun ni wọn maa n ranṣẹ pe gbogbo awọn cardinal lati wa si Vatican, ni Rome.

Ọna kan yii ni wọn n lo lati yan Poopu tuntun lati nnkan bii ọdun 800 sẹyin.

Lọjọ kinni ti wọn ba pade ni wọn maa n kọkọ ṣe isin ninu ile kan ni St Peter's Basilica. Lẹyin naa ni wọn maa korajọ sinu ile ijọsin Sistine lati ṣe awọn isin mii.

Lati igba naa lọ, wọn kii fi Vatican silẹ titi ti wọn yoo fi kede Poopu tuntun.

Ibi ti wọn ti n yan Poopu tuntun

Awọn cardinal lanfaani lati kọkọ dibo lọjọ kinni ninu ile ijọsin Sistine. Lati ọjọ keji, wọn yoo maa dibo ni aarọ ati ọsan titi ti wọn yoo fi ja awọn ọmọ oye si ẹnikan ṣoṣo.

Lasiko ibo naa ni ẹnikọọkan awọn cardinal yoo kọ orukọ ẹni ti wọn ba n fẹ ko di Poopu sinu iwe kan labẹ ọrọ "Eligio in Summum Pontificem", to n tumọ si "Mo dibo yan alufaa to ga julọ."

Lẹyin ọjọ meji ti wọn ko ba tii yan ẹni ti yoo joye Poopu, adura ni wọn yoo fi ọjọ kẹta gba, lẹyin naa ni wọn yoo tun bẹrẹ si n dibo pada.

Ida meji ninu mẹta gbogbo awọn cardinal gbọdọ dibo yan ọmọ oye ti yoo di Poopu tuntun.

Igbesẹ yiyan Poopu tuntun naa le gba ọpọ ọjọ, nigba mii o le gba ọpọlọpọ ọsẹ paapaa.

Ki lo n ṣẹlẹ ninu papal Conclave?

Awọn eeyan duro ni St Peter's Square lati gbọ esi ẹni to di Poopu tuntun lọdun 2013

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan duro ni St Peter's Square lati gbọ esi ẹni to di Poopu tuntun lọdun 2013

Lasiko ti awọn alufaa cardinal ba wa ninu ile ti wọn n pe ni 'Conclave' wọn ko ni lanfaani lati ka iwe iroyin, gbọ redio tabi wo tẹlifiṣon, koda wọn ko ni lo foonu wọn tabi ba ẹnikẹni sọrọ.

Ko ni i si ẹni ti yoo le wọ inu ile ti wọn wa lasiko ti wọn ba n jiroro lori Poopu ti oye kan.

Bakan naa, ko ni si aaye fun ẹnikẹni lati ṣe ipolongo ibo ita gbangba nitori bi wọn ṣe ni Ẹmi Mimọ lo n dari awọn cardinal ti yoo yan Poopu tuntun.

Bo tilẹ jẹ pe gbogbo alakalẹ yii ni wọn ṣe, awọn kan gbagbọ pe oṣelu wa ninu yiyan Poopu tuntun ọhun.

Eefin funfun lati inu ile ijọsin Sistine Chapel n ṣafihan pe wọn ti yan Poopu tuntun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Eefin funfun lati inu ile ijọsin Sistine Chapel n ṣafihan pe wọn ti yan Poopu tuntun

Igba meji loojọ ni wọn maa n jo iwe ti wọn fi yan Poopu tuntun ninu ile ijọsin Sistine.

Wọn maa n fi ọda dudu tabi funfun si ara eefin na lati ṣafihan ipo ti ibo wọn de.

Ti eefin dudu ba jade, o n tumọ si pe wọn ko tii yan Poopu amọ eefin funfun n tumọ si pe wọn ti yan Poopu tuntun.

Ki ni yoo ṣẹlẹ ti wọn ba ti yan Poopu tuntun?

Poopu tuntun yoo ba awọn eeyan sọrọ ni gbagede St Peter's Basilica

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Poopu tuntun yoo ba awọn eeyan sọrọ ni gbagede St Peter's Basilica

Ni kete ti wọn ba ti pari ibo, wọn yo beere lọwọ ẹni to jawe olubori pe "Ṣe o gba lati di alufaa to ga julọ ninu ijọ?

Oun funra rẹ ni yoo yan orukọ oye ti wọn yoo maa pe e ki wọn to fi aṣọ alufaa agba naa wọ ọ lọrun.

Lẹyin eyi ni awọn cardinal yoo bu ọla fun, ti wọn yoo si ṣeleri fun pe awọn yoo ṣatilẹyin fun.

Ti gbogbo eyi ba pari ni wọn yoo kede ni gbagede St Peter's Basilica pe "habemus papam", eyii to n tumọ si pe "A ti ni Poopu tuntun."

Wọn yoo kede orukọ Poopu tuntun naa ti oun funra rẹ yoo si farahan lati ba awọn eeyan sọrọ.