Wo ànfààní tó wà nínú jíjẹ́un làí kánjú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iwadii ijinlẹ sayẹnsi ti fidi ẹ mulẹ, pe anfaani nla lo wa ninu keeyan maa jẹun diẹdiẹ lai kanju.
O fi han pe bi a ṣe n jẹun, ni ipa to n ko ninu alaafia ara wa, bẹrẹ lati ibi ti ounjẹ ti n dà ninu, titi de ibi ki eeyan jẹun ko si kapa isanra rẹ, ati alaafia ara delẹdelẹ.
Bí oùnjẹ ṣe ń dà nínú
Onimọ nipa ounjẹ, Livia Hasegawa, to kẹkọọ ni Yunifasiti São Paulo, ni Brazil, ṣalaye pe :
"Lati maa jẹun diẹdiẹ maa n jẹ ki ounjẹ pin si wẹwẹ lẹnu, yoo si dẹrun lati dà ninu.
"Nigba mi-in, mo maa n ran awọn to wa n gba itọju lọdọ mi leti pe ko si eyin nikun ti yoo ba wọn ge ounjẹ si wẹwẹ .
"Fun idi eyi, bi ounjẹ ba ṣe gidigbi to si ṣe bẹẹ bọ sikun, o maa n ṣoro ki ounjẹ bẹẹ too da ninu. Ko si ni i tọ ilana to yẹ ko tọ. "
O fi kun un pe, "Bi a ba jẹ ounjẹ pẹ lẹnu, o maa n pe awọn eroja to n ba itọ́ ṣiṣẹ lẹnu jade, yoo si jẹ ko tete siṣẹ to yẹ lara ".
Bi eeyan ko ba jẹ ounjẹ lẹnu daadaa, yoo ṣoro fun ikun lati dà ounjẹ naa.
Eyi le fa ki inu kun, o si le mu ki ara eeyan maa rẹwẹsi.
Hasegawa lo ṣalaye bẹe.
Bo tilẹ jẹ pe awọn onimọ ko sọ pato iye asiko to yẹ ki ounjẹ pẹ lẹnu da ki eeyan too gbe e mi, wọn maa n gba eeyan lamọran lati ri i pe ounjẹ naa ti rọ lẹnu daadaa.
Wọn ni ko si gbọdọ tobi ju keeyan too gbe e mi.
"Bi eeyan ba n jẹun ti ko si fi ọkan si i, boya tọhun n wo tẹlifiṣan tabi o n wo foonu rẹ ju, o le ṣakoba fun ounjẹ to n jẹ lẹnu.
"Eyi maa n fa ki eeyan maa sare jẹun, yoo si maa gbe atẹgun mi ju bo ṣe yẹ lọ, eyi to le fa ki inu kun."
Hagasewa lo fi kun alaye naa bẹẹ.
Kí oùnjẹ tẹ́ èèyàn lọ́rùn àti ara sísan

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ara sisan jẹ kinni kan to n waye nipasẹ ounjẹ to n da ninu wa.
"Bi eeyan ba n sare jẹun, o maa n fa ki ara rẹ tete fa agbara mọra, eyi to maa n fa a ki eeyan maa jẹ odiwọn ohun ti a mọ si calories ju bo ṣe yẹ lọ niṣẹju kan.
"Iwadii fi han pe akanju jẹun yoo jẹun ju."
Sander Kersten Adari lẹka ounjẹ to tun jẹ Ọjọgbọn ni Cornell Yunifasiti, New York, lo ṣalaye bẹe.
O ni bi eeyan ba n jẹun diẹdiẹ, o maa n jẹ ki ounjẹ pẹ lẹnu, o maa n pe awọn eroja ti yoo mu ounjẹ da wa, yoo si jẹ kawọn ohun ti a mọ si hormones ninu ara sọkalẹ.
Sísáre jẹun lè fa àìsàn ọkàn, ẹ̀dọ̀ àti jẹjẹrẹ.
Jijẹun kiakia le mu iṣoro aida ounjẹ lagbara si i.
"Nnkan pataki mi-in to yẹ ka mọ ni pe bi ounjẹ ba de inu ifun wa pẹlu bi wọn ṣe tobi, o le ṣakoba fun inu, yoo si koba gbogbo ọna ti ounjẹ maa n gba ko too dà ninu." Hasegawa lo ṣe afikun bẹẹ.
O ni bi iwa akanju jẹun naa ba mọ eeyan lara tan, paapaa ti eeyan ba tun ni awọn iwa ijẹun mi-in ti ko daa fun ilera, yoo fa ki eeyan sanra asanju.
O ni o le fa ki eeyan ni aisan itọ ṣuga ti a mọ si 'type 2 diabetes', aisan ẹdọ, (fatty liver), aisan ọkan, ẹjẹ riru ati awọn jẹjẹrẹ bii tii oju idi, ti ọyan ati ti ifun.
Bí o ṣe lè máa jẹun làì kánjú
Fun awọn eeyan to fẹẹ kọ bi a ṣe n jẹun lọna to dara, Hasegawa, ṣalaye pe nnkan akọkọ ni lati maa fi nnkan ijẹun wọn silẹ laaarin ounjẹ naa.
"Ma ṣe mu fọọki tabi ṣibi rẹ dani fun igba pipẹ, nitori eyi le mu ki o fẹẹ maa sare jẹun ju, o ko si ni I mọ.
"Pe o kan fun nnkan ijẹun rẹ nisinmi diẹ ko o too tun lo o ko ni i jẹ ki o maa sare jẹun"
Bakan naa lo ni ki eeyan maa jẹ ounjẹ lẹnu titi ti yoo fi rọ daadaa lẹnu.
Yago fun awọn nnkan to le ṣi ọkan rẹ kuro nibi ounjẹ naa.
"Lati maa wo tẹlifiṣan tabi maa tẹ foonu nigba to o n jẹun lọwọ le ma jẹ ko o mọ boya o n sare jẹun tabi bẹẹ kọ.
Fi ọkan si ounjẹ ti o n jẹ.
"Gbiyanju lati ma ṣe maa sọrọ ju bi o ba n jẹun lọwọ.
Ọrọ sisọ le wọ ọ lara ko o si maa sare jẹun lai fiye si i."
Hasegawa lo ṣalaye bẹẹ.














