ECOWAS ní kí Mali, Niger àti Burkina Faso fi àwọn iléeṣẹ́ wọn sílẹ̀

Àwọn ológun Niger, Mali àti Burkina Faso

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Àjọ ECOWAS ti képe orílẹ̀ èdè Burkina Faso, Mali àti Niger pé kí wọ́n kúrò ní gbogbo àwọn iléeṣẹ́ àti ẹ̀ka tó so mọ́ àjọ náà lẹ́yìn tí wọ́n ní àwọn kò bá wọn ṣe pọ̀ mọ́.

ECOWAS tún ní kí wọ́n gbé gbogbo àwọn iléeṣẹ́ àjọ náà tó wà ní àwọn orílẹ̀ èdè kalẹ̀ padà fáwọn àti pé àwọn máa gba iṣẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè náà tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn ní gbogbo ẹ̀ka.

Níbi ìpàdé àwọn mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè àwọn orílẹ̀ èdè ECOWAS tó wáyé ní Ghana ni wọ́n ti sọ̀rọ̀ náà.

Ẹ ó rántí pé ní òpin oṣù Kìíní ọdún 2025 ni Mali, Burkina Faso àti Niger, tí wọ́n wà lábẹ́ ìjọba ológun parí gbogbo ìgbésẹ̀ wọn láti fi àjọ ECOWAS sílẹ̀ lẹ́yìn bíi ọdún kan tí wọ́n ní àwọn kò bá ECOWAS ṣe mọ́.

Kíkúrò ní ECOWAS, àjọ tí ọ̀pọ̀ gbà pé òhun ló fẹsẹ̀ rinlẹ̀ jùlọ ní ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Africa láti bíi àádọ́ta ọdún sẹ́yìn, kìí ṣe ohun kékeré fún àjọ náà rárá.

Àìgbọ́ra ẹni yé láàárín àwọn orílẹ̀ èdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà àti ECOWAS bẹ̀rẹ̀ nígbà tí wọ́n kọ̀ láti dá ìjọba padà fún alágbádá, tí wọ́n sì dá àjọ ti wọn tí wọ́n pè ní Alliance of Sahel States (AES) kalẹ̀.

ECOWAS ní gbayau ni ilẹ̀kùn àwọn wà fún àwọn orílẹ̀ èdè náà tí wọ́n bá pinnu láti padà darapọ̀ mọ́ wọn.

'Pípàdánù iṣẹ́'

Mínísítà fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè Nàìjíríà, Yusuf Maitama Tuggar wà lára àwọn tó péjú síbi ìpàdé náà tó sì ṣàlàyé nípa àwọn iléeṣẹ́ ECOWAS tí wọ́n ń fẹ́ káwọn orílẹ̀ èdè náà kúrò níbẹ̀.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Tuggar sọ pé àjọ náà iléeṣẹ́ ètò ìlera ńlá kan tó wà ní Burkina Faso. Ó ní iléeṣẹ́ náà máa palẹ̀ ẹrù rẹ̀ mọ́ ní Burkina Faso lọ sí orílẹ̀ èdè mìíràn níwọ̀n ìgbà tí Burkina Faso ti kúró ní àjọ náà.

"Bákan náà ni iléeṣẹ́ ètò ìsúná, tó ń ṣe àmójútó owó níná àti ìdènà gbígbé egbògi olóró wà níbẹ̀."

Mínísítà náà dárúkọ àwọn iléeṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìlera, ìrìnnà àti gáàsì tó wà ní àwọn orílẹ̀ èdè yìí, tó sì ní gbogbo wọn ni àwọn máa gbìyànjú láti gbé kúró ní àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti kúrò lára ECOWAS.

"Gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè náà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ láwọn iléeṣẹ́ ECOWAS ni wọ́n máa pàdánù iṣẹ́ wọn nítorí gbogbo wọn ló máa kúrò," Tuggar sọ.

Ó fi kun pé ilé ìfowópamọ́ ECOWAS ti dókoòwò tó lé ní mílíọ̀nù $280 lórí àkànṣe iṣẹ́ lọ́kan-ò-jòkan láwọn orílẹ̀ èdè náà àti pé àwọn òṣìṣẹ́ báǹkì náà máa pàdánù iṣẹ́ wọn nígbà táwọn orílẹ̀ èdè náà kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ́ àwọn mọ́.

Ó tẹmpẹlẹmọ pé ECOWAS ní òfin àti àwọn ìlànà tí wọ́n máa ń tẹ̀lé láti ri dájú pé ìpínyà lọ ní ìrọ̀rùn pẹ̀lú àlááfíà.

Ní ọdún tó kọjá, ECOWAS fún Mali, Niger, àti Burkina Faso ní oṣù mẹ́fà láti tún ṣe àgbéyẹ̀wò ìpinnu wọn lórí fífi àjọ náà sílẹ̀ àmọ́ àwọn orílẹ̀ èdè náà àwọn kò ní yí ìpinnu àwọn padà láti fi àjọ náà sílẹ̀.

Ní oṣu Kìíní, ọdún 2025 ni Niger, Mali àti Burkina Faso fi àjọ ECOWAS parí gbogbo ìgbésẹ̀ láti fi ECOWAS sílẹ̀.