Orí Adé dèrò ilé-ejọ̀ fún gbígba ilẹ̀ onílẹ̀, gba ọ̀pọ̀ mílíọ́nù naira lọ́wọ́ ẹnikan nípìnlẹ̀ Ogun

Oríṣun àwòrán, Others
Ijọba ipinlẹ Ogun ti wọ Olu ti ilu Obafemi to wa ni ijọba ibilẹ Obafemi Owode, Oba Taofeek Owolabi lọ ile-ẹjọ fun ẹsun gbigba ilẹ ni ọna aitọ.
Ọba Owolabi, ẹni to jẹ ọmọ ẹgbẹ lọbalọba Egba, foju ba ile-ẹjọ lọjọ Isẹgun, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2025, ti ijọba si tun ni ko rọkun nile bayii.
Ninu atẹjade kan ti ijọba fi lede lati ọwọ ẹka ijọba to n ri si idajọ, ṣalaye pe Ori Ade naa dero ile-ẹjọ fun bi o ṣe fọwọsowọpọ pẹlu awọn kan lati ta ilẹ lai gba aṣẹ, to si tun ṣekọlu si ọlọpaa kan.
Atẹjade naa fẹsun kan Oriade naa pe, o fi tipatipa gba ẹẹdẹgbẹta eeka ilẹ to wa ni agbegbe Obafemi Owode, to si tun tan ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Michael Adeyemi, lati san miliọnu marundinlọgọrin naira fun ilẹ naa.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Channels ṣe jabọ, Oba Owolabi kọ lati fi owo jisẹ fun awọn idile to ni ilẹ, to si tun fi awọn janduku sọ ilẹ naa, ti ọkan ninu wọn si ṣekọlu si ọlọpaa pẹlu ada.
Ṣaaju ki ijọba to gbe Ọba Owolabi lọ si ile-ẹjọ, atẹjade naa ni ijoba gbiyanju lati kesi Ori Ade naa ṣugbọn o kọ lati gbe ipe ijọba nigba ti wọn ni ko yọju si ile igbimọ aṣofin ninu oṣu Keje, ọdun 2024, to si morile ile-ẹjọ.
"Oba Owolabi pada yọwọ ninu ẹjọ to pe ijọba ṣugbọn o kọ lati juwọ ara rẹ fun ile igbimọ aṣofin.
Lẹyin iwadii ile igbimọ aṣofin ni ijọba palaṣẹ pe ki wọn mu Ori Ade naa, ko si lọ jẹjọ ni ile-ẹjọ fun gbigba ilẹ ni ọna aitọ.
"Labẹ idari Alake ti ilu Egba, HRM Oba Aremu Gbadebo, igbimọ ladelade Egba kesi Oba Owolabi ni ọpọ igba ṣugbọn o kọ lati jẹ ipe.
"Ni ọjọ kẹtala, oṣu Kejila ọdun 2024, igbimọ ladelade Egba fofin de Oba Owolabi gẹgẹ bi Olu Obafemi. "
Atẹjade naa ni bo ti lẹ jẹ pe Oba Owolabi ti gba beeli, igbẹjọ naa si n tẹsiwaju, ti ijọba ipinlẹ Ogun si ti pinnu pe awọn yoo yanju ọrọ naa lati ri pe idajọ ododo waye.















